Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá pín aṣọ tuntun fún àwọn òṣìṣé

aworan

Oríṣun àwòrán, NIGERIA POLICE FORCE/FACEBOOK

Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Usman Alkali ti paṣẹ pe ki wọn pin aṣọ tuntun , akoto ibori, asọ agbọtami, afẹfẹ tajutaju ati awọn nnkan miiran fun awọn ọlọpaa saaju ẹto idibo lọdun 2023.

Aṣẹ yii wa lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa ti ra awọn ohun elo ọlọpaa tuntun lati mu ilọsiwaju ba awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọhun.

Ninu atẹjade ti alukoro ikọ ọlọpaa gbẹ jade, CSP Olumuyiwa Adejobi ṣalaye pe igbesẹ na ko sẹyin ipinnu ileṣe ọlọpaa lati ripe awọn oṣiṣe ileeṣẹ ọhun da yatọ pẹlu aṣọ tuntun, eyi ti yoo ṣe iwuri fun wọn lati ṣe isẹ wọn ni ọna to tọọ nigba ẹtọ idibo ọdun 2023 ati lẹyin eto idibo odun 2023.

aworan

Oríṣun àwòrán, NIGRIA POLICE FORCE/FACEBOOK

Usman Alkali ni nigba ti oun je ọga agba fun ikọ Ọlọpaa lorilẹede Naijiria, ohun yoo ṣe akitiyan lati ri si igbayegabdun awọn Ọlọpa lorilẹede yii.

O wa rọ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa lati daabobo iyi iṣẹ wọn ki wọn si daabo bo ẹtọ awọn ọmọ orilẹ-ede Nigeria.