“Èmi ni mo pe orò tí orò sì dáhùn, ifá ló mú mi láti máa pe orò”

Àkọlé fídíò, oro Isakete Iyoko
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Igbagbọ ọpọ eeyan nilẹ Yoruna ni pe ọkunrin lo n gbe oro, amọ niluu Iyoko, to wa ni Isakete, lorilẹede Benin, obinrin lo ni oro.

BBC Yoruba ṣabẹwo si ilu naa lati ṣe iwadii bi ọrọ naa ṣe jẹ, a si ba obinrin to pe roro sọrọ nibẹ.

Obibrin ọhun, Segi Olanise sọ pe ni ibẹrẹ pẹpẹ obinrin lo n pe oro lọdọ awọn bo tilẹ jẹ pe obinrin ko gbọdọ fi oju kan oro.

O ni obinrin le pe oro, ti oro naa yoo si da awọn lohun ṣugbọn irufẹ obinrin bẹẹ ko gbọdọ fi oju kan irufẹ oro ọhun.

Olanise sọ pe inu idile awọn obinrin to n gbe oro ni wọn bi oun si amọ wọn da ifa ti ifa naa si mu oun pe oun gan ni yoo maa pe oro naa.

Ninu ọrọ rẹ, o ni “ifa ni wọn da, mi o tilẹ si nibẹ, wọn difa, wọn ni emi ni....”

Nigba ti a kan si Alake Oro ilu naa, iyẹn Ahmadu Owolabi, o fidi rẹ mulẹ pe obinrin lo maa n pe oro nibẹ.

A tun kan si Ajana Oro ilu Iyoko, Olakunle Olanise, o ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe lootọ ni awọn n pe oro naa, wọn ko le foju kan an, nitori obinrin to ba fi oju kan oro ọhun le ya were.

O ni ti obinrin ba ti pe oro naa tan ni yoo maa salọ sile rẹ, bi bẹẹ kọ ko ni le ṣalaye ohun ti oju rẹ bari nibẹ.

Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ ohun ti a ba bọ niluu Iyoko.