Ọlọ́pàá mú ọkùnrin tó dáná sun ọmọ ìyàwó rẹ̀ márùn-ún ní Ondo

Ina kan to n jo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo sọ pe ọwọ ti tẹ ọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelọgọta kan, Ojo Joseph, fun ẹsun pe o dana sun ọmọ iyawo rẹ marun-un nilu Ondo.

Opin ọsẹ ni iṣẹlẹ naa waye ni agbegbe Fagun, niluu Ondo.

Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ naa, Arabinrin Funmilayo Odunlami sọ fun BBC pe Ọgbẹni Joseph binu dana sun awọn ọmọ naa lẹyin ija to waye laarin oun ati iyawo rẹ to jẹ iya awọn ọmọ naa.

Iyawo rẹ ọhun ti wọn ko darukọ, ti bi awọn ọmọ naa ko to o wa fẹ afurasi naa.

Iroyin sọ pe obinrin naa bi ibeji, to ṣi jẹ ọmọ irakoro fun Ọgbẹni Joseph.

Agbẹnusọ ọlọpaa Ondo sọ pe ọ̀kan lara awọn naa sinu ina naa, ti awọn mẹrin yooku si fi ara pa.

O ni wọn ti gbe wọn lọ si ileewosan gbogboogbo FMC, to wa niluuu Owo.

“Ọgbẹnu Ojo Joseph gbe epo bẹtiro, o si da a sinu yaara ti awọn ọmọ maraarun sùn si ninu ile rẹ, to si ṣa ina si lẹyin ede aiyede to ni pẹlu iya wọn.”

Arabinrin Odunlami sọ pe ọwọ awọn ti tẹ ọkunrin naa bayii, to si ti wa ni ahamọ ọlọpaa fun iwadii.

Ọjọ diẹ sẹyin ni ọwọ tẹ arakunrin kan, Tope Oladiji, funẹsun pe o dunkooko lati pa baba rẹ.

Oladiji, ẹni ọdun mọkandinlogoji, to tun jẹ ọlọkada, ni ọwọ awọn ọlọpaa tẹ ni agbegbe Holy Trinity Italuwo Italuowo niluu Ondo, ti wọn si wọ lọ ileẹjọ lati wi tẹnu rẹ.

Olujẹjọ ọhun ni ileeṣẹ ọlọpaa ni o gbe igbesẹ naa lọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹwaa ọdun 2022.

Eyi to lo di ofin orilẹede Naijiria ati ofin ipinlẹ Ondo lati ma ṣe dunkoko pe oun yoo ṣekupa eeyan.

Olujẹjọ ni oun ko jẹbi ẹsun ti wọn kan oun rara, ati wọn kuna lati lo ilana ofin gbe oun wa si ileẹjọ .