Ọkọ̀ tí kò bá ti kun ọdà àwọ ọkọ̀ akérò yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní wọ gbaga òfin l'Eko - LASTMA

LASTMA

Oríṣun àwòrán, @Others

Ko si aye fun awọn awakọ ero ti ko kun ọkọ wọn ni ọda awọn pupa ati awọ yẹlo pẹlu ile dudu meji tẹẹrẹ lara rẹ gẹgẹ bi ijọba ipinlẹ Eko ṣe laa silẹ mọ loju popo ni ipinlẹ Eko.

Ọga agba ajọ igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Eko LASTMA, Ọgbeni Bolaji Ọrẹag a sọ pe ìjọba ti ṣetan lati maa gbẹsẹ le irufẹ awọn ọkọ ti ko kun ọda wọnyii loju popo nipinlẹ Eko.

Orẹagba fi kun un pe igbesẹ yii ko ni eredi meji ju ọna lati rii daju pe awọn ọkọ akero gbogbo nipinlẹ Eko tẹlẹ ilana ati aṣẹ ti de lilọ bibọ ọkọ.

Ọga agba ajọ LASTMA naa tun ṣalaye pe awọn ẹṣọ agbofinro ijọba yoo bẹrẹ si ní ṣíṣe lori igbesẹ yii lati ọjọ Aje ọjọ keje oṣu kọkanla ọdun 2022 kaakiri ipinlẹ Eko.

Oga LASTMA ni ikilọ naa waye lati rii daju pe awọn ọlọkọ ero ni ipinlẹ Eko tẹ le ilana ofin ti wa nilẹ lori atunṣe irinna ọkọ Lagos State Transport Sector Reform Law, 2018 lati lee da alaafia pada si oju popo ati lati daabo bo ẹmi ati dukia araalu.

Àkọlé fídíò, Uber Lady: Bùkátà pọ̀ lọ́rùn mi ní mo ṣe ń wa taxi akérò

O salaye pe gbogbo awọn ọkọ Danfo ati korope Lo gbọdọ kun ọda awọ yẹlo pẹlu ila dudu tẹẹrẹ meji, nigba ti awon ọkọ akero nlanla gbọdọ kun ọda awọ pupa ti ijọba fọwọsi.

O ni aṣẹ ti jade si gbogbo awọn ẹṣọ agbofinro LASTMA lati bẹrẹ si ni fi panpẹ ofin gbe gbogbo ọkọ to ba tapa si ofin yii, bẹẹni ọkọ tọwọ ba tẹ yoo wa ni gbaga ajọ naa titi di igba ti ọlọkọ naa ba ṣe ohun to tọ.