'Ó ṣe jẹ́ èmi ni Ọlọ̀run wá fún nírú ọmọ yìí'
Ibo ni wọn ko ti koju idẹyẹsi bii pe alebu wa lara ọmọ naa, ko wọ pọ.
Eyi a maa ba iya ọmọ lọkan jẹ pupọ koda titi to fi de ile ijọdsin ni wọn ti n koju iru idẹyẹsi yii latori pẹpẹ gan tori ọ̀rọ̀ àwọn pásítọ nígbà mìí máa ń ba àwa aláàbọ̀ ara nínú jẹ́.


O wo o wipe, bi awọn pasitọ ba le maa sọ iru awọn ọrọ alebu to n ta ba awọn tara wọn o pe, ṣe ki awọn to dẹ wa ri bẹẹ fun sọ pe awọn o ni nkan to yẹ ki wọn fi dupẹ lọwọ Ọlọrun ni.
Pẹlu ọwọ kan ati ekeji to kuru jọjọ ni wọn fi bi TiaraOluwa.
Kii ṣe gbogbo ode ni iya ọmọ yii le lọ tori iru ọmọ to bi. Kii lọ sibi elero bii ariya, apejẹ elero, ọja elero ati bẹẹ bẹẹ lọ ko to wa yi ironu rẹ pada pe bi onigba ba ṣe pe igba rẹ ni wọn yoo ṣe ba a pe e.
