Ariwo sọ nílùú Ilorin lẹ́yìn tí ìjọba wó ilé ìtajà ńlá tó jẹ́ ti èèkàn ẹgbẹ́ APC

Ọpọ eeyan lo n beere idi ti ijọba ipinlẹ Kwara fi wo ile itaja igbalode kan, to ni ọpọlọpọ sọọbu ninu to jẹ ti eekan ẹgbẹ oṣelu APC kan nipinlẹ naa, Họnọrebu Moshood Mustapha.
Ọgbẹni Mustapha yii ti figba kan ri jẹ ọmọ ile igbimọ asofin agba niluu Abuja ko to di pe o du ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ APC lọdun 2019, amọ ko wọle.
Bi awọn to n kẹdun ṣe n kẹdun, ni awọn eeyan kan yabo ibi ti ijọba ti wo ile itaja naa ti wọn si n ko gbogbo awọn dukia to wa nibẹ.
Lalẹ ọjọ Aiku, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹwaa, ọdun 2024, ni ajọ KWGIS to n mojuto bawọn eeyan ṣe n kọle sori ilẹ nipinlẹ Kwara gbe igbesẹ naa ninu abẹwo to ṣe kaakiri awọn agbegbe naa.
Alẹ ọjọ naa ni wọn gbe ọkọ katakata lọ sibi dukia ọhun, pẹlu awọn agbofinro ti wọn si da a wo lulẹ.
Laarọ kutukutu ọjọ Aje, ọṣẹ yii, ni ọgọọrọ awọn araalu tu jade, ti wọn si n yọ gbogbo awọn dukia to wa nibẹ lọ.
Bi wọn ṣe n fọ awọn ogiri ni wọn n yọ awọn irin, wọn n ko pako, ti ko si si ẹnikẹni to yẹ wọn lọwọ wo.
Awọn kan n ko nnkan ti wọn ji ko sinu ọkọ ti wọn si n ko o lọ, awọn mii si n ta ohun ti wọn ji ko nibi ile itaja ti wọn wo naa lẹsẹ kẹsẹ fun awọn onibaara wọn ti wọn wa sibẹ lati ra ọja ọpọ.
Ẹnikan ti a fọrọ wa lẹnu wo to bẹbẹ pe ka fi orukọ bo oun lasiri sọ pe, oun ti pa N120,000 lẹnu aarọ ọjọ Aje toun de ibi ti wọn ti wo ile naa.


Okan lara awọn to gba sọọbu nibẹ, Ọgbẹni Seyi, ni lotitọ ni ijọba ti ni ki awọn ko gbogbo ọja awọn kuro sugbọn oun sẹsẹ san N1.2m owo ọdun kan ni.
Ọkunrin naa ni ati ri owo gba sọọbu mii pẹlu bi gbogbo nkan ṣe wọn bayii lo n kọ oun lominu.
Awọn eeyan kan sọ pe ijọba wo ile itaja naa lati fi jẹ ẹni to ni in niya nitori aawọ to wa laarin rẹ ati gomina ipinlẹ Kwara.
Awọn mii ni ọrọ ko ri bẹẹ rara, wọn sọ pe ijọba n se atunṣe ilu ni ọna to tọ ni, pe wọn ti kọkọ wo awọn ile itaja awọn kan naa ti ko si dariwo.
Wọn ni eleyii mu ariwo lọwọ nitori ẹni to ni in naa jẹ oloselu ati abẹnugan ninu ẹgbẹ oṣelu APC.
Saaju ni ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe nitori wọn kọ ile itaja naa sibi ti ko tọ ni awọn ṣe fẹ da a wo.
Ọga agba ajọ KWGIS, Ọgbẹni Abdulkareem Babatunde Sulyman ṣalaye pe ile itaja naa wa nibi aaye tijọba maa n fi silẹ lẹṣẹ titi.
O ni ibi ti wọn kọ ile naa si tako ofin fifunni ni aṣẹ ilẹ ijọba tọdun 2013.
O tẹsiwaju pe ṣaaju ni ijọba ti wo gbogbo awọn ṣọọbu ati ile ti wọn kọ sibi ti ko tọ wi pe aparo kan ko ga ju ọkan lọ labẹ ofin.
Ọgbẹni Sulyman wa rọ gbogbo olugbe ipinlẹ Kwara pe ki wọn ye kọle tabi kọ ṣọọbu si aaye ti ijọba fi silẹ lẹṣẹ titi lati le dena dida ile wọn wo lulẹ lọjọ iwaju.















