'Àwọ̀ ara Nisha wà ní ipò tó ba ni lẹ́rù gan'

Àkọlé fídíò, Ṣé ẹ ti rí kí èèyàn ní àwọ̀ ara tó ń ṣí bíi ìpẹ́pẹ́ ẹja rí?

Nisha Lobo jẹ ọmọ ti a bi pẹlu ipenija awọ ara kan to le ba ni lẹru gidi gan.

Àwọ̀ ara rẹ̀ dàbíi ti ẹja. O maa n la o si maa n sipẹpẹ ni gbogbo igba.

Awọn oludasilẹ ile ọmọ alaini kan ni orilẹede India lo gbe e ti wọn si n tọju rẹ.

Nigba ti wọn ri i, awọ ara Nisha wa ni ipo to ba ni lẹru gidi gan.

Ṣugbọn ni bayii, wọn ti tọju debi pe wọn kọ ọ bi eeyan ṣe n gbe aye oun naa si jẹ ọmọ to maa n dunnu

A maa rẹrin musẹ bii ẹrin igba ayeraye.

Ohun gbogbo ni wọn fi tẹ ẹ lọrun tọkan oun gan naa si yọ mọ wọn lai ronu ipo ti o wa pẹlu ibinujẹ.