Ìjọba ya èèyàn 100 sọ́tọ̀ ní Ghana tórí àrùn pọ̀jẹ̀-pọ̀jẹ̀ Marburg

Ami idamọ arun Malburg

Ijọba orilẹede Ghana ti fi eeyan bii ọgọrun si ipamọ lẹyin tawọn osisẹ eleto ilera fidi rẹ mulẹ pe eeyan meji ti ko kokoro arun iba asekupani Marburg

Awọn alasẹ orilẹede naa ni eeyan meji ti ku sile iwosan lẹkun guusu Ashanti lẹyin ti wọn ko kokoro arun iba pọ̀jẹ̀-pọ̀jẹ̀ naa, eyi to fi ara jọ arun Ebola.

Amọ ẹyẹ adan ni iwadii sọ pe o n se okunfa iba buruku yii, tawọn alasẹ si ti n laago ikilọ pe ki wọn takete sawọn iho ti awọn ẹyẹ yii lugọ si.

Isẹlẹ iba pọjẹ-pọjẹ to bẹ silẹ lorilẹede Ghana yii ni isẹlẹ keji ti yoo waye lawọn orilede to wa lẹkun iwọ oorun Afirika.

Bẹẹ ba gbagbe, a mu iroyin wa fun yin ni ọdun to kọja pe arun iba pọjẹpọjẹ Marburg bẹ silẹ lorilẹede Guine.