Ohun tí a mọ̀ rèé nípá òṣìṣẹ́ FRSC tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pe o fún aláboyún ní ìpá ní ikùn...

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ileeṣẹ to n risi irinna FRSC nipinlẹ Ondo ti fi atẹjade lede pe ko si otitọ ninu iroyin pe oṣiṣẹ wọn kan fun alaboyun kan ni ipa ni opopona ilu Akure.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ naa fi sita ni wọn ti ni iroyin ofege ni iroyin naa, ti iru iṣẹlẹ naa ko si waye.

Adari ẹka ileeṣẹ naa nipinlẹ Ondo, Ezekiel SonAllah lo fi oro naa lede fun awọn oniroyin.

Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe waye?

Amọ FRSC ni kii ṣe nkan to ṣẹlẹ ni ọjọ ti a wi yii niyii.

Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, SonAllah ni oṣiṣẹ FRSC lo da ọkọ igboro ti arabinrin naa wa duro nitori ko lo seatbelt ọkọ rẹ.

Amọ kaka ki ọlọkọ naa duro niṣe lo gbiyanju lati salọ, to si fẹ fi ọkọ rẹ tẹ awọn oṣiṣẹ FRSC meji pa.

Wọn ni kete ti wọn gbiyanju lati da ọkọ naa duro ni rogbodiyan bẹ silẹ nibẹ.

Awọn ero inu ọkọ bọ silẹ ti obinrin kan si ni wọn gba ohun amọ ko si nkankan to ṣe e, ti ẹjẹ ko si jade ni ibi kankan.

Amọ ni gba ti obinrin naa tẹnumọ pe oun wa ninu irora ni wọn gbe lọ si ileewosan to sunmọ itosi ibẹ.

Mo fi da awọn ọmọ Naijiria loju wi pe ọrọ ko ri bi awọn eniyan ṣe sọ rara.