Ilé ẹjọ́ gba béèlì àwọn tó kópa níbi ìwọ́de ‘Ebi ń pa wá’ pẹ̀lú N10 mílíọ̀nù fún ẹnìkọ̀ọ̀kan

Awon Oluwode

Oríṣun àwòrán, @End Bad Governance

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ile ẹjọ giga nilu Abuja ti sọ pe wọn le gba beeli awọn to kopa ninu iwọde ‘Ebi n pa wa’ #End Bad Governance’ to waye loṣu to kọja pẹlu miliọnu mẹwaa fun ẹnikọọkan.

Ẹsun ti wọn fi kan awọn Oluwọde naa ni pe wọn fẹ doju ijọba Aarẹ Bola Tinubu bolẹ laarin ọjọ kini si ọjọ kẹrin, oṣu kẹjọ, ọdun 2024.

Adajo emeka Nwite tun sọ pe awọn ti yoo gab oniduro ẹnikọọkan gbọdọ ni ile ni Abuja ti yoo ko iwe ile naa sile yatọ si pe yoo bura ọn\a to fi n ri owo rẹ.

Bakan naa ni ile ẹjọ tun paṣẹ pe oniduro ẹnikọọkan wọn yoo tun maa gbe Abuja to jẹ olu ilu Naijiria ti yoo tun fi iwe irinna rẹ silẹ pẹlu fọto rẹ mẹta.

Adajo Nwite tun paṣẹ fun awọn Oluwọde naa lati maṣẹ kopa ninu iwọde kankan mọ titi igbẹjọ wọn yoo fi pari lasiko ti ọga agba agbofinro n sọ pe ki wọn mase fi wọn silẹ.

Adajọ tun sọ pe ki wọn si wa ni ahamọ titi ti wọn yoo fi yanju gbigba beeli wọn.

Esun iditẹ gabjọba lasiko iwọde ni wọn fi kan awọn oluwode naa.

Ile ẹjọ ti mu ọjọ kétadinlọgbọn, oṣu kẹsan an, ọdun 2024 lati bẹrẹ igbẹjọ wọn.