Ìjọba àpapọ̀ kìlọ̀ fún ìpínlẹ̀ mọ́kànlá láti gbáradì fún bí Cameroon ṣe ṣí Lagdo Dam sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Nigeria Ministry of Water Resources
Ìjọba Nàìjíríà ti ṣèkìlọ̀ fún àwọn èèyàn orílẹ̀ èdè nàá láti wà ní ìgbáradì fún bí orílẹ̀ èdè Cameroom ṣe ṣí adágún odò Lagdo Dam sílẹ̀.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí adarí àjọ tó ń rí sí bí ojú ọjọ́ ṣe rí ní Nàìjíríà fi síta, Nigeria Hydrological Services Agency, Umar Muhammed, ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹsàn-án ni wọ́n ti ṣí omi náà kalẹ̀.
Àtẹ̀jáde náà ṣàlàyé pé odò Lagdo Dam yóò máa kún tó ìwọ̀n 1000m³/s fún ọjọ́ méje tó ń bọ̀.
Àjọ Nigeria Hydrological Services Agency ní àwọn aláṣẹ tó ń mójútó Lagdo Dam láti Cameroon ló kàn sí àwọn láti fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn létí.
Wọ́n ṣàlàyé pé díẹ̀díẹ̀ ni àwọn aláṣẹ ń jo omi odò náà láti ri pé wọ́n dènà kí omi náà ya wọ odò Garoua èyí tó jẹ́ odò tó ń gbé omi wọ River Benue.
Muhammed ní kò sí èwù kankan, pé kí àwọn èèyàn fi ọkàn balẹ̀, pé kò ní sí ewu nítorí odò River Benue tí omi náà máa wọ̀ wà ní iye tó ṣì wà ní èyí tí kò le fa omíyalé.
Àmọ́ ó ní èyí kò dènà pé kí àwọn ìpínlẹ̀ tó pààlà pẹ̀lú odò River Benue bíi Adamawa, Taraba, Benue, Nasarawa, Kogi, Edo, Delta, Anambra, Bayelsa, Cross Rivers àti Rivers láti gbáradì fún omíyalé.
Bákan náà ló rọ ìjọba ní gbogbo ẹ̀ka látorí ìjọba àpapọ̀, ìpínlẹ̀ àti ìbílẹ̀ láti wà ní ojú lalákàn fi ń ṣọrí láti dènà omíyalé tó lè wáyé látàrí tí omi náà bá kún ju bí ó ṣe yẹ lọ.
Ó ní àwọn yóò túnbọ̀ máa ṣe àmójútó àwọn odò náà láti mọ bí ó ṣe ń kún sí, tí àwọn yóò sì máa fi tó àwọn ará ìlú létí.
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí àwọn aláṣẹ Lagdo Dam yóò máa ṣèkìlọ̀ fún Nàìjíríà tí wọ́n bá fẹ́ ṣí odò náà kódà ọdọọdún ni wọ́n máa ń kàn sí àwọn aláṣẹ orílẹ̀ èdè yìí tí wan bá fẹ́ ṣi.
Odò Lagdo ló wà ní ẹkùn àríwá Cameroon lẹ́bàá odò River Benue ní Niger Basin.
Odò náà ló máa ń jẹ́ ohun ìkọminú fún Naijria nítorí ọ̀pọ̀ ìpínlẹ̀ ló máa ń ṣàkóbá fún tó bá wọ orílẹ̀ èdè Naijiria nítorí ó wọ odò River Benue.
Bákan náà ni ṣíṣí odò yìí jẹ́ ìkọminú fún àwọn ọmọ Naijiria nítorí omíyalé tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣọṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Borno látàrí bí odò Alau Dam ṣe ya wọ ìlú Maiduguri tí èèyàn tó lé ní ọgbọ̀n sí pàdánù ẹ̀mí wọn, táwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù kan sì di aláìnílé.
Àwọn odò Tiga àti Challawa Goje kò mú ewu kankan dání - ìjọba Kano

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nínú ìròyìn tó fara pẹ, àwọn aláṣẹ ajọ tó ń mójútó Hadejia Jama’are ní odò Tiga àti Challawa Goje ní ìpínlẹ̀ Kano wà bó ṣe yẹ kí wọ́n wà.
Àjọ náà sọ fún BBC pé àwọn ti ran ikọ̀ kan lọ sí àwọn odò náà láti mọ ipò táwọn odò náà wá lójúnà àti dènà irú omíyalé tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Borno.
Adarí àjọ náà, Ma’amun Da’u Aliyu ni àwọn kò bẹ̀rù pé omíyalé le da àwọn láàmú nítorí àwọn ti ṣe nǹkan tó yẹ kí àwọn ṣe.
Ó ní ìbẹ̀rùbojo tó gba ọkàn àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Kano ló jẹ́ kí àwọn ran ìgbìmọ̀ lọ sí àwọn odò ọ̀hún láti mọ̀ bóyá kò ní ìpalára tó lè ṣe fún àwọn ará ìlú.
Malam Da’u ní omi tó wà ní odò Tiga ju omi tó wà ní odò Alau lọ ní ìlọpo mẹ́ẹ̀dógún àti pé èyí ló jẹ́ kí àwọn gbé àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ dìde láti wo ipò tí omi náà wà báyìí.
Ó fi kun pé àwọn kò pa àwọn odò náà tì bí àwọn kan ṣe ń sọ nítorí àwọn ń ṣe àmójútó rẹ̀ láti ri pé àwọn ṣì sílẹ̀ fún àwọn èèyàn pàápàá àwọn àgbẹ̀ láti ṣàmúlò rẹ̀ tó bá di ìgbà ẹ̀rùn fún nǹkan oko wọn.












