Amnesty International korò ojú sí ìdájọ́ ile-ẹjọ Kano lórí àwọn tó ṣe Tiktok fi fi Ganduje ṣe àwàdà

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ajo ajafeto ọmọniyan, Amnesty International ti bu ẹnu ate lu idajọ ile ẹjọ Majisireti kan nilu Kano.
Ileẹjọ naa lo paṣẹ pe ki wọn lu ọdọkunrin meji ni ẹgba nigba ogun
Kini o kọkọ ṣẹlẹ?
Awọn odokunrin meji naa ni wọn fi ẹsun ibaniloruko jẹ kan ni ipinlẹ Kano to wa ni ariwa orilẹ-ede Naijiria.
Awọn odomodekurin meji ohun ti wọn lokiki lori ero ayelujara Tiktok, Mubarak Muhammad ti a n pe ni Unique Pikin ati Nazifi Muhammad, ni ileẹjọ ni ọjọ Ajẹ ose yii da wọn lẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀.
Wọ́n sì tọrọ àforijin, ṣùgbọ́n Adájọ́ ní kí wọ́n fún wọn ní ogún (20) paṣán lọ̀kọ̀ọ̀kan.
Kí wọ́n san owó ìtanràn tí ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà (£20) àti láti gba ilé ẹjọ́ náà mọ́ fún ọgbọ̀n ọjọ́.
Kini Amnesty International sọ lori re?
Ajo Amnesty International ti bu enu ate lu idajọ naa.
Bakan naa lo pe fun idasile awọn odomokunrin meji ohun
O ni pe: ọrọ ika ni a gbọdọ parẹ ati pe awọn irawọ Tik Tok ọdọ gbọdọ wa ni idasilẹ lẹsẹkẹsẹ ati lainidi.

Oríṣun àwòrán, AMNESTYINTERNATIONAL/FACEBOOK
Eṣẹ wo ni wọn mu awọn oni tik tok naa fun?
Mubarak Isa Muhammad ati Muhammad Bala ni wọn mu ni ọsẹ to kọja lẹyin ti wọn gbe fidio wọn jade.
Ninu eyi ti wọn fi gomina ipinle Kano ṣe ẹlẹya fun ẹsun fifipa gba ilẹ, iwa ibajẹ ati sisun lori iṣẹ ti won gbe jade lori ero ayelujara TikTok ati Facebook.
Ajọ ajafeto omoniyan, Amnesty International koro oju si bi won se ti awọn ọdọmọkunrin mejeeji sinu atimọ́le fun ọsẹ kan ''laisi iwadii'' eyi ti o lodisi eto ọmọniyan won.
Amnesty International sọ pe ''fifi awọn ti o dipo oṣelu mu se awada ki i se ẹṣẹ.''
Igbẹjo yii yoo mu ariyanjiyan tuntun jade lori lilo eto awọn ọmọ orilede lori oro siso ati lilo awọn ero ayelujara.

Adájọ́ pàṣẹ pé kí wọ́n lu génde méjì, kí wọ́n tún gbálẹ̀ ilé ẹjọ́ nítorí Tiktok
Ile ẹjọ Majisireti kan nilu Kano ti paṣẹ pe ki wọn lu ọdọkunrin meji ni ẹgba ogun, ki wọn si tun san ẹgbẹrun mẹwaa owo itanran.
Yatọ si eyi, awọn mejeeji yoo tun gba ilẹ ile ẹjọ fun ọgbọn ọjọ.
Ọjọ Aje, ọjọ keje, oṣu Kọkanla ni igbẹjọ naa waye.
Ẹsun ti wọn fi kan awọn ọkunrin mejeeji, Mubarak Muhammad ati Nazifi Muhammad, ni pe wọn fi fidio kan to tabuku Gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje sori ayelujara Tiktok.
Ọsẹ to kọja ni awọn ọlọpaa mu wọn fun pe wọn fi fidio naa fi ẹsun iwa ibajẹ kan gomina naa.
Wọn ti kọkọ farahan nile ẹjọ nibi ti wọn ti ka ẹsun iditẹ ati ibani lorukọ jẹ kan wọn.
Adajọ sun igbẹjọ si ọjọ keje, oṣu Kọkanla. Lati ile ẹjọ si ni awọn ọlọpaa ti fa awọn ọmọkunrin naa le awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn lọwọ.
Eyi to sọ wọn di ero ọgba ẹwọn Kurmawa Central Prison nilu Kano.
Onidajo Aminu Gabari to gbọ ẹsun naa paṣẹ pe ni kiakia ni ki wọn lu wọn ni ogun ẹgba ninu ọgba ile ẹjọ, ki wọn si tun san owo itanran.
Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹjọ, oṣu Kọkanla ni wọn o bẹrẹ si ni gbálẹ ọgba ile ẹjọ.
Ni kete ti igbẹjọ pari si ni awọn oṣiṣẹ ile ẹjọ naa ko ẹgba wọle, ti wọn si lu awọn ọmọkunrin naa loju gbogbo eeyan.
Onidajo Gabari sọ pe ireti oun ni pe idajọ naa yoo jẹ́ ẹ̀kọ́ fun awọn eeyan to ma n lo ayelujara lati rí àwọn agbalagba fín.
Agbẹjọro ijọba, Wada Wada sọ pe idajọ naa tẹ oun lọrun.
Kilo wa ninu fidio to koba Mubarak ati Nazifi?
Ninu fidio ti wọn fi sori ayelujara, ni Mubarak to jẹ apanilẹrin ti n tumọ awọn ọrọ kan ti Nazifi to n ṣe bi alfa n sọ ni ede Arabiiiki.
Lara awọn nkan ti wọn sọ ni pe “iwaasu yii da lori ọkunrin kan ti wọn n pe ni Ganduje, ọkọ Gwaggo, baba Balaraba.
“Ọkunrin ti wọn n pe ni Ganduje yii j eeyan kan ti awọn araalu Kano ko finu tan, o si jẹ ẹnikan to jẹ pe gbogbo ilẹ to ba fojuri lo n tà.”
Mubarak ṣẹṣẹ pari eto agunbanirọNYSC laipẹ ni.
Kini ofin Naijiria sọ nipa iru nkan bayii?
Onimọ ofin kan, Isah Jamil sọ fun BBC pe lootọ ni ofin faaye gba ominira ọrọ sisọ, amọ ofin tun tako ibanilorukọ jẹ.
Amofin naa sọ pe awọn apanilẹrin naa le ṣe ohunkohun to ba wu wọn, amọ wọn ko gbọdọ darukọ ẹnikẹni ninu fidio wọn.












