Àwọn Òbí àwọn ọmọ tí oògùn ikọ́ pa kọ̀ láti gba $20:000 owó gbà-má-bínú tíjọba fún wọn

aworan

Obi awọn aadorin omo wewe ti wọn ṣaa deede gbemimi, latari oogun Ikọ oyinbo ti wọn n sagbekale re latorile-ede India naa ti kọ lati gba ẹ̀bùn Owo gba-ma-binu eyi to je Ogun ẹgbẹrun owo dola.

Ileeṣẹ ijọba to n ri si oogun lilo to tun mojuto idagbasoke awujọ lorileede yii lo sagbekale ogun ẹgbẹrun owo dola fun awọn Obi awọn ọmo naa fun pinpin laarin ara wọn.

Aarẹ fegbe agbarijopo awọn obi, Ebrima Sanyang ṣalaye pe gbigba Owo naa ni yoo je ohun itiju sawọn Omo to pandanu emi wọn naa. Ko sai fikun wi pe titẹ wọgba Owo naa ni yoo tumo si pe awọn obi ko fẹ́ eto idajọ toyanranti fun awọn Omo naa.

Awon Obi ti pe Ajo to n gbogun ti asilo oogun lorile-ede yii lati sayipada sọrọ kan to filede saaju pe ikun omi lo sekupa awọn Omo naa.

Ati wi pe oogun oyinbo kọ lo so wọn di ero ọrun aremabo.

Ajọ naa ko gbodo gunle eto iwadi kankan ti aare egbe naa pe fun .

Ti e ko ba gbagbe, losu Kẹwaa, Ọdun yii lajo eto ilera lagbaye kilo lori irufẹ oogun Iko mẹrin -in otoọto eyi ti o n faa aisan kidirin.

Leyin igba ti iroyin ti filede pe awọn Omo wewe lorile-ede Gambia naa ṣadede dalaisan kidinrin lẹyin igba ti wọn lo oogun Ikọ bee. Ewe, ileese ti oun poogun eyiti amo si 'Maiden Pharmaceuticals', eyi to satenumo re pe Ilana ipoogun lagbaye ni oun tẹle..