Adedoyin àti afurasí yókù ní àwọn kó jẹ̀bi ẹ̀sùn ípànìyàn tí iléẹjọ́ fí kàn wọn

AWORAN

Awọn afurasi to n jẹjọ lori Igbẹjọ iku akẹẹkọ fasiti Obafemi Awolowo, Timothy Adegoke ni awọn ko jẹbi ẹsun mejidinlogun ti ileẹjọ giga ipinlẹ Osun fi kan wọn.

Okan lara awọn ẹsun naa ni pe wọn sowọpọ ṣekupa oloogbe naa.

Ti a ko ba gbagbe igbẹjọ ọhun ni ko ni anfani lati tẹsiwaju nibi ọsẹ mẹji ṣeyin nitori pe ọkan gboogi lara awọn afurasi, Rahmon Adedoyin ko lati farahan si ileẹjọ nitori ilera, to si ti bere fun anfani lati lọ tọju ara rẹ.

Lara awọn ẹsun ti ileẹjọ giga ipinlẹ Osun, labẹ asakoso Adajọ Adepele Ojo, fi kan awọn afurasi ọhun ni pe wọn sowọpọ lati ṣekupa Timothy Adegoke nilẹ itura kan niluu Osun.

Awọn afurasi naa salaye fun Adajọ Adepele Ojo pe awọn ko jẹbi ẹsun kankan ti ileẹjọ fi wọn kan wọn rara.

Adajọ Adepele Ojo ni orisiris ipe ni oun gba pe oun fẹ mọmọ ran eeyan lọ si ọgba ẹwọn.

“Ko yami lara lati ran eeyan lọ ọgba ẹwọn sugbọn o yami lara lati gbe idajọ ododo kale.

“ Ti ẹnikẹni lara awọn agbẹjọro ba ti gba owo lọwọ awọn afurasi, ki iru ẹni bẹẹ tete lọ da owo ọhun pada.

“Tabi ko wa sile ẹjọ, ki n ran an lọwọ lati gba owo rẹ pada.”

Kini Agbẹjọro Adedoyin sọ nile ẹjọ?

Bakan naa ni ileẹjọ, Agbẹjọro Adedoyin ni awọn ko nifẹ lati si anfani lati lo gba iwosan lori ailera afurusi ọun ati pe awọn ni awọn ẹlẹrii kan ti wọn fẹ pe wa si ileẹjọ.

Lafikun, awọn agbẹjọrọ afurasi meta miran eyi ti Adeniyi Aderogba wa lara wọn ni pe awọn ni ẹlẹri ti awọn fẹ safihan ni ileẹjọ

Agbẹjọro ita Okon, ni afurasi keje, Adedeji Adesola to lati gbeja ara rẹ.

Ileejo ti wa sun igbejo naa si ojo kinni, ati ojo keji, oṣu kejila odun yii.

Eyi waye nitori pe awọn agbẹjọro ni awọn fẹ safihan awọn ẹlerii mii.