Àwọn obìnrin tó n lo ọṣẹ ìṣerun àti àwọn kẹ́míkà mìí wà nínú ewu jẹjẹrẹ ilé ọmọ

Oríṣun àwòrán, GETTY
Iwadi ti fidi rẹ mulẹ pe awọn obinrin to kundun lati ma lo ọṣẹ iṣerun onikẹmika wa ninu ewu lati ni aisan jẹjẹrẹ ile ọmọ.
Eleyi jẹyọ ninu abọ iwadi ajọ to n kọ nipa eto ilera lorileede America, eyi to fikun wi pe awọn obinrin alawọ dudu lo saba ma n lugbadi aarun jẹjẹrẹ ẹnu ọna ile ọmọ nitori kẹmika lilo si irun wọn.
Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022, ni wọn gbe esi iwadii naa jade.
Wọn ṣe iwadii naa fun ọdun mọkanla, laarin o din diẹ ni ẹgbẹrun mẹrinlelọgbọn awọn obinrin to n gbe ni orileede America.
Awọn obinrin naa wa laarin ọdun marundinlogoji si merinlelaadọrin.
Afojusun iwadii naa ni lati mọ okunfa jẹjẹrẹ oyan fawọn obinrin.
Wọn ṣayẹwo awọn obinrin to din diẹ ni irinwo, o si fihan pe awọn obinrin to n lo kẹmika sirun wọn ni wọn ma ni aarun jẹjẹrẹ ile ọmọ ni ida merin ju awọn ti wọn kii lo elo irun bẹẹ.
Jẹjẹrẹ ile ọmọ jẹ aarun to wa ni ipo kẹfa lagbaye eyi ti o sa ba ma n ba awọn obinrin finra.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Mọ die ninu ami aisan jẹjẹrẹ ile ọmọ
Diẹ ninu ami jẹjẹrẹ ile ọmọ niyii:
a. Àìdá ẹ̀jẹ̀ lẹyin nkan oṣu ati igba ti ireti bibi ọmọ kobasi mo
b. Itan rirọ
c. Aarẹ ara
d. Nkan yoo ma rin ninu ara
e. Ara to fuyẹ, ati bẹẹbẹẹ lọ.
Ni ibamu pẹlu iwadi Dokita Alexandra White, ẹni to jẹ adari agba fun ajọ ijọba to n risi imọ ijinlẹ ilera ati ayika, lilọ ọsẹ oni kẹmika si irun, ma n ṣi obinrin silẹ fun aisan jẹjẹrẹ.
Eyi lo ni ko ṣẹyin awọn ohun elo inu elo irun naa bii phthalates, parabens, cyclosiloxanes ati bẹẹbẹẹ lọ.
Bakan naa lo sọ pe awọn iwadii kan to ti waye ṣaaju fihan pe o ṣe e ṣe ki aró ti awọn eeyan fi n kun irun wọn ni oriṣiriṣi awọ, to fi mọ awọn kẹmika ti wọn fi n na irun, ni nnkan ṣe pẹlu awọn omoonu to yara n gba jẹjẹrẹ mọra - paapaa jẹjẹrẹ yan ati ti ọpa to n gbe ẹyin obinrin.
Ẹwẹ, iwadii tuntun naa tun sọ pe ida ọgọta awọn obinrin to n lo awọn kẹmika yii lo jẹ alawọdudu.
Bo tilẹ jẹ pe iwadii naa ko sọ pato ẹya ti jẹjẹrẹ ile ọmọ wọpọ si ju, o ṣe e ṣe ko pọ laarin awọn alawọdudu nitori pe awọn lo n lo awọn ọṣẹ iṣerun ati kẹmika ju lọ.












