Gbemisola Yusuf: Láti ẹni tó ń ta omi tútù ní Agege sí adarí eré bọ́ọ̀lù fún àjọ CAF

Gbemisola Yusuf

Oríṣun àwòrán, Gbemisola Yusuf

Àkọlé àwòrán, Gbemisola Yusuf
    • Author, Emmanuel Akindubuwa
    • Role, BBC Sport Africa
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ẹni ọdun mọkanlelogun pere ni Gbemisola Yusuf, o si ti di adari ere bọọlu ni Naijiria.

Nigba to n gba BBC sọrọ, o ni ko rọrun lati dari bọọlu ti eeyan mejilelogun n gba, iṣẹ ọhun si jẹ ohun to n mu inu oun dun.

Yusuf jẹ ọkan lara awọn adari ere bọolu ni Naijiria.

Bo tilẹ jẹ pe awọn obinrin to n ṣe adari ere ni Afrika ti pọ ju ti tẹlẹ lọ, iye ọkunrin to n ṣe iṣe naa ṣi pọ ju obinrin lọ.

Lọdun 2023, obinrin alawọ dudu mẹtalelaadọta lo n dari ere bọolu, eyii ti ajọ FIFA buwọlu.

Bi awọn obinrin alawọ dudu ṣe n pọ nidi iṣẹ naa jẹ lara aṣeyọri ajọ CAF to n pe fun idọgba laarin ọkunrin ati obirin nidi iṣẹ ọhun.

Orilẹede South Africa ati Morocco lo ni adari ere to jẹ obinrin, ti pọju ni Afrika.

Awọn obinrin to n ṣiṣẹ adari ere bọọlu ni Afrika n koju oniruru ipenija latari oju ti awọn eeyan ni Afrika fi n wo obinrin.

Gbemisola Yusuf with Zambian referee instructor Janny Sikazwe at the finals of the Caf African School Football Championship in Tanzania

Oríṣun àwòrán, Gbemisola Yusuf

Bi Gbemisola ṣe bẹrẹ aye rẹ

Agbegbe Agege, niluu Eko ni wọn bi Gbemisola si lọdun mọkanlelogun sẹyin, papa iṣere Agege to sunmọ ile wọn ni oun ati iya rẹ ti n ta ọja.

Gẹgẹ bii ọmọ kekere, o maa n tẹle iya rẹ lọ si papa iṣẹre naa lati lọ ta ohun mimu bii omi tutu ati ẹlerindodon fun awọn to n gba bọọlu ni papa iṣere naa.

Lati ibẹ lo ti bẹrẹ si n fi ifẹ han si ere bọọlu afẹsẹgba.

O kọkọ bẹrẹ gẹgẹ bii agbabọọlu ko to yan iṣẹ adari ere laayo, ti awọn mọlẹbi rẹ si fọwọ si.

Ẹni ti Gbemisola n wo gẹgẹ bii awokọse, Dele Atoun, to ti fẹyinti nidi iṣẹ adari, to tun jẹ akọwe ẹgbẹ awọn adari ere nipinlẹ Eko sọ fun BBC pe “lati kekere lo ti nifẹ lati maa lọ papa iṣere bọọlu.

“Ko bẹru rara bo tilẹ jẹ pe o maa n ri bi wọn ṣe maa n kọju ija si awọn adari ere.”

Idẹyẹsi ati idunkokomọni nidi iṣẹ adari ere

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Igba to wa lọmọ ọdun mẹrinla lo bẹrẹ si n kọ nipa iṣẹ adari ere bọọlu lasiko ti ajọ CAF gbe eto kan kalẹ lati ṣawari awọn adari ere fun ọjọ iwaju.

Bo tilẹ jẹ pe ọdọbinrin naa fẹran iṣẹ adari ere bọọlu, o mọ pe iṣẹ naa kii ṣe eyii to rọrun rara nitori ohun ti awọn ololufẹ bọọlu maa n fi oju awọn adari ere ri ni Naijiria.

Ninu iwadii kan ti ajọ Nigeria Referees Association (NRA) ṣe, o ni ida 80% awọn adari lo ti koju eebu ati iwọsi lati ọwọ awọn ololufẹ bọọlu.

Amọ ṣa, irufẹ idẹyẹsi bẹẹ maa n waye lawọn ipele bọọlu kekeke ti eto abo rẹ ko peye.

Gbemisola foju ri bi awọn eeyan ṣe maa n dunkoko mọ awọn adari ere amọ ko mikan.

O ni “mo fẹẹ le sọ pe iṣẹ adari ere ni iṣẹ to nira julọ lagbaye.

“Aarin iṣẹju perete ni o gbọdọ ṣe ipinnu lasiko ti ere ba n lọ lọwọ yala ipinnu naa tọ tabi bẹẹ kọ.”

Irawọ Gbemisola bẹrẹ si n tan nigba to wa lọmọ ọdun mejidinlogun ti adari ere kan ko yọju si papa iṣere nibi ti oun ati iya rẹ ti n ta omi tutu.

Ọjọ naa ni wọn ke si pe ko wa dari ifẹsẹwọnsẹ to n lọwọ.

Ọjọ naa lo fi ẹbun rẹ nidi iṣe naa han.

Lati ibẹ lọ, Gbemisola di ẹni to n dari ere bọọlu ni ipele Premier League awọn obinrin ni Naijiria.

Oniruru ipenija lo wa ninu ṣiṣe adari ere bọọlu ni ipele yii ni Naijiria, paapaa fun awọn obirin.

Amọ Gbemisola sọ pe ko si ifoya kankan fun oun niwọn igba ti oun ba le maa ṣe ohun to tọ ati eyii to yẹ lori papa.

O ni “mo maa ṣe iwọn ti mo le ṣe, ma a si fi iyoku silẹ fun Ọlọrun.”

Gbemisola dari ere ni Tanzania

Gbemisola Yusuf ni Caf School Championship

Oríṣun àwòrán, Gbemisola Yusuf

Àkọlé àwòrán, Gbemisola Yusuf ni Caf School Championship ni Tanzania

Fun Gbemisola, papa iṣere Agege kii kan n ṣe papa iṣere lasan, amọ o jẹ ibi to ti bẹrẹ aye rẹ gẹgẹ bii adari ere.

Bo tilẹ jẹ pe ko ta omi tutu ati ẹlẹrindodo nibẹ mọ, ko le gbagbe papa iṣere naa lailai.

Ni bayii, o jẹ akẹkọọ fasiti UNILAG, to wa niluu Eko nibi to ti n kẹkọọ nipa imọ ‘human kinetics and education.’

O ni “ohun gbogbo ti mo mọ laye mi bẹrẹ lati papa iṣere Agege.

“Ibẹ ni mo ti ni igboya lati darapọ mọ awọn adari ere bọọlu, agbegbe naa atawọn eeyan ibẹ si ṣe iwuri fun mi.”

Gbemisola ti lọ si orilẹede Tanzania ninu ọdun 2024 yii nibi to ti dari ere ninu idije African Schools Football Championship ti ajọ CAF ṣe onigbọwọ rẹ.

Lẹyin idije naa, Gbemisola sọ pe iriri naa mu inu oun dun pupọ, o si jẹ imuṣẹ ala fun oun.

O pari ọrọ rẹ pe oun ṣẹṣẹ bẹrẹ ni ati pe oun gbagbọ pe ọjọ iwaju oun yoo dara ninu iṣẹ adari ere naa.