100 ọmọ ló ń kú ní Nàìjíríà láàrín wákàtí kọ̀ọ̀kan lójúmọ́- UNICEF

Unicef logo

Oríṣun àwòrán, @Unicef

Ajọ to n risi ọrọ ọmọde ni agbaye ti a mó si United Nations Children's Fund ti sọrọsoke lori iku ọmọde ni Naijiria lasiko yii.

UNICEF ni eyi ko ṣẹyin airi ounjẹ to n ṣe ara loore jẹ bi o ti yẹ.

Nemat Hajeebhoy to jẹ adari ẹka to n mojuto eroja ounjẹ ti awọn ọmọde n jẹ lo sọ ọrọ yii nilu Abuja nibi ipade apero kan ti ajọ amojuto ohun jijẹ ni Naijiria.

O salaye pe pẹlu ajọṣepọ ọfiisi igbakeji aarẹ ati atilẹyin ajọ UNICEF at'awọn miran pe aisi ounjẹ to dara to n ṣe akoba fun igbayegbadun ati idagbasoke awọn ọmọde ni Naijiria.

Arabinrin Hajeebhoy sọ pe airi ounjẹ to dara jẹ n ṣe akoba fun ilera, idagbasoke ati afojusun ọjọ ọla awọn ọmọde, bẹẹni opo awọn ọmọ ni ko ri ounjẹ to ṣe ara loore jẹ ti wọn nilo fun didagba bi o ṣe yẹ.

"Bi wọn ko ba ri amojuto to yẹ, ni ilọpo mejila, o ṣeeṣe fun awọn ọmọ ti ko ri ounjẹ to sara loore jẹ o tete ku ju awọn to jẹun daada lọ.

Àkọlé fídíò, Uber Lady: Bùkátà pọ̀ lọ́rùn mi ní mo ṣe ń wa taxi akérò

"Bi igbesẹ to dara ko ba tete di gbigbe, nnkan bi miliọnu marundinlogun o din diẹ ọmọde tọjọ ori won ko ju marun un lọ ni yoo maa koju airi ounjẹ to sara loore jẹ lọdun yii.

O fi kun pe ipenija nla ni ọwọn ounjẹ jẹ fun ọjọ ọla Naijiria nitori pe ida kan ninu mẹta idile ni ko le pese ounjẹ to ṣe ara lore fun àwọn ọmọ wọn.

Àkọlé fídíò, Olutoye: Ọmọ ọdọ̀ àgbà ni mí, kò sì y kí èdè Yorùbá parun