Ìwọ́de wáyé bí ìgbẹ́jọ́ àgbẹ̀ tó fi òkú àwọn obìnrin méjì tó pa ṣe oún jẹ fáwọn ẹlẹ́dẹ̀

Àwọn tó ṣe ìfẹ̀hónúhàn níta ilé ẹjọ́
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ilé ẹjọ́ ní orílẹ̀ èdè South Africa ti bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ bóyá kí wọ́n gba béèlì àgbẹ̀ Zachariah Johannes Olivier àtàwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ méjì, Adrian de Wet tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé wọ́n pa àwọn obìnrin méjì.

Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni wọ́n ń kojú ẹ̀sùn ìpànìyàn àti pé wọ́n fún àwọn ẹlẹ́dẹ̀ ni òkú náà jẹ lẹ́yìn tí wọ́n pa wọ́n tán.

Níṣe ni àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe ìfẹ̀hónúhàn níwájú ilé ẹjọ́ ní Polokwane pé ilé ẹjọ́ kò gbọdọ̀ gba béèlì wọn.

Níṣe ni ilé ẹjọ́ kún fún ẹbí àwọn obìnrin méjì tí wọ́n pa ọ̀hún àtàwọn èèyàn àwọn tó jẹ́jọ́.

Adájọ́ májísíréètì tó ń gbọ́ ẹjọ́ náà, Ntilane Felleng fàyè gba àwọn akọ̀ròyìn láti máa ká ìgbẹ́jọ́ náà bó bá ṣe ń lọ nítorí tó jẹ́ nǹkan tí àwọn ará ìlú fẹ́ mọ̀ nípa rẹ̀.

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàkátì níbi ìgbẹ́jọ́, ó sún ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ Kẹfà, oṣù Kọkànlá kí ìwádìí fi tẹ̀síwájú si.

Ó ní kí àwọn afurasí náà ṣì wà ní àhámọ́ títí tí di ìgbà náà.

Àwọn afurasí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó ń kojú ìgbẹ́jọ́

Àgbẹ̀ yìnbọn pa obìnrin méjì, Ó tún fi òkú wọn ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹlẹ́dẹ̀

Àwòrán Maria Makgato

Oríṣun àwòrán, Àwọn ẹbí Makgato

Ìròyìn ọkùnrin aláwọ̀ funfun àgbẹ̀ kan tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó yìnbọn pa àwọn obìnrin aláwọ̀ dúdú méjì tó sì fún ẹlẹ́dẹ̀ ní òkú wọn jẹ lórìlẹ̀ èdè South Africa ló ń jà ràìnràìn lórí ayélujára.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Maria Makgato ẹni ọdún márìndínláàdọ́ta àti Lucia Ndlovu, ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ni wọ́n ní wọ́n ń wá oúnjẹ lọ sí inú oko afurasí náà tó wà ní agbègbè Polokwane, ní ẹkùn àríwá Limpopo, South Africa nínú oṣù Kẹjọ kó tó yìnbọn pa wọ́n.

Wọ́n ní afurasí náà gbé òkú àwọn ẹni náà fún àwọn ẹlẹ́dẹ̀ jẹ lójúnà àti dènà rírí ẹ̀rí pé òun ló pa wọ́n ní àkàtà rẹ̀.

Ilé ẹjọ́ ni yóò sọ bóyá wọn yóò fún àgbẹ̀ náà, Zachariah Johannes Olivier, ẹni ọgọ́ta ọdún àtàwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ méjì Adrian de Wet àti William Musora ní ìdáǹdè láti máa jẹ́jọ́ ẹ̀sùn ìpànìyàn tí wọ́n fi kàn-án láti ilé.

Ilé ẹjọ́ kò ì tíì ní kí àwọn afurasí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta láti pé ẹjọ́ láti bèèrè fín ìdáǹdè lórí ẹ̀sùn tí wọ́n ń jẹ́jọ́ lé lórí èyí tó máa wáyé lọ́jọ́ iwájú.

Níbi àwọn ìgbẹ́jọ́ tó ti wáyé sẹ́yìn, àwọn olùwọ́de tí wọ́n ń fẹ̀hónú hàn níwájú ilé ẹjọ́ ní wọn kò gbọdọ̀ fún àwọn afurasí náà ní ìdáǹdè.

Àbúrò Makgato, Walter Mathole sọ fún BBC pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣàlàyé irú ìhà tí àwọn aláwọ̀funfun àti aláwọ̀dúdú kọ sí ara wọn ní orílẹ̀ èdè South Africa.

Èyí tó peléke ní àwọn ìlú kéréje ní orílẹ̀ èdè náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti jà fún fífi òpin sí ẹlẹ́yàmẹ̀yà láàárín àwọn aláwọ̀dúdú àti aláwọ̀funfun láti bíi ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn.

Àwọn afurasí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ni wọ́n tún ń kojú ìgbẹ́jọ́ pé wọ́n fẹ́ pa ọkọ Ndlovu látàrí bí wọ́n ṣe yìnbọn ba òun náà oko ọ̀hún.

Bẹ́ẹ̀ náà ni wọn yóò tún kojú ìgbẹ́jọ́ pé wọ́n ní ìbọn lọ́wọ́ láì gba ìwé àṣẹ láti ní ìbọn.

Mabutho Ncube móríbọ́ lọ́wọ́ ikú lọ́jọ́ Kẹtàdínlógún oṣù Keje nígbà tó rí bi rá kúrò nínú oko náà lẹ́yìn tí wọ́n yìnbọn fun, tó sì kàn sí àwọn dókítà fún ìtọ́jú.

Ncube ní òun fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó àwọn ọlọ́pàá létí àti pé àwọn ọlọ́pàá bá òkú ìyàwó òun àti ti Makgato tó ti ń jẹrà ní ẹ̀ka tí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ wà ní ọgbà oko náà lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé.

Mathole tó jẹ́ àbúrò Makgato ní òun àtàwọn ọlọ́pàá rí òkú ẹ̀gbọ́n òun tí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ jẹ kù.

Makgako, Ncube àti Ndlovu ló wá àwọn oúnjẹ tí ọjọ́ ti lọ lórí wọn tàbí tó kù díẹ̀ kí ọjọ́ lọ lórí wọn lọ sí ọgbà okò náà. àwọn irúfẹ́ oúnjẹ báyìí ni wọ́n máa ń fún àwọn ẹlẹ́dẹ̀ jẹ lóko náà.

Àwọn ẹbí Makgato ní ikú rẹ̀ ba àwọn lọ́kàn jẹ́ gidi pàápàá àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún márùn-ún sí méjìlélógún.

'Ikú oró ni ìyá mi kú, ìyá tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀, tó máa ń ṣe ohun gbogbo fún wa ni'

“Ikú oró ni ìyá mi kú, ìyá tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀, tó máa ń ṣe ohun gbogbo fún wa ni. A ò kí ń ṣe àfẹ́kù ohunkóhun nítorí ìyá wa,” Ranti Makgato tó jẹ́ àkọ́bí sọ fún BBC.

Ó fi kun pé ìnú òun máa dùn tí ilé ẹjọ́ kò bá tú àwọn afurasí náà sílẹ̀ láti máa jẹ́ja láti ilé.

Ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò, Economic Freedom Fighters (EFF), ní ó yẹ kí ìjọba ti oko náà pa ni.

EFF ní àwọn kò lè máa wòran kí wọ́n máa ta àwọn èrè oko náà fún ará ìlú.

Àjọ tó ń já fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ní South Africa ti bẹnu àtẹ́ lu ìpànìyàn náà, tí wọ́n sì ń pè fún ìjíròrò tako ìwà ẹlẹ́yàmẹ́yà laáàárín àwọn agbègbè méjì tí ọ̀rọ̀ náà kàn.

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ méjì kan tó níṣe pẹ̀lú àwọn àgbẹ̀ tó ń hùwà ẹlẹ́yàmẹ̀yà sáwọn aláwọ̀dúdú ló ti kọ́kọ́ ń fa auyewuye.

Àgbẹ̀ kan àti ẹ̀ṣọ́ ààbò rẹ̀ ní wọ́n wà ní àhámọ́ ọlọ́pàá ní ẹkùn ìlà oòrùn Mpumalanga fẹ́sùn wí pé wọ́n ṣekúpa èèyàn méjì nínú oko wọn ní Laersdrift.

Ẹ̀sùn pé àwọn ọkùnrin náà fẹ́ jí àgùtàn gbé nínú oko ọ̀hún ni àwọn afurasí náà fi dáná sún wọn, tí wn sì jóná kọjá mímọ̀.

Bákan náà ni bàbá àádọ́rin kan ń kojú ìgbẹ́jọ́ ìpànìyàn àti wíwa ọkọ̀ lọ́nà àìtọ́ bí ó ṣe wa ọkọ̀ lórí ẹsẹ̀ ọmọ ọdún mẹ́fà tó fẹ́ mú ọsàn nínú oko rẹ̀.

Wọ́n ní ọmọ náà fẹ́ mú ọsàn tó jábọ́ sílẹ̀ lásìkò tí òun àti ìyá rẹ̀ ń kọjá lẹ́gbẹ oko náà kí Christoffel Stoman, tó ni oko náà tó wa ọkọ̀ lórí ẹsẹ̀ rẹ̀.