Olaitan Olamide: mò lè má nílò ìwé ẹ̀rí mi tí mo bá parí ní LASU

Àkọlé fídíò, Olaitan Olamide: mò lè má nílò ìwé ẹ̀rí mi tí mo bá parí ní LASU

Aisi owo lọwọ awọn obi mi sun mi de idi iṣẹ ọwọ ki n le ri owo fi ka iwe ni fasiti- Olamide

Olamide Olaitan jẹ akẹkọọ fasiti ipinle Eko nibi to ti n kọ ẹkọ nipa iṣẹ olukọni.

Bakan naa lo tun n ṣe iṣẹ atun amu ọkọ tutu ṣe, o n ṣe mẹkaniiki to n tun ọkọ ṣe, o tun wa n ṣe bata pẹlu.

O ni oun gba pe iṣẹ ọwọ oun le pa ọpọlọpọ miliọnu wọle fun oun lọjọ ọla.

Mufutau Olaitan ba BBC sọrọ lori bi Olamide ṣe n ran oun lọwọ lẹnu iṣẹ atun nkan to n mu ọkọ tutu ṣe ti a mọ si Air Conditioner.

Olamide ni oungbẹ lati ran awọn obi oun ti ko ni owo lọwọ lo gbẹ oun de idi iṣẹ atun ọkọ ṣe.

Omọ ọdun mejilelogun yii ni bayii, oun ti n ran ara oun ni ẹkọ iwe de fasiti, ti oun si n ran awon aburo oun naa lọwọ

Olamide gba awon ọdọ Naijiria ni imọran lati ma ya ọlẹ nitori pe atẹlẹwọ ẹni kii tan ẹni jẹ.

O ni ki onikaluku gbiyanju lati fi iṣẹ ọwọ kun iwe kika nitori pe, ọna lati ran obi ati awujọ lọwọ ni.