Ìjàmbá ọkọ̀ pa ọmọdé mẹ́ta, àgbàlagbà méje ní márosẹ̀ Eko sí Badagry

Aworan ijamba ọkọ

Oríṣun àwòrán, Getty image

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

O kere tan, eeyan mẹwaa lo padanu ẹmi wọn lalẹ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹwaa ọdun 2024 yii, nigba ti ijamba ọkọ kan waye loju ọna marosẹ Eko si Badagry.

Ọmọdebinrin meji, ọmọdekunrin kan, baale ile mẹta ati iyaale ile mẹrin ni awọn eeyan to di oloogbe, gẹgẹ bi ajọ Lagos State Emergency Management Agency, (LASEMA), ṣe fidi ẹ mulẹ.

Nigba to n ṣalaye nipa bi ijamba naa ṣe waye, ọga agba LASEMA, Olufemi Oke-Osanyintolu, sọ pe mọto Sienna ti nọmba idanimọ rẹ jẹ BDG 342 FS, lo n bọ lati apa ilẹ Igbo, o si ko ero pupọ sinu.

Ọga LASEMA tẹsiwaju pe ere ni Sienna naa n ba bọ, bẹẹ lo si ṣe lọọ kọlu ọkọ akoyanrin nla kan to wa loju ọna, to si ti gba idaji ọna tan pẹlu.

‘’Sienna to n sare bọ ko mọ pe ọkọ akoyanrin ti ko ni nọmba naa wa lẹba ọna, pẹlu yanrin to kun inu rẹ, bo ṣe rọlu ọkọ naa lati ẹyin niyẹn.

‘’Eeyan mẹwaa lo padanu ẹmi sinu iṣẹlẹ aburu yii,awọn mẹta mi-in si farapa’’

Osanyintolu lo sọ bẹẹ.

O fi kun un pe nnkan bii aago mọkanla alẹ ni ijamba yii waye.

Ajọ FRSC to n ri si aabo loju ọna lo doola awọn to farapa gẹgẹ bi Osanyintolu ṣe wi. Wọn ti di awọn oku mẹwaa naa sinu apo igbeokusi, wọn yoo si gbe wọn fun ẹka to n ri si imọtoto nipinlẹ Eko, fun igbese to kan, bi ọga LASEMA ṣe sọ.