̀Irìnàjò ojú irin Abuja-Kaduna yóò gbérasọ padà nínú oṣù yìí

Abuja-Kaduna Train Service To Commence This November

Oríṣun àwòrán, @NTANewsNow

Ijọba apapọ ti sọ pe iririnajo ọkọ oju irin Abuja si Kaduna yoo gberasọ pada ninu Kọkanla ọdun 2022 yii.

Minisita eto irinna, Mu’azu Sambo lo sọ ọrọ naa lasiko to n jabọ iriju ileeṣẹ naa niluu Abuja.

O ni gbogbo eto to yẹ ni awọn ti pese loju ọna naa, amọ ko mẹnuba akoko pato ti ọkọ oju irin naa yoo bẹrẹ iṣẹ pada.

Sambo ni ileeṣẹ eto irinna ti kọ ẹkọ nla lara ikọlu ti awọn agbesumọmi ṣe si ọna oju irin ọhun ninu oṣu Kẹta ọdun 2022, eyii to mu ki wọn wọgile irinajo oju ọna ọhun ṣaaju.

Gẹgẹ bii ohun tọ sọ, ijọba ti ṣeto ti yoo mu ko rọrun fun awọn lati maa boju irinna awọn eeyan loju ọna ọhun.

O fi kun pe, pẹlu alakalẹ awọn, Aarẹ Muhammadu Buhari atawọn ti eto abo kan yoo maa wo ohun gbogbo to ba n ṣẹlẹ loju ọna ọkọ oju irin ọhun.

Idi ti a ṣe da irinajo oju ọna naa duro

Inu oṣu Kẹta ọdun yii ni ijọba da irinajo oju ọna oju irin naa duro lẹyin ti awọn agbesumọmi kọlu ọkọ oju irin to n na ọna ọhunt, nibi ti wọni ṣekupa ọgọ ta eeyan, ti wọn si tun ji ọpọ awọn mii gbe.

Lẹyin naa lawọn agbesumọmi ọhun bẹrẹ si n tu awọn ti wọn ti gbe silẹ diẹdiẹ titi di inu oṣu Kẹwaa ọdun yii.

Lasiko naa ni awọn mọlẹbi awọn ti wọn ji gbe gunle oriṣiriṣi ifẹhonuhan pe ki ijọba doola awọn eeyan awọn to wa ni ahamọ.

Sambọ pari ọrọ rẹ pe irinajo oju ọju ọhun ko ni gberasọ padatiti di igba ti ijọba yoo fi doola awọn to ṣi wa lakata awọn ajinigbe naa, ti wọn si pada sọdọ awọn mọlẹbi wọn.