Wo ìdí tí ilé ẹjọ́ fi wọ́gilé ìdàjọ́ ẹ̀wọ̀n tó fún alága àjọ EFCC, Bawa

Oríṣun àwòrán, efcc
Ile ẹjọ giga ijọba apapọ nilu Abuja ti wọgile idajọ ẹwọn ti adajọ da fun alaga ajọ EFCC, Abdulrasheed Bawa fun iwa afojusi sile ẹjọ.
Ọjọbọ ni Onidajọ Chizoba Oji, wọgile idajọ to kọkọ ṣe ni ọjọ Iṣẹgun, lẹyin ti Ọgbẹni Bawa mu iwe ẹ̀bẹ̀ wa sile ẹjọ.
Ninu iwe naa ni EFCC ti sọ fun ile ẹjọ lati da gbogbo igbẹjọ duro lori ọrọ laarin ijọba apapọ ati Rufus Adeniyi Ojuawo, ko si gbọ ẹbẹ ti oun mu wa.
Ṣaaju ni adajọ ni ki wọn o ju alaga EFCC si ẹwọn Kuje niluu Abuja, titi yoo fi mu aṣẹ ti ile ẹjọ pa pe ki ajọ naa da ọkọ ayọkẹlẹ Range Rover ati ogoji miliọnu Naira pada fun ẹni to ni.
Ọdun 2018 ni ile ẹjọ pa aṣẹ naa.
EFCC sọ pe oun ti da ọkọ ayọkẹlẹ naa pada ṣugbọn owo naa ṣi wa lọwọ oun.
Ẹni to ni awọn dukia naa, Ọgagun ofurufu Rufus Adeniyi lo pe ẹjọ tako EFCC.
Rufus Adeniyi ni oludari ẹka iṣẹ nileeṣẹ ologun ofurufu Naijiria.

Oríṣun àwòrán, efcc
Alága EFCC tó ṣe àìgbọràn sí àṣẹ ilé ẹ̀jọ́ ló yẹ́ kó lọ sí ẹ̀wọ̀n kìí ṣe Bawa - EFCC
Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria, EFCc, ti fi esi sita lori idajọ ile ẹjọ to paṣẹ pe ki wọn o ju alaga ajọ naa si ẹwọn.
Ọjọ Iṣẹgun ni adajọ ile ẹjọ giga ijọba apapọ nilu Abuja, Onidajọ Chizoba Oji, sọ pe Abdulrasheed Bawa ṣe aigbọran si aṣẹ ile ẹjọ.
Eyi niiṣe pẹlu idajọ kan ni oṣu Kọkanla, ọdun 2018, nibi ti ile ẹjọ ti paṣẹ pe ki ajọ EFCC da ọkọ ayọkẹlẹ Range Rover kan, ati ogoji miliọnu Naira pada fun ẹnikan ti wọn gba a lọwọ rẹ.
Onithun lo pe ẹjọ lati mu ki ofin gba awọn dukia rẹ pada fun.
Ṣugbọn EFCC ko ṣe bẹẹ.
Ninu atẹjade to fi sita lẹyin idajọ lọjọ Iṣẹgun, agbẹnusọ EFCC, Wilson Uwajaren sọ pe iyalẹnu ni idajọ ẹwọn naa jẹ, nitori pe o ṣafihan alaga ajọ naa gẹgẹ bi ẹni to n ṣe atilẹyin fun iwa taani yoo mu mi.
Ọgbẹni Uwajaren sọ pe ajọṣepọ to dara lo wa laarin EFCC ati ẹka idajọ, ti Abdurasheed Bawa paapaa si jẹ ẹni to ma n tẹle ilana ofin ninu ohun gbogbo to ba n ṣe.
O ni “idajọ ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2018 ọhun ti waye lọdun mẹta ṣaaju ki Bawa to di alaga ajọ EFCC.
“Iwa ọdaran aitẹle ofin ile ẹjọ, eyi to yẹ ki ijiya rẹ bọ sori ẹni to ṣẹ ẹṣẹ naa.”
Agbẹnusọ EFCc sọ pe Ọgbẹni Bawa gẹgẹ bi alaga EFCC ko ri iwe kankan gba lori idajọ naa, amọ nigba to gbọ nipa rẹ, o ti da ọkọ ayọkẹlẹ Range Rover naa pada lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹfaa, ọdun 2022.
“O si tun ti buwọlu igbesẹ lati da ogoji miliọnu to kù pada fun ẹni to ni.”
O ni o ṣeni laanu pe idajọ aigbọran si ofin ile ẹjọ waye, botilẹ jẹ pe awọn bẹrẹ igbesẹ lati dena rẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Taa ni alaga ajọ EFCC ṣaaju Abdulrasheed Bawa?

Oríṣun àwòrán, Other
Ṣaaju iyansipo Abdulrasheed Bawa ni ọdun 2021, Ibrahim Magu lo wa ni ipo naa.
Amọ Aarẹ Buhari yọ kuro ni ipo naa ni ọjọ keje, oṣu Keje, ọdun 2020.
Ẹsun iwa ibajẹ to nii ṣe pẹlu kiko owo jẹ, inakuna ati awọn ẹsun mii ni wọn fi kan Magu.
Lẹyin naa ni Buhari yan Muhammed Umar gẹgẹ bi adele alaga, titi di ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keji, ọdun 2021 ti Abdulrasheed Bawa de ipo naa.

Oríṣun àwòrán, others
Bi igbẹjọ to ju Abdulrasheed si ẹwọn ṣe lọ
Ileẹjọ giga niluu Abuja ti ni ki Ọga agba fun ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria EFCC, AbdulRasheed Bawa lọ ma gba atẹgun ni ọgba ẹwọn Kuje fun bi o ṣe kọ lati tẹle asẹ ileẹjọ
Ninu igbẹjọ ti Adajọ Chizoba Oji gbe kalẹ lọjọ isẹgun, o ni Ọga kọ eti ikun si idajọ ti ileẹjọ gbe kalẹ ni ọjọ kọkanlelogun oṣu kọkanla ọdun 2018 pe ki ajọ naa daa ọkọ ayọkẹlẹ Range Rover ati owo toto milọnu lọna ogoji naira pada fun olupẹjọ kan.
Adajọ Oji ni bi Bawa ṣe kọ lati tẹlẹ asẹ ileẹjọ lo so okun fa idajọ ti oun gbe kalẹ, ti yoo si mulẹ ayafi ti Bawa ba ṣe ohun ti ileẹjọ palasẹ ko ṣe.
Oji tun wa kesi Ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa, Usman Baba pe ko ri pe idajọ ti ileẹjọ gbe kalẹ wa si imusẹ.
Bakan an ni Adajọ Oji wọgile gbogbo ọrọ agbẹjọro fun ajọ Efcc, Francis Jirbo, eyi to ṣọ lati fi tan imọlẹ si iwa Ọga agba ajọ ọhun
Agbẹnusọ ajọ Efcc, Wilson Uwujaren ni ajọ ọhun ti setan lati wọ ẹjọ naa lọ ileẹjọ ko tẹmilọrun lati tako idajọ ti Adajọ Chizoba Oji gbe kalẹ.
“A gbe ẹjọ naa lọ ileẹjọ ko tẹmilọrun.”















