Oyo Politics: Bayo Adelabu ké sí gómìnà Seyi Makinde kọ̀wé fipò sílẹ̀ nítorí ìkùnà ìjọba rẹ̀

Adelabu ati Makinde

Oríṣun àwòrán, Others

Oludije si ipo Gomina Ipinlẹ Ọyọ lati inu ẹgbẹ oṣelu 'Accord Party', Oloye Bayọ Adelabu ti pe fun ikọwe fi ipo silẹ Ṣeyi Makinde gẹgẹ bii Gomina ipinlẹ Ọyọ.

Adelabu lo fi ọrọ yii lede ninu ifọrọwerọ kan ti o waye lopin ọṣẹ.

O ṣe alaye wi pe ijọba k'ijọba ti o ba kuna gẹgẹ bi ijọba Makinde lo yẹ ki o kọwe fi ipo silẹ, paapaa julọ ti ikuna naa ba niṣe pẹlu eto aabo, imọtoto ayika ati ipese awọn ohun elo amayedẹrun.

Wo awọn nkan ti Adelabu ka silẹ pe Gomina Seyi Makinde kuna le lori:....

Adelabu ni, "Ileeṣẹ kolẹ-kodọti ko si lẹnu iṣẹ mọ.

-A nilo awọn ibudo ikodọti si ti ko ni si laarin ilu.

-A le bẹrẹ sini sọ ẹgbin di ọrọ lati ara awọn idọti ti wọn ba kojọ ninu ilu. Ẹgbin ti di nnkan ti wọn fi n ṣe ọrọ ni awọn ipinlẹ mii".

Adelabu tẹsiwaju wi pe ikuna Ṣeyi Makinde waye nipasẹ aini otitọ ati aikun oju osunwọn.

Bakan naa lo fi ẹsun kan wi pe Ṣeyi Makinde ko fun oun laaye lati ṣe tunṣe agọ ọlọpaa ti awọn olufẹhonuhan ENDSARS dana sun.

Lẹyin ọpọlọpọ nnkan ti o ka silẹ wi pe oun yoo ṣe ti o ba wọle gẹgẹ bii Gomina ipinlẹ Ọyọ,

Adelabu tun ṣe alaye wi pe o ṣeeṣe ki oun lẹdi apo pọ mọ awọn oṣelu mii n'ipinlẹ Ọyọ, ki o le rọrun fun oun ati gbogbo awọn to n dije ninu ẹgbẹ oṣelu 'Accord' lati jawe olubori ninu eto idibo ọdun 2023.

Àkọlé fídíò, Uber Lady: Bùkátà pọ̀ lọ́rùn mi ní mo ṣe ń wa taxi akérò

Adelabu ni oun ko ni pada sinu ẹgbẹ oṣelu APC mọ, nitori pupọ ninu awọn agba ẹgbẹ oṣelu mii to n bẹ n'ipinlẹ Ọyọ lo n ṣe atilẹyin fun ilepa rẹ ati awọn ẹlomii to n dije ninu ẹgbẹ oṣelu ti o wa.

O fi igboya han wi pe ẹgbẹ oṣelu 'Accord' ni yoo jawe olubori ninu eto idibo to n bọ lọna.

Adelabu ni o ṣeeṣe ki ẹgbẹ oṣelu naa ni ajọṣepọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu APC tabi PDP, ti wọn ba ṣetan lati ṣe atilẹyin fun ilepa rẹ.