Wo nǹkan mánigbàgbé márùn ún tó ṣẹlẹ̀ níbi omíyalé Maiduguri ní ìpínlẹ̀ Borno

Iṣẹlẹ omiyale ti ba ọpọ dukia jẹ nipinlẹ̣ Maiduguri, bẹẹ lo tun mu ọpọ ẹmi lọ.
Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni Naijiria, NEMA sọ pe eeyan mẹtadinlogoji lo ti padanu ẹmi wọn, nigba ti ijọba ipinlẹ naa ni miliọnu kan eeyan ni iṣẹlẹ ọhun pa lara.
Iroyin ni iṣẹlẹ yii ni eyii to buru julọ iru rẹ ti yoo waye lati ọgbọn ọdun ṣeyin ni Borno, iyẹn lasiko ti adagun omi Alau faya lọdun 1994.
Iṣẹlẹ omiyale ti ọdun 2024 yii lo n waye lẹyin ti adagun odo Alau yii kan naa kun akun faya latari ojo arọrọda alẹ ọjọ Aje.
Eyii ni akojọpọ awọn ohun manigbagbe to ṣẹlẹ latari iṣẹlẹ omiyale yii.
Omi yabo ọgba ẹranko, gbe ọpọ ẹranko lọ

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ọgba ẹranko Sanda Kyarimi Park wa lara awọn ibi ti omi gbe lọ, bẹẹ ni omi naa tun gbe ọpọ ẹranko kuro ninu ọgba naa pẹlu.
Atẹjade kan lati ọwọ awọn alaṣẹ ọgba ẹranko naa sọ pe ida 80% awọn ẹranko to wa ninu ọgba naa lo ti jade laye, lara wọn ni kiniun ati ọni wa.
Atejade ọhun sọ pe “ọpọ awọn ẹranku buburu bii ejo ati ọni ni omi ti gbe jade ninu ọgba naa si adugbo wa.”
Amọ lasiko ti a n ko iroyin yii jọ, a ko tii gbọ pe ẹranko kankan ṣe araalu ni ijamba.
Ṣe lootọ ni awọn ẹlẹwọn 200 salọ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹnikan to jẹ olugbe ilu Maiduguri sọ fun BBC pe agbara omi ya bo ọgba ẹwọn ilu ọhun.
O ni “iwaju ọgba ẹwọn naa ni mo wa bayii, omi ti gba gbogbo ibẹ, bẹẹ ni ọpọ ọkọ ayọkẹlẹ ti ha sinu omi naa laarin adugbo.”
Lẹyin ọrọ ọkunrin ọhun ni iroyin gbode pe nnkan bii igba lara awọn ẹlẹwọn naa ti salọ.
Ẹwẹ, ileeṣẹ ijọba to n ri si ọgba ẹwọn ni Naijiria ti sọ pe lootọ ni omi gba ọgba ẹwọn naa amọ ko fidi rẹ mulẹ boya lootọ ni awọn ẹlẹwọn salọ abi bẹẹ kọ.
Agbara omi gba aafin Shehu ilu Borno

Oríṣun àwòrán, FGN
Fidio atawọn aworan aafin Shehu Borno ti gba ori ayelujara pẹlu bi omi ṣe gba aafin naa.
Ninu fidio ọhun ni a ti ri igbakeji Aarẹ Naijiria, Kashim Shettima ninu agbara omi eyii to de orokun rẹ.
Nigba to n gba awọn eeyan sọrọ nibẹ, Shettima sọ pe “a maa ri daju pe a nu omije yin nu.”
Aisan kọlẹra n kan ilẹkun
Ajọ UN ti sọ pe o ṣeeṣe ki arun kọlẹra bẹ silẹ ni agọ awọn alairilegbe to wa niluu Maiduguri.
Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ naa ti sọ pe oun ṣi agọ Bakassi fun awọn ti iṣẹlẹ omiyale naa gba ile lori wọn.
Ajọ UN ti wa sọ pe awọn eeyan naa nilo ounjẹ, omi to mọ geere ati ile.
O ni idọti ti da pọ mọ omi ti awọn eeyan naa n mu tẹlẹ, eyii si le yọri si oniruru aisan fun awọn eeyan ọhun.
Ojo mii ṣi n bọ
Ni bayii ti awọn eeyan ṣi n daro itu ti ojo yii pa ni Maiduguri, ajọ to n ri si ọrọ oju ọjọ ni Naijiria, Nigerian Meteorological Agency ti sọ pe ojo pẹlu ara ọlọjọ mẹta n bọ kaakiri Naijiria, eyii ti ko ni yọ ipinlẹ Maiduguri silẹ.
Lara awọn agbegbe ti ojo ati ara naa yoo kọlu ni Borno, Adamawa, Taraba, Yobe, Katsina, Sokoto ati Kadunaa.
Ajọ NiMet sọ pe awọn ipinlẹ ti ara yoo ti san ni Kano, Katsina, Kaduna, Zamfara, Kebbi ati Jigawa.
Ẹwẹ, NEMA ti ni apapọ eeyan 229 ni omiyale ti ṣekupa ni Naijiria lati ibẹrẹ ọdun 2024.















