Anti-grazing law: Awon Fulani Darandaran Oyo ti gbe Gomina Makinde lo si ile ejo

Fulani darandaran kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn ẹgbẹ́ Fulani Darandaran ní ìpínlẹ̀ Oyo fi léde pé ijọba ìpínlẹ̀ Oyo ń tẹ ojú ẹ̀tọ́ wọn mọ́lẹ̀ pẹ̀lú òfin darandaran.

Ijọba ipinlẹ Oyo ti ni awọn ko gbọ pe ẹgbẹ fulani darandaran kankan ni ipinle naa gbe awọn lọ si ile ẹjọ.

Eyi ko ṣẹyin iroyin to tan kalẹ pe awọn ẹgbẹ Fulani Darandaran, Gan Allah Fulani Development Association of Nigeria,ti gbe ijọba lọ si ile ẹjọ lori ẹsun pe wọn fi ofin tuntun de kiko maluu jẹ kaakiri ilu, eleyii ti wọn ni o tẹ oju ẹtọ awọn mọlẹ.

Àkọlé fídíò, 2020: Ọdun 2020 yii ko nìí nira fún àwọn tó bá bẹ̀rù Olorun

Adari eto iroyin fun Gomina Makinde, Taiwo Adisa lo fi lede bẹẹ pe ohun ti awọn gbọ ni wi pe awọn ẹgbẹ darandaran kan n fapa janu lori ofi tuntun ti awon ṣe lori eto ọgbin ni ipinlẹ naa.

Adisa fikun un wi pe ofin naa ko tẹ ẹtọ wọn loju mọlẹ, bi kii ṣe ki eto ọgbin le gbooro si ni awọn ṣe ṣe ofin naa ti Ile Asofin ipinlẹ si gbe e yẹ wo, ki wọn to wa buwọ lu u.

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Ninu ọrọ rẹ, O ni awọn ti tọ awọn fulani darandaran lọ lati gbe ofin tuntun naa yẹwọ, ti wọn si wo o finifini, ki o to di wi pe wọn fi ontẹ lu ofin naa.

Ọpọlọpọ ijọba ipinlẹ lo ti gbe ofin dide dida ẹran kaakiri yẹ wo nitori eto aabo to dẹnukọlẹ ati ijamba to n ṣe fun eto ọgbin ni awọn agbegbe kan lorilẹ-ede Naijiria.

Àkọlé fídíò, 2020: Oloye Awurela Ifaleke ti wúré ọdún ìgbéga fún kóówá