Àwoͅn awakòͅ ìgboro ti fagilé ìyansͅéͅlódì oͅlóͅsèͅ kan ní ìlú Eko

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Eͅgbeͅ awoͅn awakoͅ nipinleͅ Eko , JIDWAN ti fagile iyansͅeͅlodi ti woͅn gunle fun oͅseͅ kan .
Adari eͅgbeͅ naa, Opeyemi Sulaiman lo fi iroyin naa lede ni ibudokoͅ oͅkoͅ to wa ni agbegbe Agege ni ilu Eko.
Eͅgbeͅ awakoͅ naa ni idi ti awoͅn fi gunle iyansͅeͅlodi naa ni bi awoͅn oͅmoͅ igbooro sͅe n gba owo ribiribi loͅwoͅ awoͅn lati ibudokoͅ kan si omiran.
Amoͅ, O ni awoͅn ti fagile iyansͅeͅlodi naa nitori adari awoͅn awakoͅ nipinleͅ Eko, MC Oluomo ti sͅeleri fun awoͅn pe opin yoo deba owo goͅboͅi ti woͅn n gba loͅwoͅ woͅn naa.
Bakan naa ni woͅn fikun un pe MC Oluomo ti gbe igbimoͅ kaleͅ lati tun sͅewadii bi woͅn se n gba owo goͅboͅi loͅwoͅ awoͅn awakoͅ geͅgeͅ bi owo itanran.
''Awa awakoͅ n sͅisͅeͅ bi Erin, a n jeͅun bi kokoro nitori awoͅn agbowo ode’’

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Lara awoͅn awakoͅ to soͅroͅ ni o koͅ awoͅn lominu bi awoͅn awoͅn agbowo ode sͅe n fi iya jeͅ woͅn loju popo.
Woͅn ni lati ileto kan de omiran ni awoͅn agbowo ode yii n wa, ti woͅn si n gba owo loͅwoͅ awoͅn.
Bakan naa ni woͅn ni owo itanran ti awoͅn n san ti awoͅn ba sͅeͅ ofin tun poͅju bosͅe yeͅ loͅ.
Amoͅ ninu oͅroͅ reͅ, MC Oluomo ni awoͅn awakoͅ ko gboͅdoͅ san ju 20,000 loͅ fun owo itanran lori eͅseͅkeͅseͅ ti woͅn ba sͅeͅ.
Ninu oͅroͅ reͅ, MC Oluomo ni oun ti gboͅ gbogbo eͅdun oͅkan woͅn, ti oun yoo si wa oͅna abayoͅ si.
MC Oluomo ni oun ti kesi igbimoͅ amusͅeͅya naa lati sͅe iwadii naa ni kiakia, ki awoͅn si ri iyatoͅ laaarin osͅu kan.
‘’Gbogbo awoͅn oͅmoͅ ita to n gba owo goͅboͅi loͅwoͅ awoͅn awakoͅ ni opopona Eko si Badagry yoo foju wina ofin.’’
‘’Kete ti woͅn ba ti kuro ni opopona Badagry naa ni woͅn yoo tun sͅewadii oͅna Ikorodu.
Oluomo fikun un pe ni saa ti oun, iya kankan ko ni jeͅ awoͅn awakoͅ ni ipinleͅ Eko.












