Prophet SK Abiara: Ọdún tóo bọ́ sí yìí, oò mọ ohun tí yóó ṣẹlẹ̀ àfi ...

Àkọlé fídíò, 'Ohun tóo gbúdọ ṣe lọ́dún yìí bí o bá fẹ́ kí Ọlọ́run bá ọ rìn'

Ilé ìgbọ̀nsẹ̀ tóo lọ lọ́dún tó kọjá, ó yẹ kóo dúpẹ́, fun gbogbo ohun too ṣe lọdun to kọja, o yẹ koo dupẹ.

Gbajugbaja ojiṣẹ Ọlọrun ni, Woli Samuel Abiara to jẹ oludari agba ijọ Christ Apostolic Church (CAC) lagbaye gbadura fawọn eniyan pe 2020 a dara.

Nigba ti BBC Yoruba ba Baba SK Abiara lalejo, ọpọ ọ̀rọ̀ lo fi gba awọn ọmọ Naijiria niyanju.

Baba ni "o ṣàgbèrè lọ́dún tó kọjá, má ṣe irú ẹ̀ mọ́, iṣekuṣe, ole, ma ṣe bẹẹ mọ.

Ṣe ni koo faye rẹ ati ọkan rẹ fun Ọlọrun".

Awọn adura kabiti kabiti ni baba fi kasẹ ọrọ ikini ku ọdun tuntun nilẹ.