Tinubu ti já aráàlú kulẹ̀, kò fẹ́ ẹ̀ sí ìyàtọ̀ làárín rẹ̀ àti Adolf Hitler - Gani Adams

Iba Gani Adams ati Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, The Office Of Ààre Onakankafo Of Yoruba Land Iba Gani Adams/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ Ona Kakanfo Ile Yoruba, Iba Gani Adams ti sọ pe Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti ja iretu araalu kulẹ lẹyin ti wọn fi ibo wọn gbe de ori alefa tan.

Gani Adams lo sọ ọrọ naa ninu lẹta kan to kọ si Tinubu, eyi to fi lede lori ikanni ibanidọrẹ rẹ lori ayelujara.

O ni ọpọ araalu lo kọkọ ri Tinubu gẹgẹ bii ‘Mesiah’ ti wọn n reti lati gba wọn lọwọ iya lai mọ pe ọpalamba iya gan ni Tinubu yoo fi jẹ awọn.

Adams sọ pe “ki a ma parọ, Aarẹ, ẹ ti ja ireti araalu to ri yin gẹgẹ bii olugbala ti wọn n reti kulẹ.”

Ninu ọrọ rẹ, o ni igba naira ni wọn n ta lita epo bẹntiro kan ti dọla si naira si jẹ N740 ṣaaju ijọba Tinubu amọ lẹyin to goti alefa tan, jala epo kan ti di ẹgbẹrun kan naira bayii ti dọla si naira si jẹ N1,600.

Gani sọ pe bo tilẹ jẹ pe minisita eto iṣuna ati gomina CBN jẹ awọn to ba Tinubu lasiko rẹ gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Eko ti wọn si ṣe daadaa amọ bayii niṣe lo da bii pe wọn ko mọ nnkan ti wọn n ṣe mọ.

Wo awọn koko to wa ninu lẹta Gani Adams si Tinubu

Aworan lẹta Gani Adams si Tinubu

Oríṣun àwòrán, Iba Gani Adams/Facebook

  • Eto ọrọ aje Naijiria ti dẹnukọlẹ, ọpọ lo ro pe nnkan yoo pada bọ sipo lẹyin ijọba Aarẹ ana, Muhammadu Buhari, ṣugbọn kaka ko san lara iya ajẹ niṣe lo n fi gbogbo ̣ọmọ rẹ bi obinrin
  • Owọngogo owo epo bẹntiro ati iye ti wọn n ṣe owo dọla si naira; epo gbowo lori bẹẹ ni araalu ko ri epo naa ra lasiko to yẹ, gbogbo rẹ lo buru ju atẹyinwa lọ
  • Eto abo to dẹnukọlẹ ti ọpọ ro pe yoo pin lori ijọba Buhari tun buru jai siwaju si
  • Ijọba n fi ṣikun ofin mu awọn olufẹhonuhan, o si n fi ẹsun ti ko tọ kan wọn, bẹẹ lo n tẹ ẹtọ araalu loju mọlẹ
  • Bi epo ṣe gbowo lori dabi igba ti ijọba mọọmọ n kọju ija si araalu ni, ko si yẹ ko ri bẹẹ
  • Ko fẹ ẹ si iyatọ kankan laarin ijọba Bola Tinubu ati ijọba Adolf Hitler, ewu nla lo n bẹ loko longẹ ti ijọba Naijiria ba tẹsiwaju ninu awọn igbesẹ to n gbe lọwọ yii
  • Tinubu gbọdọ tẹti si igbe awọn ọmọ Naijiria ko si yi awọn igbesẹ aninilara to n gbe pada ni kankan