Drug Abuse in Nigeria: Afurasí ṣàlàyé bí òun ṣ̣e ń lo òògùn olóró fún àwọn adìyẹ

Adiyẹ

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Arakunrin kan ti ọwọ tẹ pẹlu oogun oloro nipinlẹ Kaduna ti ṣalaye bi oun ṣe n fun awọn adiyẹ ti oun sin ni awọn oogun oloro yii mu.

Awọn agbofinro to n koju lilo oogun oloro, NDLEA lo fi panpẹ ọba mu arakunrin naa ni inu ile rẹ, ni ipinlẹ Kaduna.

''Mo n sin awọn adiyẹ fun tita, nitori naa mo ma n fun wọn ni igbo mu nitori mo fẹ ki wọn tete dagba, ki wọn si ni egungun daadaa, ti wọn ko si ni ṣe aisan.''

Bakan naa lo ni oun fun ara oun n lo oogun oloro indian hemp naa.

Afurasi naa ni oun woye pe ti awọn adiyẹ naa ba ti lo oogun naa ara wọn n ji pepe ju ti tẹlẹ lọ.

Ọga agba ikọ NDLEA ni Kaduna, Umar Adoro ni awọn mu afurasi naa ni Ọjọ Kẹtadinlogun, Oṣu Kẹrin, ọdun 2022 pẹlu kilomita oogun oloro naa.

Wọn ni agbegbe Makarfi ni Rigasa ni ijọba ibilẹ Igabi ni wọn ti ri ọkunrin naa mu bio tilẹ jẹpe o ti wa ninu awọn ti wọn n wa fun ọpọlọpọ igba.

Ọga agba NDLEA naa wa parọwa si awọn eniyan ki wọn dẹkun fifun awọn ẹranko ni oogun oloro mu.

O fikun un pe awọn to n ṣetoju ẹran osin fun tita gbọdọ ro ti ilera awọn ara ilu ati ti awọn eniyan ni apapọ.

Àkọlé fídíò, Wo àwọn ohun tí BBC fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípa ohun tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ IPOB ń gbé sorí ayélujára