Àwọn obìnrin tó fẹ́ bá mi ya fọ́tò máa ń fẹ́ kí n da ara lé àwọn
"Ti awọn obinrin ba fẹ ya fọto pẹlu mi, wọn ma n fẹ ki n gbe ara le wọn. Ki n fi ara kan wọn ki wọn le mọ wi pe awọn n ya fọto pẹlu ẹni to gaju lọ."
Ọkunrin yii lo di ẹni to ga julọ bayii ni orilẹede Ghana. Oṣu mẹta-mẹta si mẹrin- mẹrin ni o ma n ga si.
“Ti o ko ba ri mi ni aarin oṣu mẹta si mẹrin, ti o ba wa ri mi ni oṣu miran, mo ti ga sii.”
Sulemana Abdul Samed ti ọpọ mọ si Awuche ga to iwọn bata ẹṣẹ mẹsan le ni mẹfa.
Ni ọdun 2015 si 2016 ni o sakiyesi pe o n gasi.
Ibi ahọn lo ni o ti bẹrẹ nigfba ti o sun to si ji to rii pe ahọn ti fẹ o si ti gun sii.
“O tobi debi pe mi o lee mi daradara. Ko kọkọ ye mi afi bi awọn eniyan to ba wa lati Gambaga ṣe n sọ ti wọn ba ri mi pe; Awuche, wo o bi o ṣe ga! Bi o ṣe bẹrẹ niyẹn.”

"Awọn eniyan ma n fẹ lati sun mọ mi"

''Iwọ ọkunrin yii, mo fẹ ya fọtọ pẹlu rẹ. Mo ma n rii loju opo ikansiraẹni''.
''Njẹ mo le ya fọto pẹlu rẹ''. O le sun mọ mi ti aa si ya fọto pẹlu ara wa".
O jẹ ko di mimọ pe awọn kan to ri oun nileewosan lọjọ kan sọ pe oun ni aarun
gigantism, to ma n mu ki egungun eniyan gun ju bo ṣe lọ.
"Dokita naa kọ lẹta fun mi to sọ wi pe ki n lọ si ileewosan Tamale Teaching Hospital (TTH).
Nitori ọpọlọ mi ni wọn yoo ti ṣayẹwo ohun to n ṣe mi. Wọn yoo yọ ohun kan ti
yoo jẹ ki opin de ba bi mo ṣe n ga si."
Erongba Sulemana ni lati fẹ iyawo ko si jẹ baba ọmọ, ko si ri bi awọn ọmọ rẹ yoo ṣe ri.
"Nitori bi Allah ṣe kọ temi niyẹn, o si bami lara mu."
















