Ramon Abass Hushpuppi, gbajúmọ̀ oníjìbìtì rí ẹ̀wọn he ní America

Oríṣun àwòrán, Hushpuppi/instagram
Ile ẹjọ kan ni America ti ju gbajumọ ọmọ Naijiria, Hushpuppi, si ẹwọn to le ni ọdun mọkanla fun ipa to ko ninu ẹgbẹ onijibiti kan ni agbaye.
Hushpuppi, ti orukọ abisọ rẹ n jẹ Ramon Abbas gbjumọ fun ṣiṣe afihan ọ̀rọ̀ ati ọla to ni, loju opo ayelujara Instagram rẹ nibi to ti ni eero iworan to to 2.8 miliọnu.
Adajọ ile ẹjọ niluu Los angeles tun paṣẹ pe ko san $1,732,841, gẹgẹ bi owo itunu fun meji lara awọn to lu ni jibiti.
Ọgba ẹwọn ijọba apapọ ni Abaas yoo ti ṣe ẹwọn oṣu marundinlogoje ọhun.
Hushpuppi ko si pampẹ ijọba orilẹ-ede Amerika fun ẹsun fifi ayederu email gba ọpọlọpọ milionu ọwọ dola lọna aito (Business Email Compromise BEC) ati awọn ẹsun miran.
Awọn ọlọpaa orilẹ-ede Dubai lo koko fi pampẹ ofin mu u ninu Oṣu kẹfa, ọdun 2020 ni United Arab Emirate nibiti o n gbe ki wọn to gbe e lo si orilẹ-ede Amẹ́ríkà.
Oriṣiriṣi awuyewuye lo tẹle bi ijọba ile Dubai ṣe fi pampẹ ofin gbẹ Hushpuppi laarin awọn ti wọn bu enu ate lu igbesi aye rẹ lori ẹrọ ayelujara ati awọn ololufẹ Hushpuppi lori ayelujara.
Awọn Agbejoro Hushpuppi.
Lẹyin igba ti awọn agbofinro ilu Dubai fi Hushpuppi ranse si orilẹ-ede Amẹrika lati jẹjo lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an ni ile ẹjọ kan ni Illinois ni ilu Chicago ni wọn ti koko gbo igbejo rẹ ni ojo kẹta, Oṣu keje, 2020 .
Hushpuppi, Gbajugbaja oni jibiti gba agbejoro Gal Pissetzky to jẹ agbejoro agba ni ilu Chicago.

Oríṣun àwòrán, HUSHPUPPI/INSTAGRAM/PBZLAWFIRM
Bawo ni igbẹjọ ṣe bẹrẹ?
Ẹka ẹtọ idajọ orilẹ-ede Amẹrika ti o fi ẹsun kan Hushpuppi gbẹ igbejo naa kuro ni ilu Chicago lo si Los Angeles ni California.
Awọn iwẹ igbejo fihan pe Pissetzky yoju si ile ẹjọ gẹgẹ bi aṣoju Hushpuppi ni ọjọ kefa, Oṣu keje, ọdun 2020
Nitori Gal Pissetzky ko le ṣoju Hushpuppi ni ile ẹjọ ni California, Hushpuppi gba agbejoro tuntun, Vicki Podberesky lati ile iṣẹ amofin Andrues/Podberesky .
Ilẹ iṣẹ Andrues/Podberesky ni asẹ lati ṣoju ẹnikẹni ni agbegbe Chicago ati California ati awọn igbejo to ni i se pẹlu iwa odaran.
Oṣu kinni, ọdun 2021 ni Gal Pissetzky ati Vicki Podberesky jawo kuro ninu igbejo Ramon Abbas Hushpuppi nitori ko ba wọn sọrọ.
Ọjọ kinni, Oṣu keta ni Louis Shapiro so fun ilẹ iṣe akoroyin BBC pe oun ni aṣoju tuntun fun Ramon Abass Igbalode.

Oríṣun àwòrán, LOUIS SHAPIRO
Mo Jẹbi Ẹ̀sùn lilu jìbìtì- Hushpuppi
Hushpuppi jẹwo nile ẹjọ wi pe oun jẹbi ẹsun iwa jibiti ti wọn fi kan an.
Ọkan ninu awọn iwẹ ile ẹjọ naa fihan wi pe Hushpuppi ti gba ọwọ toto milionu mẹrinlelogun dola lọna aito.
Iwẹ igbejo fihan pe Hushpuppi gbero lati ji ọwọ to le ni milionu kan dola lọwọ ẹnikan ti o fe ko ile ẹkọ fun awọn ọmọde ni ilu Qatar.
Ọkan ninu awọn iwẹ ti wọn fi fi esun kan an ni wi pe laarin ọjọ kejidinlogun, oṣu kinni, ọdun 2019 si ọjọ kẹsan an, oṣu kẹfa, ọdun 2020 ni Hushpuppi ati awọn miran fi ọna aito gba ọwọ lọwọ ọpọlọpọ kaakiri agbanla ayẹ.
Ilẹ ẹjọ ni o ṣẹeṣẹ ko lo to ogun ọdun ni atimole ti yoo si da awọn owo ti ọ gba lọna aito pada.

Oríṣun àwòrán, HUSHPUPPI/INSTAGRAM
Nibo ni ọrọ Igbẹjo Hushpuppi dé duro?
Ile iṣẹ ti o n risi ẹtọ idajọ ni Central District ti California ti saaju kede ọjọ kẹrinla, Oṣu keji, ọdun 2022 fun kika idajọ.
Loius Shapiro, eni ti o n soju Hushpuppi be ilẹ ẹjọ lati sun igbejo naa siwaju, eyi ti Adajo Otis D Wright gba ti wọn si sun idajọ naa si ọjọ kokanla, Oṣu keje.
Ile ẹjọ tun sun idajọ siwaju sii Lẹyin ti agbejoro Ramon Abass tun ro ile ẹjọ leekansi lati sun igbejo naa.
Ọjọ tuntun fun ẹtọ igbejo Hushpuppi ni ọjọ keje, oṣu kọkanla, ọdun yii,

Oríṣun àwòrán, HUSHPUPPI/INSTAGRAM
Hushpuppi tọrọ idarijin fun awọn ẹṣẹ rẹ
Hushpuppi ninu lẹ́tà ti o ko si Adajo Otis D.Wright so wi pe ẹgbẹrun lọna oọdunrun dola $300,000 ni oun ri gba ninu milionu owo ti wọn fi esun re kan oun.
Ramon Abass ni òwò aso ati bata ni oun n se ki oun to rowo gba sọobu ki oun to ni Ẹka kaakiri.
Hushpuppi ni oun darapo mọ ẹrọ ayelujara Instagram lodun 2012 lati ta awọn ọja oun ati lati fi awọn ona igbesi aye oun han .
Ninu lẹ́tà ti o ko si Adajo agba, Ramon Abass ni bí awọn agbofinro se fiya jẹ oun lo ṣokunfa ero arokan si oun lara ti oyinbo n pe ni Post Traumatic Stress Disorder.
Hushpuppi tọrọ aforijin lọwọ Adajo agba.
O si seleri lati san ọwọ ti ọ gba lona aito pada.
Ile-ẹjọ ẹjọ nilu America yoo gbẹ Igbẹjo kalẹ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan Hushpuppi loni ọjọ keje, oṣu kọkanla.
Igbẹjo naa yoo waye lẹyin ọdun meji ti awọn agbofinro ilu Dubai fi pampẹ ofin gbẹ e.
O seese ki o lo okeretan ọdun mọkanla ni atimọle.
Ohun ti o daju ni wi pe ọjọ keje, oṣu kẹsan an, yoo je ọjọ male gbagbe ni Ẹka ẹto idajo to nise pelu gbigba ọwọ lọna aito lori ẹrọ ayelujara.












