Ewu wo ló wà nínú ọtí mímu?

Group of friends drinking and toasting glass of beer

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lọpọlọpọ agbegbe kakiri agbaye ni ode ariya kii dun ti ko ba si ọti nibẹ.

Fun awọn kan, ọti waini ni wọn kọkọ fi n bẹrẹ ko to kan awọn ọti lile.

Awọn mii yan lati maa mu ọti fun oniruru idi, bii ṣiṣe ajọyọ, lati pa ironu rẹ tabi lati ṣe faaji laarin ẹbi tabi ọrẹ.

Lawọn ọdun diẹ sẹyin, awọn iwadii kan fi han pe ọti - bii waini - mimu ni iwọnba dara fun ilera ẹda.

Amọ ni bayii, ajọ WHO ti sọ pe ọti mimu lewu fun ilera ẹda, yala eeyan mu ọti naa ni amuyo tabi ni iwọnba.

BBC ti ṣe ayẹwo anfani atawọn ewu to wa ninu ọti mimu.

Aisan jẹjẹrẹ ati iku aitọjọ

Close up of man pouring red wine to his wife in dining room.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iwadii kan ti ajọ WHO ṣe fi han pe 2.6 miliọnu eeyan lo ti ku kaakiri agbaye bayii latari ọti mimu.

Wọn ni nnkan bii irufẹ arun jẹjẹrẹ meje ni ọti mimu le ṣokunfa rẹ, lara wọn ni arun jẹjẹ ọmu to n ba awọ obinrin finra.

WHO fidi rẹ mulẹ pe ọti mimu ni iwọnba, eyii to jẹ iwọn lita kan abọ waini lewu gidi.

Gẹgẹ bii ohun ti WHO sọ, ko si iwọn ọti to dara fun agọ ara ẹda.

Adinkun awọn to n mu ọti

Akosilẹ WHO fi han pe bi awọn eeyan ṣe n mu ọti lagbaye ti dinku laarin ọdun 2015 si ọdun 2019.

Akọsilẹ ọhun fi han pe iye ọkunrin to n mu ọti pọ ju iye obinrin to n mu bi ọkuunrin ṣe n mu 8.2 lita ọti lojumọ nigba ti awọn obinrin n mu 2.2 lita ọti.

Awọn eeyan kan bii Anna Tait, to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelogoji ti sọ pe oun ko mu ọti mọ.

O ni “mi o lẹ sọ pe mo maa n mu ọti bẹe naa yatọ si gbogbo ọjọ ẹti.”

Tait sọ pe opin lẹyin iṣẹ loun maa n mu ọti, nigba mii oun si maa n pin igo waini pẹlu ọkọ oun.

Amọ lẹyin igba diẹ o bẹrẹ si n mu ọti naa lojojumọ.

Ni bayii to ti n ṣe ere idara, o ni oun ti n fi ọti naa silẹ, oun si ti n ri awọn iyatọ tunutn ninu aye oun lẹyin ipinnu ọhun.

O fikun pe ọpọ awọn ọrẹ oun lo maa n bu ẹnu atẹ lu oun ti oun ba kọ lati mu ọti lasiko ti oun ba wa pẹlu awọn ọrẹ oun lagbo ariya.

Ju gbogbo rẹ lọ, o ni inu oun dun fun aṣeyọri oun lati fi ọti mimu silẹ.

A woman looking at the shelf stacked with wine bottles at a super market

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ṣe awọn onimọ ijinlẹ ṣe aṣiṣe ni?

Ẹri obrinrin yii fi han pe anfani pupọ lo wa ninu ki eeyan fi ọti silẹ.

Dokita Tim Stockwell to jẹ onimọ ijinlẹ ni Candada sọ pe ko si irọ kankan ninu esi iwadii WHO.

Tim Stockwell sọ pe “ọti lewu pupọ, ewu naa si bẹrẹ ni kete ti o ba bẹrẹ si n mu.”

Onimọ ijinlẹ naa ṣe ọpọ iwadii lati tu aṣiri to wa larin iku ati ọti mimu.

Stcokwell ni aṣiṣe wa ninu iwadii to sọ ṣaaju pe anfani wa ninu ki eeyan maa mu ọti ni iwọnba.

Drunk young adult male holding glass of alcohol

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iwọntuwọnsi ni gbogbo nnkan

Amọ ṣa, pẹlu gbogbo iwadii yii na, awọn kan gbagbọ pe ko si ohun to buru ninu ki eeyan maa mu ọti ni iwọnba.

Ọjọgbọn nipa imọ iṣiro ni fasiti Cambridge nilẹ Gẹẹsi, Sir David Spiegelhalter sọ pe iwọntuwọnsi ni gbogbo nnkan.

O ni ewu wa ninu ọkọ wiwa loju popo amọ ṣe eeyan yoo tori irufẹ ewu bẹẹ fi ọkọ wiwa silẹ.

O wa gba awọn eeyan ni imọran pe wọn le maa mu ọti amọ ki wọn maṣe mu amupara.