Pàtàkì gbígbé ìkókó wọnú odò fún àwọn èèyàn kan nílẹ̀ Yorùbá àti àwọn ẹ̀yà mìí ní Naijiria

Ọmọ kekere ti iya rẹ gbe lọwọ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Awọn eeyan ti wọn n gbe ni agbegbe ti omi yi wọn ka bii awọn Ijaw, Ilaje ati awọn Ọlọṣun gbagbọ pe omi ṣe pataki si ẹda nitori pe omi ni abuwẹ ati abumu ki eeyan le wa laaye ati pe a ko le ya igbeaye wọn ya omi.

Kini o ṣẹlẹ tẹlẹ to ṣokunfa iroyin BBC yii?

Lopin ọsẹ to kọja ni fọnran fidio kan gba ori ayelujara kan, to ṣafihan awọn agbaagba kan ti wọn n gbe ikoko kan wọnu odo nipinle Osun ni eyi ti ọpọ eeyan si n sọ nipa rẹ lori ayelujara.

Eyi lo jẹ ki BBC lọ ṣe iwadii lori idi ti wọn ṣe maa n gbe ikoko wọnu omi ni awọn agbegbe kọọkan bii ti awọn to n gbe nitosi odo ni Ijaw, Ilaje ati awọn to n bọ oriṣa bii Oṣun ati Oya.

Tani awọn Ilajẹ, Ijaw ati Ọlọṣun?

Ilaje jẹ ọkan lara awọn ẹya Yoruba ni ipinlẹ Ondo to paala pẹlu Ijebu, Itsekiri, Ikale, ati Apoi Ijaw. Won tun wa ni apa ibi kan ni Doula (Cameroon), Sapele / Warri (Delta), Asejire (Oyo) ati awọn ibi kan ni ipinlẹ Eko.

Awọn Ijaw ni wọn jẹ ọkan lara awọn iran to dagba julọ ni Naijiria ti awọn mii n pe ni 'Ijo' tabi " Izon" tabi " Niger-Delta" .

Wọn n gbe leti odo ni apa kan ni ipinlẹ Bayelsa, Delta, Rivers, Akwa Ibom, Edo ati Ondo ni Naijiria. Awọn onpitan sọ pe Oru ni Babanla wọn to rin wa lati ẹkun odo nla Nile ati orilẹ-ede Chad.

Oriṣa Ọṣun jẹ ọkan lara awọn oriṣa ilẹ Yoruba ti wọn n bọ fun ibimọ ati idagbasoke iran ni ẹkun Iwọ oorun guusu Naijiria ti ojubọ rẹ si wa niluu Osogbo ti gbogbo ero kaakiri agbaye si wa n bọ lọdọọdun nipinlẹ Osun.

Osun ni itan gbagbọ pe o jẹ ọkan lara awọn iyawo oriṣa Sango.

Oloye Tansemi Ilaje Ijaw

Àwọn idi yii ni awa Ijaw ati Ilajẹ ṣe maa n gbe ikoko wa wọnu omi....

BBC ba Oloye Mercy Tansemi to jẹ agba ọjẹ olukọ ati oloye ninu iṣẹṣe ni Ijaw ni agbegbe Bolowo ni ijọba ibilẹ Ilaje Ese Odo nipinlẹ Ondo sorọ lori koko yii.

Tansemi ṣalaye pe, ko si ewu kankan fun ikoko ti wọn ba gbe wọnu odo lẹyin ti a bii. O ni igbesẹ yii ṣe pataki pupọ lati ṣe fun gbogbo ọmọ tuntun ti a ba bi ni ẹkun Ilajẹ Ijaw yii nitori pe ohun ni wọn fi maa n ki ikoko kabọ si agbegbe ti omi yika naa.

" Ọmọ ti a ba gbe wọnu odo yoo tete mọ pataki ti omi jẹ fun wa"- Tansemi ṣalaye fun BBC.

Tansemi tun sọrọ nipa iṣẹṣe to nii ṣe pẹlu bi odo ṣe yi won ka ati pataki ki ọmọ naa le mọ nipa iṣẹṣe naa ni lati kekere. O ni pe awọn kii gbe ọmọ tuntun jojolo ti o ṣẹṣe jade lati inu ẹjẹ wọnu odo bikoṣe awọn ikoko to ti dagba to bi ọmọ oṣu meji tabi ju bẹẹ lọ.

O ni pe aṣa ati iṣe wọn ni lati gbe ọmọ wọnu odo lati kekere ki ọmọ naa le tete mọ pataki awọn odo to yi won ka lagbegbe naa.

Oloye Ifayemi Elebuibon

Oríṣun àwòrán, @Yemi Elebuibon

Àkọlé àwòrán, Oloye Ifayemi Elebuibon

Kini idi ti awọn Ọlọṣun ṣe n gbe ikoko wọn wọnu odo lẹyin ibimọ?

Bakan naa ni BBC tun kan si Oloye Ifayemi Elebuibon to jẹ Araba ti ilu Osogbo to mọ nipa aṣa ati ẹsin awọn Yoruba pupọ lori ọrọ yii.

O ṣalaye pe gbogbo ẹbi ni ilẹ Yoruba lo ni aṣa ati iṣe mọlẹbi wọn to jẹmọ ẹsin koowa wọn ni eyi ti wọn n fi le ọmọ lọwọ.

Elebuibon sọ pe gbigbe ọmọ wọnu odo jẹ ọkan lara aṣa awọn idile Olosun to jẹ wi pe oriṣa Ọṣun ni wọn n bọ. O sọ pe eyi jẹ ọna kan lati fi Osun mọ ọmọ naa gẹgẹ bi oriṣa ajọbọ ti idile wọn.

Odo ni agbegbe Ilaje

Ati pe: "Gbigbe ikoko wọnu odo jẹ ọna lati mu oju ọmọ naa mọ iṣẹṣe ati aṣa idile Olọsun"

Elebuibon tun sọ pe igbesẹ naa ko mu ewu dani rara fun ikoko naa nitori pe obinrin agbalagba to ni iriri lo maa n gbe awọn ikoko naa wọnu odo ti ko jin pupọ.

O tun sọ pe igbesẹ naa jẹ ọkan lara iṣẹṣe to n fi oju ọmọ naa mọ pataki omi ati igbagbọ idile rẹ ninu oriṣa Osun ni eyi to saaba maa n waye lasiko ti ikoko naa ba wa laarin ọmọ oṣu meji si mẹfa.

Ikadii:

Yatọ si pe igbesẹ gbigbe ikoko wọnu odo jẹ ọkan lara ọna iṣẹṣe lati ṣe afihan ikoko si aṣa Yoruba; O tun jẹ ọna ti awọn kan gbagbọ pe wọn fi n da ọmọ ọkọ mọ yatọ si ọmọ ale eyi ti awọn oloyinbo n pe ni Deoxyribonucleic acid testing (DNA).

Ko tii si imọ ijinlẹ sayẹnsi kankan to ti fi idi awọn nnkan wọnyi mulẹ ati pe awọn iran kọọkan ti n pa wọn rẹ nitori ọlaju ati ẹsin miran.