'Oyún tí mo ní pé ọ̀sẹ̀ mẹ́tàlá, ni jẹjẹrẹ ojú ara mú mi’

Dorothy Masasa ree niwaju ile kan.
Àkọlé àwòrán, Dorothy Masasa jẹ ọkan lara awọn ẹgbẹẹgbẹrun obinrin ti ayẹwo ọdọọdun fidi ẹ mulẹ pe wọn ni jẹjẹrẹ oju ara ni Malawi.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Nnkan idunnu ati ayọ ni oyun nini ma n jẹ fun ọpọ obinrin ati idile wọn.

Adura ti kaluku si maa n gba ni pe ki oyun naa lọ lai si wahala kankan.

Ṣugbọn ni ti Arabinrin Dorothy Masasa, ọrọ ko ri bẹẹ rara.

Idi ni pe inu oyun ọmọ rẹ kẹta lo wa, nigba ti awọn dokita sọ fun un pe o ni aarun jẹjẹrẹ oju ara.

Ko ti i ju nnkan bii oṣu mẹfa sẹyin lọ ti Dorothy, ọmọ orilẹede Malawi, ẹni ọdun mọkandinlogoji, lọ si Kenya lati gba itọju aisan jẹjẹrẹ to le so ẹmi ro, eyi ti wọn maa n ṣe nilana ti wọn n pe ni 'radiotherapy'

“Wọn gba mi wọle gẹgẹ bii ẹni ti wọn gbọdọ tete fun ni itọju pajawiri ni, nigba tawọn dokita ri i pe mo ni jẹjẹrẹ oju ara pẹlu oyun ọsẹ mẹtala to wa ninu mi. Wọn sọ fun mi pe oyun ati jẹjẹrẹ ko gbọdọ wa papọ.”

Bayii ni Dorothy to jẹ iya ọlọmọ mẹta ṣalaye fun BBC.

O ni awọn dokita to wa ni Malawi sọ f'oun pe awọn le ṣiṣẹ abẹ ti jẹjẹrẹ naa yoo fi kuro, ṣugbọn eyi yoo ba oyun inu oun jẹ.

Dorothy sọ pe wọn ni ti oun ko ba fẹ eyi, oun le maa gba itọju Chemotherapy, ṣugbọn o ṣee ṣe ko jẹ abirun ni oun yoo fi ọmọ inu oun bi nitori igbesẹ naa.

Dorothy gba lati lo ilana itọju Chemotherapy, titi digba to fi bimọ naa pẹlu iṣẹ-abẹ ọmọ naa ko si wa a ya abirun, ko ni abawọn kankan.

Nnkan kan ni pe, wọn yọ ile ọmọ rẹ kuro bi wọn ṣe ṣiṣẹ abẹ fun un.

Awọn apẹẹrẹ ti obinrin yoo maa ri ti jẹjẹrẹ ẹnu ọna ile aba wọle sii lara ba mu u

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nipa awọn apẹẹrẹ ti obinrin yii n ri ki wọn too ṣiṣẹ abẹ naa, Dorothy Masasa ṣalaye pe isalẹ ikun maa n dun oun.

O ni ẹjẹ maa n jade loju ara oun pẹlu, bẹẹ si ni awọn kinni kan maa n jade ti wọn yoo maa run oorun buruku (vaginal discharge).

O ni awọn kinni naa si kọ, wọn ko lọ, wọn ṣaa n jade labẹ oun ni. Nigba toun si fi lọ awọn dokita, wọn kọkọ ro pe arun ibalopọ ni.

Ṣugbọn pẹlu Chemotherapy ati iṣẹ abẹ to ṣe naa, Masasa tun ṣi nilo itọju si i lati tọju jẹjẹrẹ oju ara to n ba a finra.

Iru itọju to nilo ko si ni Malawi nigba naa, wọn ṣẹṣẹ gbe e de nibẹrẹ ọdun 2024 ni.

Eyi ni Dorothy fi darapọ mọ awọn obinrin bii ọgbọn (30), ti wọn ko lọ si orilẹede Kenya fun itọju lọsibitu kan.

Ajọ Médecins Sans Frontières (MSF) lo ṣagbatẹru irinajo wọn naa, lati le lọọ gba itọju nilana ti wọn n pe ni radiotherapy, eyi ti yoo pa awọn kokoro jẹjẹrẹ to n ba wọn finra.

Dorothy ko wọ ọkọ baalu ri, jẹjẹrẹ to n ba a ja lo fẹẹ mu un wọkọ naa lati rin irin ajo. Eyi jẹ ki ẹru maa ba a, ko kọkọ fẹẹ lọ si Kenya naa, bẹẹ ni ko si fẹẹ fi ọmọ ikoko to ṣẹṣe bi silẹ pẹlu.

"Ṣugbọn nigba ti mo ro o pe ṣebi iwosan ni mo fẹẹ lọọ gba nibẹ, mo gba ara mi niyanju pe o yẹ ki n lọ, ki n le pada wale pẹlu alaafia ati idunnu."

Nigba ti BBC ṣabẹwo si i nileewosan, ara Dorothy ko ti i le daadaa, o fuyẹ pupọ, bẹẹ lo ti ru hangogo, irun ori rẹ pẹlu ti re danu nitori itọju to gba naa.

Dorothy Masasa jẹ ọkan ninu awọn alaisan mẹtadinlọgọrin (77) ti wọn fi ọkọ ofurufu ko lọ si Kenya lati Malawi, lati tọju aisan jẹjẹrẹ oju ara ni 2022 ti iṣẹlẹ yii waye.

Kí ẹ̀rọ ìwòsàn tóó dé Malawi...

Ọgọta ọdun lẹyin ti Malawi gba ominira lọwọ orilẹede United Kingdom ni wọn ṣẹṣẹ ni ẹrọ iwosan radiotherapy wọn akọkọ, eyi ti ṣe ti ileewosan adani Blantyre Cancer Centre, ninu oṣu kẹta ọdun 2024 yii. Eyi si jẹ igbesẹ pataki ninu eto ilera orilẹede naa.

Ninu oṣu Kẹfa lo yẹ ki awọn ẹrọ miran tun de bi wọn ṣe wi, ti wọn yoo si ko wọn si ibudo National Cancer Centre ti wọn n kọ lọwọ ni olu ilu Malawi ti i ṣe Lilongwe.

Loootọ ni ọna Malawi ṣi jin bi wọn ba fẹẹ pese ilera to kun fun awọn eeyan wọn, ṣugbọn sibẹ naa, ọga ni wọn ṣi jẹ fun awọn ilu kan to wa lapa ọdọ wọn.

Ni awọn ẹkun Sahara Africa kan,o le ni ogun orilẹede ti wọn ko ni anfaani iwosan radiotherapy rara, irinṣẹ to si ṣe pataki fun itọju jẹjẹrẹ si ni.

Eyi tumọ si pe o di dandan fun ẹni ti jẹjẹrẹ ba mu lati rin irinajo olowo nla lọ sibi ti yoo ti gba itọju lapa ibo mi-in. Owo itọju pọ, ọna si tun jin réré pẹlu.

Aworan ẹrọ radiotherapy ree ninu ileewosan kan, o tan ina alawọ buluu, bẹẹ ni bẹẹdi wa nibẹ fun alaarẹ lati sun le, ẹrọ gbohun-gbohun kan naa wa nibẹ.
Àkọlé àwòrán, Oṣu kẹta ọdun yii ni Malawi ṣẹṣẹ ni ẹrọ radiotherapy rẹ.

Àwòràn àwọn jẹjẹrẹ to saaba máa ń ṣe obìnrin jù ní Malawi

Aworan eeyan to n ṣafihan irufẹ arun jẹjẹrẹ marun-un to maa n ṣe awọn obinrin ju ni Malawi. Jẹjẹrẹ oju ara ni akọkọ, ti ọyan lo ṣikeji, ọna ọfun lo ṣikẹta, Kaposi sarcoma ati eyi ti wọn n n pe ni non-hodgkin lymphoma si tẹle e.
Àkọlé àwòrán, Aworan arun jẹjẹrẹ to saaba maa n ṣe awọn obinrin ju ni Malawi, ati ìdá tí wọn ko.

Àlékún ń bá jẹjẹrẹ ojú ara

Jẹjẹrẹ oju ara lo wa nipo kẹrin lagbaaye ninu awọn jẹjẹrẹ to n ba obinrin finra.

Awọn obinrin ẹgbẹta le lọgọta (660,000) ni wọn tun ṣẹṣẹ ni arun naa bayii, bẹẹ ni eeyan irinwo din laadọta ẹgbẹrun (350,000) ni jẹjẹrẹ oju ara ti pa lobinrin gẹgẹ bi ajọ World Health Organization (WHO), ṣe fidi ẹ mulẹ.

Ileewosan Queen Elizabeth Central Hospital (QECH), to jẹ tijọba to si ti ti pẹ daadaa ni Malawi, maa n gba ọlọkan-o-jọkan awọn eeyan ti jẹjẹrẹ oju ara mu kaakiri orilẹede naa.

Dokita to n tọju awọn obinrin to si tun maa n gba ẹ̀bí,Samuel Meja, to n ṣiṣẹ fun QECH ati MSF, ṣalaye pe iṣoro nla ni jẹjẹrẹ oju ara fun ọpọlọpọ orilẹede lapa ọdọ awọn.

“Jẹjẹrẹ oju ara lo n lewaju ninu awọn eyi to n yọ awọn obinrin lẹnu fun igba pipẹ.

'' A ti ni to 75.9 ninu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan eeyan. Bẹẹ naa si ni iku lati ara aisan yii ti wa ni ida mẹrinlelaaadọta (54) ninu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan lọdun lorilẹde Malawi.

''Ai to ayẹwo ati bi arun ko-gboogun (HIV) ṣe n tan kalẹ lawọn apa ibi kan ni Sub-Saharan Africa lo n jẹ ki nnkan maa buru si i”.

Dokita Samuel Meja lo ṣalaye bẹẹ.

Ni 2018, Eswatini to wa ni Guusu Africa lo gba ipo kinni ninu awọn orilẹede ti jẹjẹrẹ oju ara ti pọju, Malawi lo tẹle e pẹlu ipo keji ti wọn gba.

Lágbàáyé, jẹjẹrẹ oju ara ń pa obìnrin kan láàárín ìṣẹ̀jú méjì

Adari ajọ WHO fun ẹkun Africa to n fipo naa silẹ bayii, Dokita Matshidiso Moeti, sọ pe laaarin iṣẹju meji, kaakiri agbaye, obinrin kan yoo ṣaa ku latari aisan jẹjẹrẹ oju ara ni.

O ni ida mẹtalelogun (23%) ninu iku yii lo n ti Africa wa.

Lati yi onka ibanujẹ yiipada, ilẹ Africa ti bẹrẹ ipolongo to pọ kaakiri, paapaa nipa abẹrẹ ajẹsara HPV to n dena jẹjẹrẹ oju ara laaarin awọn ọmọdebinrin.

Ni Lesotho, awọn ti gbiyanju gan-an lori eyi. Wọn ti fun awọn ọmọbinrin 139,000 ni abẹrẹ ajẹsara yii, o si ti wọ ida mẹtalelaadọrun (93% ) ti wọn ti kari.

Ṣugbọn awọn apa ibi kan ṣi wa l'Africa yii to jẹ bi wọn ṣe n dẹyẹ si awọn ti jejẹrẹ oju ara ba mu ti mu adinku ba iye eeyan to n gba abẹrẹ to n dena rẹ bayii.

Fun apẹẹrẹ, ni Zambia, bi ẹnikẹni ba n sọrọ nipa ohun to kan ara obinrin bii, wọn ki i fẹẹ gbọ, wọn maa n koro oju si i ni.

Ìgbẹ̀yìn ọrọ Dorothy

Ni ti Dorothy Masasa, o ti pada sile rẹ ni Malawi.

Itọju to gba ni Kenya ti fun un ni igbesi aye tuntun.

Irun rẹ tu hù pada, o le rin kaakiri pẹlu ọmọ rẹ lẹyin rẹ, o ti le fun awọn maaluu rẹ lounjẹ, bẹẹ lo n ṣiṣẹ ninu oko pẹlu.

Dorothy sọ pe oun ti mọ bayii pe jẹjẹrẹ oju ara ṣee tọju , ati pe abẹrẹ to n dena rẹ le ran awọn obinrin mi-in lọwọ ti wọn ko fi ni i lugbadi arun naa.

O loun ko ṣiyemeji lori ẹ toun fi gba abẹrẹ naa fun ọmọ oun obinrin.

“Jẹjẹrẹ oju ara fi mi lakalaka, o foju mi han mabo, mi o si ni i fẹ k'ọmọ mi obinrin foju wina iru ẹ

“Iyatọ wa ninu bi mo ṣe ri nigba naa ati bi mo ṣe wa bayii. Inu mi dun gidi pe mo ri iwosan.”

Bayii ni Dorothy Masasa wi.