Drug abuse: Àwọn ọ̀rẹ́ ló sún mí síi ní Fásitì- Busayo tó ti bọ́ lọ́wọ́ oògùn olóró lílò

Àkọlé fídíò, Àwọn ọ̀rẹ́ ló sún mí síi ní Fásitì- Busayo tó ti bọ́ lọ́wọ́ oògùn olóró lílò

Owó tó bá yẹ ki n fi jẹun ni mo fi n ra igbo- Busayo;

Ti ẹni to n mu oogun oloro ba ni ipinnu lati jajabọ pẹlu iranlọwọ ẹbi ati dokita yi o bọ- Dokita Oluwatayo.

Ọ̀rọ̀ oogun oro lilo laarin awọn ọdọ ti n pe fun apero gbogbo ọmọ eriwo ni Naijiria bayii.Codein lọ, DXM wọlé, kinni iyatọ?

Busayo to jẹ ọdọ to ti mu oogun oloro ri salaye bi irinajo rẹ ṣe bẹrẹ ki awọn ọdọ bii tirẹ le kọ ẹkọ.

Busayo fi idunnu re hans si Obi ati ẹbi rẹ ati ajọ NGO ti kii ṣe ti ijoba to ran an lọwọ lati bọ lọwọ isoro naa.

Dokita Ajayi salaye ọna abayọ kuro lọwọ oogun oro lilo
Àkọlé àwòrán, Dokita Ajayi salaye ọna abayọ kuro lọwọ oogun oro lilo

Kini Dokita sọ lori oogun oro lilo?

Dokita Ajayi salaye ipa ti ẹbi le ko fun BBC Yoruba.

O menuba ọna abayọ paapaa lori ipinnu eni to ba ti n lo oogun oloro.

O sọ ipa pataki ti ẹni, ara ati ileewosan ni lati ko.