Lóòótọ́ ni èmi àti Binta Ayo Mogaji bímọ fúnra wa - Jibola Dabo

Oríṣun àwòrán, Jibola Dabo/FACEBOOK
- Author, Faoziyah Saanu-Olomoda
- Role, Broadcast Journalist
Gbajùgbajà àgbà òṣèré tíátà Micheal Ajibola Daboiku tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Jibola Dabo ti ní àwọn ipa kan wà tí òun kò le kó nínú eré mọ́ nítorí àwọn nǹkan tí ojú òun rí nígbà tí òun kó àwọn ipa náà.
Jibola Dabo nígbà tó ń bá ìwé ìròyìn Punch sọ́rọ̀ ṣàlàyé àwọn ohun tí àwọn ènìyàn ti fojú òun rí sẹ́yìn nígbà tí wọ́n bá ri òun lójú ayé.
Ó ní òun kò le kó ipa ìhòhò nínú eré nítorí àwùjọ wa fajúro sí irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ àti pé òun ti kó àwọn ipa kan nínú eré tó bu òun lọ́wọ́.
Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ló máa ń bú òun lórí ayélujára nígbà tí òun bá kó àwọn ipa tí àwọn ènìyàn náà kò fẹ́ràn láì ní rántí pé eré lásán ni àwọn ń ṣe.
"Mo rántí pé obìnrin kan fọ́mi létí ní ilé epo kan ní Alapere nítorí ipa tí mo kó nínú sinimá kan níbi tí mo ti kó tọ ọmọbìnrin kan lọ nínú eré náà."
"Kò dùn mí pé obìnrin náà fọ́mi létí nítorí mo gbàgbọ́ wí pé mo kó ipa náà dada ni ló ṣe rò bóyá ojú ayé ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹlẹ̀."
Jibola Dabo tẹ̀síwájú pé ipa tí òun kó nínú eré kan níbi tí òun ti fẹnuko ọkùnrin lẹ́nu jẹ́ èyí tí ọ̀pọ̀ ènìyàn lò láti fi tàbùkù òun tí wọ́n sì ń sọ onírúurú nǹkan nípa òun.
"Nígbà tí mo gbégbá òṣẹ̀lú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló lo ipa tí mo kó nínú eré náà láti fi tàbùkù mi pé ṣe ẹni tí wọ́n máa dìbò fún ni ẹni tó ń fẹnuko ọkùnrin ẹgbẹ́ rẹ̀ lẹ́nu."
Ó ní ìdí wọ̀nyí ni òun kò fi le kó àwọn ipa mìíràn nínú eré pàápàá èyí tó bá jẹ mọ́ ìhòhò.
Èmi àti Binta Ayo Mogaji ṣe wọléwọ̀de, a bí ọmọ kan, ṣùgbọ́n a ò gbé ara wa sílé bí i lọ́kọláya
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìbáṣepọ̀ láàárín òun àti Binta Ayo Mogaji, Jibola Dabo ní láti kékeré tí òun ti bẹ̀rẹ̀ tíátà ni àwọn méjéèjì ti ń fẹ́ ara àwọn.
Jibola Dabo ní nígbà tí òun lọ sí ìlú òyìnbó ni àwọn méjéèjì kò gbúròó ara àwọn mọ́ àmọ́ tí àwọn tún bẹ̀rẹ̀ eré ìfẹ́ àwọn padà lẹ́yìn tí òun padà dé Nàìjíríà ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2000.
Ó fi kun pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ní ìyàwó àti àwọn ọmọ ní ìlú òyìnbó ṣaájú àkòkó náà àmọ́ ètò ìpínyà ti ń lọ láàárín àwọn.
Ó ṣàlàyé pé àwọn bí ọmọkùnrin kan papọ̀ nítorí lásìkò tí àwọn méjéèjì fi ń ṣe wọléwọ̀de Ayo Mogaji ti pé ogójì ọdún tí kò sì lè yọ oyún.
Bákan náà ló fi kun pé ìwà àwọn méjéèjì kò bá ara àwọn mu ni àwọn méjéèjì kò fi tẹ̀síwájú láti ṣe ìgbéyàwó.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa fífẹ́ ju ìyàwọ kan lọ, ó ní òun gbàgbọ́ nínú níní ìyàwó tó ju ẹyọ̀kan lọ jú kí ènìyàn máa ṣe àgbèrè.
Ó ní àṣà òkèrè ni àwọn kan fẹ́ máa la bọ ìran adúláwọ̀ lọ́rùn dandan.












