Òͅnà tí àwoͅn onísͅòwò POS ń gbà lu àwoͅn ènìyàn ní jìbìtì rèé – Onísͅòwò POS sͅàlàyé

Oríṣun àwòrán, Others
Arakunrin kan to n sͅe owo POS ti kiloͅ fun awoͅn eniyan lori oͅna ti awoͅn janduku n gba fi ja awoͅn eniyan ni ole.
Geͅgeͅ bi oͅroͅ reͅ, awoͅn onisͅowo POS n gba oͅna eͅburu lati yoͅ owo ninu apo isͅuna awoͅn eniyan ti woͅn ba wa si oͅdoͅ woͅn.
Oni POS naa sͅalaye ni eͅkunreͅreͅ oͅna ti awon eniyan le gba lati masͅe jeͅ ki woͅn lu woͅn ni jibiti moͅ.
''Bi o sͅe le daabo bo ara reͅ ree loͅwoͅ awoͅn oni jibiti POS''
Geͅgeͅ bi oͅroͅ arakunrin yii awoͅn ole le lo BVN eniyan lasiko ti woͅn ba n lo POS ni oͅdoͅ woͅn, ti woͅn a si loͅ si apo isuna naa leͅyin, lati ko gbogbo owo to wa ninu apo isͅuna eͅni oͅhun.
O gba awoͅn eniyan ni imoͅran lati ma a fi ara baleͅ lasiko ti woͅn ba n lo POS.
Ni kete ti woͅn ba ti ‘approve transaction’, oͅhun ti eniyan gboͅdoͅ sͅe ni lati teͅ boͅtini ‘cancel’ ki woͅn ma bani anfaani si gbogbo iroyin to wa lori kaadi ATM naa.
Geͅgeͅ bi oͅroͅ arakunrin naa, ti woͅn ko ba teͅ ‘cancel’, ti eͅni to ni POS naa ba jeͅ onijibiti, o le lo BVN eͅni naa.
Ohun ti won ma n se ni lati fi BVN naa ranse si awon obayeje, ti won a si hack account eni naa.
Leͅyin naa ni woͅn yoo ko gbogbo owo to wani ibeͅ.
‘’Ni kete ti o ba ti fun woͅn ni ATM reͅ, ri pe o ‘approve’ loju reͅ, ki o siteͅ ‘cancel.’
‘’Amoͅran mi nipe ki o ma wuleͅ fun woͅn ni ATM Card reͅ, duro ti kaadi reͅ titi woͅn yoo fi pari ‘Transaction’ oͅhun.












