Wo àwọn nǹkan márùn-ún tó lè bẹ́yìn yọ látàrí ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé Maiduguri

Omiyale
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ìjàmbá omíyalé, àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù tó ṣọṣẹ́ ní ìlú Maiduguri, olú ìlú ìpínlẹ̀ Borno ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ yìí jẹ́ èyí tó da onírúurú ìdààmú sílẹ̀.

Odò Alau tó wà ní ẹ̀bá ìlú Maiduguri wà lára nǹkan tó fa omíyalé náà.

Ọ̀pọ̀ ilé àti ọkọ̀ ni àgbàrá òjò náà wọ́ lọ, tí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn sì di aláìnílé lórí mọ́, tí wọ́n sì ń ṣe àtìpó ní àwọn ibùdó aṣàtìpó káàkiri.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Borno, Babagana Zulum ní ó lé ní èèyàn mílíọ̀nù méjì tí àgbàrá òjò náà ṣọṣẹ́ fún.

Ọ̀pọ̀ àwọn òkú tí wọ́n sin sínú ilẹ̀ ni omíyalé náà hú jáde, tí ọ̀pọ̀ òkú sì ń ṣàn káàkiri agbègbè.

Akọ̀ròyìn BBC ní ìlú Maiduguri sọ pé níṣe ni àwọn òkú lé téńté sórí omi tó ń ṣàn.

Bákan náà ni àwọn ìdọ̀tí kún gbogbo ìgboro látara àwọn àkìtàn tí omíyalé ọ̀hún ti ṣàn káàkiri.

Èyí ló ń fa ìbẹ̀rùbojo sọ́kàn àwọn èèyàn pé ṣé nǹkan ńlá mìíràn kò ní ti ẹ̀yìn omíyalé yìí jáde.

Èyí lọ mú BBC ṣe àkójọpọ̀ àwọn nǹkan tí omíyalé yìí le bí bí àwọn èèyàn àti ìjọba kò bá tètè ṣe àmójútó tó yẹ lásìkò.

1. Àjákalẹ̀ àìsàn

Omiyale

Níbikíbi káàkiri àgbàyé tí ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé bá ti ṣẹlẹ̀, ohun kan tó máa ń sábà jẹ́ ìààmú ni àjákalẹ̀ àìsàn tó ní í ṣe pẹ̀lú omi àti àyíká.

Dókítà Muhammad Salihu Kwaifa ní ọ̀pọ̀ àìsàn ní èèyàn lè kó látara omi tí ìdọ̀tí bá ti kó sínú rẹ̀, tí èèyàn sì lo omi náà.

Ó ṣàlàyé pé agbègbè tí omi àti ìdọ̀tí bá wà máa ń fa kí ẹ̀fọn pọ̀ ní agbàgbà náà. ó ní ó ṣeéṣe kí àwọn àìsàn tí ẹ̀fọn máa ń fà pọ̀ ní Maiduguri lásìkò yìí látàrí omíyalé náà .

Bákan náà ló fi kun pé àwọn àìsàn tí ìrònú máa ń bí wá lè ṣẹ́yọ látara bí àwọn èèyàn bá ṣe ń ronú àswọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí wọn.

Ó ka àwọn àìsàn bíi kọ́lẹ́rà (Àìsàn onígbáméjì), Ibà typhoid, Hepatitis A, Ibà Dengue, Inú rírun àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ bí i àwọn àìsàn tó lè ṣẹ́yọ lẹ́yìn ìjàmbá omíyalé yìí.

Ó fi kun pé èèyàn tún lè farapa nígbà tí wọ́n bá ń ti ẹsẹ̀ bọ omi àgbàrá láì mọ bóyá kòtò tàbí nǹkan tó lè pa èèyàn lára tó wà níbi tí èèyàn bá ń ti ẹsẹ̀ bọ̀.

Ìdènà àjákalẹ̀ àìsàn

Dókítà náà ṣàlàyé pé nǹkan àkọ́kọ́ tó yé kí àmójútó wà fún láti dènà àjàkálẹ̀ àìsàn ni pípèsè ibùgbé fáwọn èèyàn kí wọ́n yé rìn kiri.

Lẹ́yìn náà ni Dókítà Kwaifa ní kí wọ́n ri dájú pé omi tí àwọn èèyàn yóò máa mu lá[sikò náà jẹ́ omi tó mọ́ dáadáa. Ó ní wọ́n le se omi tí wọ́n bá fẹ́ mú dada kí wọ́n lè dènà àjàkálẹ̀ àìsàn.

Ó sọ pé àwọn èèyàn nílò láti máa wọ aṣọ tó da, tí yóò dá ààbò bò wọ́n lọ́wọ́ òtútù àti àìsàn.

Jíjẹ oúnjẹ tó ní àwọn èròjà aṣara lóore, fífi àwọ̀n ẹ̀fọn sùn, pípèsè oògùn ibà àtàwọn nǹkan wà lára àwọn nǹkan tí dókítà náà ka kalẹ̀ láti dènà àjàkálẹ̀ àìsàn.

2. Ebi

Ọmọde ti ebi ṣọṣẹ fun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìjọba ìpínlẹ̀ Maiduguri ní èèyàn mílíọ̀nù méjì ni omíyalé ti ṣàkóbá fún, tí ọ̀pọ̀ wọn sì ti ń gbé ní ibùdó àwọn aṣàtìpó.

Akọ̀ròyìn BBC tó wà ní Maiduguri ní ibùdó aṣàtìpó márùn-ún ni ìjọba ti ṣí fún àwọn tó ti pàdánù ilé wọn.

Ẹ̀wẹ̀, tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ibùdó aṣàtìpó, ebi jẹ́ nǹkan àkọ́kọ́ tó máa ń jẹ́ ìpayà fún àwọn tó wà níbẹ̀ nítorí àìsí oúnjẹ tó bó ṣe yẹ.

Àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní Nàìjíríà, NEMA àti ìjọba ìpínlẹ̀ Borno ti bẹ̀rẹ̀ sí ní pín ohun èlò ìrànwọ́ fún àwọn èèyàn tó wà ní ibùdó náà.

Àmọ́ àwọn èèyàn tó wà nínú ibùdó náà tó bá BBC sọ̀rọ̀ kọminú lórí bí ebi ṣe ń pa àwọn tọmọtọmọ.

Obìnrin kan sọ fún BBC pé láti alẹ́ àná tí òun àtàwọn ọmọ òun ti dé ibùdó náà, àwọn kò ri oúnjẹ kankan jẹ di ọjọ́ kejì.

Ìdí nìyí tí Dókítà Kwaifa fi ní ó ṣeéṣe kí àìsàn ìta tún bẹ́ sílẹ̀ níbẹ̀ pàápàá fún àwọn ọmọdé.

Ìpínlẹ̀ Borno wà lára àwọn ìpínlẹ̀ ní ẹkùn àríwá Nàìjíríà tó ń kojú ìṣòro àìrí oúnjẹ jẹ tó ṣaájú àsìkò yìí.

Ìdènà ebi

Dókítà Kwaifa ní ìpèsè oúnjẹ púpọ̀ fún àwọn tó wà ní ibùdó náà ni ọ̀nà láti dènà ebi ọ̀pàgbà fọwọ́ mẹ́kẹ́ tó le bá àwọn èèyàn fínra.

Ó ní “ìjọba àti àwọn àjọ nílò láti ṣe ìrànwọ́ fáwọn èèyàn nílò láti pèsè oúnjẹ lapọ̀ yanturu fáwọn èèyàn láti dènà àjàkálẹ̀ àìsàn fáwọn ọmọdé.”

3. Àlékún ìpàdánù ẹ̀mí

Bí ìṣẹ̀lẹ̀ omiyale náà ṣe ṣọṣẹ́ sí

Oríṣun àwòrán, AFP

Àjọ tó ń rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní Nàìjíríà, NEMA ní èèyàn mẹ́tàdínlógójì ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn látàrí omíyalé tó wáyé náà.

Bẹ́ẹ̀ náà ni ìfoyà wà pé ó ṣeéṣe kí àwọn èèyàn tún pàdánù ẹ̀mí wọn si látara àwọn àìsàn tí wọ́n máa kojú lórí omíyalé náà.

Àjọ tó ń rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Borni ní ó ṣeéṣe kí ọ̀pọ̀ èèyàn há sínú ilé wọn àti pé àwọn tó máa ń hùwà kò tọ́ le lo ìṣẹ̀lẹ̀ náà láti fi hùwà láabi.

Dókítà Kwaifa kọminú pé àwọn ìwà ọ̀daràn bíi ìfipábánilòpọ̀ le gbilẹ̀ si pàápàá ní àwọn ibùdó aṣàtìpó tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń gbé báyìí.

Àwọn ìgbésẹ̀ tó yé láti gbé

Kí ìjọba àtàwọn àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ ṣe àrídájú rẹ̀ pé ẹnikẹ́ni kò há sínú ilé kankan.

Àwọn àjọ ti ìjọba àpapọ̀ àti ti ìpínlẹ̀ ní àwọn ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti ri pé àwọn rí gbogbo àwọn èèyàn tó wà nínú ilé wọn gbé jáde.

Wọ́n ti pèsè àwọn ọkọ̀ ojú omi láti fi ṣe èyí.

Bákan náà ni NEMA ní àwọn ti pèsè ilé ìwòsàn sáwọn ibùdó aṣàtìpó láti ṣe ìrànwọ́ fún àwọn tó bá ní ìpèníjà ìlera.

4. Ilé dídàwó

Báwọn ilé ṣe kún fún omi

Oríṣun àwòrán, AFP

Olórí àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì, NEMA, Hajiya Zubaida Umar sọ fún BBC pé ìdá ogójì nínú ìdá ọgọ́rùn-ún ìlú Maiduguri ni ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé náà ṣọṣẹ́ fún.

Ó ní ọ̀pọ̀ ilé ni omi mù dẹ́nu, tí àwọn èèyàn kò lè ríbi sá sí níbẹ̀.

Onímọ̀ ẹ̀rọ kan, Ọ̀mọ̀wé Saidu Abdullahi ṣèkìlọ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn ilé náà ló le dàwọ lẹ́yìn tí àgbàrá náà bá dawọ́.

Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn ilé náà ló ti mu omi yo, tó sì ṣeéṣe kí wọ́n má dúró dada mọ́ lẹ́yìn tí àgbàrá ọ̀hún bá lọ tán

Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ àwọn ilé tí wọ́n ń kọ́ lóde òní ni wọn kìí tẹ̀lé ìlànà àtàwón nǹkan tó yẹ kí wọ́n lò láti fi gbé ilé dúró.

Ọ̀mọ̀wé Abdullahi ní ó ṣeéṣe kí àwọn ilé náà máa mì tàbí là tó jẹ́ àmì pé ilé náà fẹ́ dàwó.

Dídènè ilé dídàwó

Ọ̀mọ̀wé Abdullahi ní tí àwọn bá ti ń ri pé ilé wọn ń ṣàmì pé ó lè dàwó, kí àwọn èèyàn kúrò níbẹ̀ lẹ́ṣẹ̀kẹsẹ̀ ló tọ́.

Ó ní àwọn ohun èlò kan wà tí ó máa ń ṣe àfihàn bí ilé bá ṣe dúró dáadáa sí.

Ó rọ àwọn èèyàn láti ṣàmúlò àwọn ẹ̀rọ láti fi ṣàyẹ̀wò ilé wón kí wọ́n tó padà síbẹ̀.

Bákan náà ló ní kí àwọn ṣe àtúnṣe àwọn kòtò ìdominù wọn láti dènà ìjàmbá bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.

5. Ìjàmbá látọwọ́ àwọn ẹranko

Àwòrán ejò

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé yìí kan ibùdó àwọn ẹranko tó wà lẹ́bàá Maiduguri.

Àwọn aláṣẹ ní ìdá ọgọ́rin àwọn ẹranko ibẹ̀ ló kú, tí omi sì gbé àwọn yòókù wọnú ìgboro.

Èyí ti ń mú ìbẹ̀rù gba ọkàn àwọn èèyàn pé àwọn ẹranko náà lè ṣe àwọn èèyàn í ìjàmbá.

Dókítà Kwaifa ní lára àwọn ẹranko tó lè ṣe ìjàmbá fáwọn èèyàn ni ejò, àkeèké, àtàwọn ẹranko míì tó lè gbé nínú omi.

Ó fi kun pé àwọn ẹranko yìí tún lè fa àìsàn kalẹ̀.

Ìdènà rẹ̀

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ì tíì sí ìròyìn kankan pé ẹranko kankan ṣe èèyàn ní ìjàmbá láti ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti wáyé, àwọn èèyàn nílò láti wà ní ojú lalákàn fi ń ṣọ́rí.

Dókítà Kwaifa gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn láti ṣọ́ra fún títi ẹsẹ̀ bọ omi láti lè dènà títẹ àwọn ẹranko mọ́lẹ̀.

Ó ní tó bá pọn dandan fún àwọn èèyàn láti ti ẹsẹ̀ bọ omi, wọ́n nílò láti wọ bàtà tó máa dá ààbò bo ẹsẹ̀ wọn, kí wọ́n sì ri dájú láti wọ bàtà gígùn.