Báwo ní akẹ́kọ̀ọ́ fásitì 'Michael Okpara' méjì ṣé kú sínú iyàrá lójú oorun?

Oríṣun àwòrán, Facebooki
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Abia ti kede pe awọn tu bẹrẹ iwadii lori bi akẹkọọ meji latiu fasiti ohun ọgbin Michael Okpara ni Umudike ṣe gbẹmii mi ni ọna to so okunkun.
Awọn akẹkọọ mẹji ọhun to orukọ wọn jẹ Edeh Chinonso Mordecai ati ẹnikeji nrẹ, Victor Ukpai da gbere pe awọn fẹ lọ sun, to si jẹ pe oku wọn ni wọn ri ni ọjọ keji.
Mordecai ni o jẹ akẹkọọ to n kọ nipa imọ nipa eranko, ti ikeji rẹ si n kọ nipa titọju ayika, ti wọn si jọ gbe papọ nile ti ile ẹkọ pese. eyi ti orukọ rẹ n jẹ Wisdom Lodge.
Awọn to wa nibi iṣelẹ ọhun ni ọkan lara wọn pe ẹnikan lati ẹrọ ibanisọrọ rẹ sugbọn nigba to de, o kan ilẹkun sugbọn ẹnikankan kọ lati da oun lohun.
Akẹkọọ fasiti to ba ileeṣẹ BBC News sọrọ, “Ọkan lara awọn oloogbe pe mi ni aimoye igba sugbọn ko sọ ọrọ.
“Mo gbera lati lọ sile wọn, mo gba ilẹkun sugbọn wọn ko mi lohun.
“Mo bu oju wo oju ferese wọn, mo si ri oku awọn mejeeji nile to wa,
“Kete ti mo ri wọn ni mo pariwo sita, ti wọn fi pa ja ilẹkun wọle .”
Nnkan to sẹlẹ pato, a ko le sọ- Ile Ekọ Fasiti
Gege bii iroyin to tẹ wa lọwọ. awọn akẹkọọ mejeeji jọ jẹnu papọ. Ki wọn to lọ sun ti wọn si gba bẹ jade laye.
Bakan ni iroyin miiran ni o ṣeṣe ko jẹ pe wọn ṣeku pa awọn mejeeji nitori eto idibo to fẹ waye ni ile ẹkọ ọhun, eyi ti ọkan lara wọn jẹ oludije.
Agbẹnusọ ile ẹkọ, Adamma Odefa ba ikọ BBC News sọrọ, to si fi idi isẹlẹ naa mulẹ sugbọn awọn ko le sọ pato ohun to so okunfa nii awọn naa ṣe jade laye
“Nnkan to sẹlẹ, a ko le sọ pato.
“Awọn ọlọpaa ti wa gbe oku wọn lẹyin ti wọn ri wọn ninu yara wọn ti wọn ku si.
“A ti n gbinyanju lati ransẹ si awọn mọlẹbi wọn.”












