Kókó mẹ́jọ tó jáde nínú ètò àríyànjiyàn tó wáyé láàrin Donald Trump àti Kamala Harris

Donald Trump ati Kamala Harris

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Jeremy Howell
    • Role, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Igbakeji Aarẹ ilẹ Amerika, Kamala Harris to ti n dije dupo aarẹ ni Amerika ni oun ati Donald Trump to ti jẹ aarẹ Amerika tẹlẹ jọ gbena woju ara wọn ninu eto idije itagbangba lori ẹrọ amohunmaworan.

Lalẹ ọjọ Isegun ni eto naa waye lori amohunmaworan ile ise ABC ni Philadelphia Constitution Center.

Eto idibo lati yan aarẹ tuntun dipo Joe Biden ni America yoo waye loṣu kọkanla ọdun 2024 yii.

Kini Kamala Harris ati Donald Trump sọ?

Harris mẹnuba ọpọ ero ti ko ni itumọ to n tẹle Donald Trump kaakiri ibi eto ipolongo rẹ ati nibi olu ileeṣẹ ipolongo rẹ.

Ọpọ gba pe eto ariyanjiyan to waye yii ṣẹnure fun Kamala Harris nitori awọn mejeeji sọrọ lori koko bii oyun ṣiṣẹ, eto ọrọ aje, owo ori gọbọi,

Kókó tó jáde níbẹ̀:-

Kamala ati Donald tako ara wọn pe ẹnikini n parọ mọ ẹnikeji.

Lori ọrọ orilẹ-ede Isreal:-Trump ni ogun Isreal yoo pari ni kete ti oun ba di aarẹ ṣugbọn Kamala sọ pe orilẹ-ede meji ni yoo jade nibẹ ti oun ba di aarẹ.

Ni ipari, Harris sọ pe oun n woye ọjọ iwaju rere fun Amerika nigba ti Trump sọ pe orilẹ-ede naa ti n ṣubu lulẹ.

Tim Walz to n dije fun ipo igbakeji Kamala sọ pe Harris fi iran ọjọ iwaju rẹ han nogba ti JD Vance to n dije dupo igbakeji Donald Trump sọ pe ete lasan ni gbogbo ẹ.

Kete ti ijiroro yii pari ni olorin takasufe Taylor Swift ti yan Harris loju opo Instagram rẹ pe yoo jẹ adari to lẹbun.

Lori Oyun Siṣẹ: Trump sọ pe ipinlẹ yoo sọ lori rẹ nigab ti Harris mẹnuba Project 2025 to si ni fifofinde nkan ko fun awon obinrin ni agbara lati yan ohun to wu wọn.

Harris sọ pe apaṣẹ to maa yan Trump jẹ lounjẹ ọsan ni Putin jẹ ṣugbọn Trump sọ pe Harris ni igabkeji aarẹ to buru ju ninu itan ilẹ America.

Ta ni yóò mókè láàárín Harris àti Trump níbi ìtàkurọ̀sọ tí yóò wáyé lọ́la ṣaájú ìbò ààrẹ Amẹrika?

Aworan Kamala Harris ati Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìjíròrò láàárín àwọn olùdíje sípò Ààrẹ ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà yóò tún wáyé ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun tó ń bọ̀, tó sì jẹ́ àkọ́kọ́ irú rẹ̀ tí yóò wáyé láàárín Donald Trump àti Kamala Harris.

Ìpàdé ìta gbangba náà jẹ́ èyí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ máa ń wò lórí tẹlifíṣàn tó sì máa ń ní ipa lórí bí àwọn bí àwọn ènìyàn ṣe máa ń dìbò ní Amẹ́ríkà.

Kamala Harris jẹ́ ẹni tó mọ ìjíròrò ìpàdé ìta gbangba ṣe dáadáa àmọ́ Donald Trump náà ti ṣàfihàn ara rẹ̀ bí i ẹni tí kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn rárá níbi àwọn tó kópa lọ́dún 2016 àti 2020.

Ìgbà wo ni ìpàdé ìta gbangba náà yóò wáyé àti pé àwọn òfin wo ló dè é?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ní ọjọ́ Kẹwàá, oṣù Kẹsàn-án ni ìpàdé ìta gbangba náà wáyé ní Philadelphia, tí yóò sì bẹ̀rẹ̀ ní aago mẹ́sàn-án alẹ́.

Èyí ni ìpàdé ìta gbangba kejì tí yóò wáyé fún ti ètò ìdìbò sípò Ààrẹ ọdún 2024. Nínú oṣù Kẹfà ni àkọ́kọ́ wáyé láàárín Donald Trump àti Ààrẹ Joe Biden kó tó di pé Biden pinnu láti má díje fún sáà kejì.

Àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn tó máa gbé ipde ìta gbangba náà ni iléeṣẹ́ ìròyìn ABC, ABC News Live, Disney+ àti Hulu.

Ìṣẹ́jú méjì ni atọ́kùn máa ń fún olùdíje kọ̀ọ̀kan láti dáhùn ìbéèrè tí wọ́n bá bi í àti láti fi jiyàn nǹkan tí ẹlòmíràn bá sọ nípa rẹ̀.

Wọ́n máa ń pa gbohùngbohùn ẹnìkejì nígbà tí ẹnìkan bá ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, tí kò sì ní sí àwọn olùwòran nínú gbọ̀ngàn tí wọ́n ti ń ṣe ìjíròrò náà.

Harris ń fẹ́ kí wọ́n tan gbohùngbohùn àwọn títí tí ìjíròrò náà máa fi parí àmọ́ tó padà gbà láti tẹ̀lé òfin náà.

Ọdún kẹrin sẹ́yìn ni wọ́n ṣe òfin náà látàrí bí wọ́n ṣe ń gba ọ̀rọ̀ mọ́ ara wọn lẹ́nu, tí ọ̀rọ̀ sì fẹ́ ẹ̀ la ìjà lọ lásìkò ètò ìjíròrò àkọ́kọ́ tó wáyé láàárín Trump àti Biden.

David Muir àti Lindsey Davis tí wọ́n ń ká ìròyìn ní iléeṣẹ́ ABC ló máa ṣe atọ́kùn ètò ìjíròrò náà lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.

Àwọn àmúyẹ wo ni Kamala Harris ní gẹ́gẹ́ bí olùkópa níbi ìjíròrò náà?

Kamala Harris nibi eto ijiroro lodun 2003

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Láti ọdún 2003 ni Kamala Harris ti ń kópa nínú ìjíròrò ìpàdé ìta gbangba nígbà tó ń díje láti di agbejọ́rò àgbà ẹkùn San Francisco.

Bákan náà ló tún kópa nínú àwọn ìjíròrò nígbà tó díje fún ipò agbejọ́rò àgbà fún California àti ipò sẹ́nétọ̀ fún California.

Ó kópa nínú ìjíròrò pẹ̀lú Joe Biden láti díje fún tíkẹ́ẹ̀tì ẹgbẹ́ Democrat lọ́dún 2019, tó sì tún kojú Mike Pence fún ipò igbákejì Ààrẹ lọ́dún 2020.

Harris ti ṣàfihàn pé òun lágbára láti ní ìkapá lórí nǹkan tó bá ń ṣe.

Ó ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrírí nípa ṣíṣe ìjíròrò gẹ́gẹ́ bí aṣòfin àti gẹ́gẹ́ bí olùpẹjọ́ ìjọba ní California.

Ó lè lo àwọn àwọn ìrírí yìí láti fi tako Donald Trump níbi ìjíròrò yìí.

Níbi ìjíròrò yìí, ó ṣeéṣe kí àwọn atọ́kùn bèèrè àwọn ìbéèrè tó níṣe pẹ̀lú ètò tí Harris ní fún orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà tó bá di Ààrẹ. Àwọn ìbéèrè yìí ni kò ṣe dada tó nígbà tó ń dáhùn wọn tó fi pàdánù tíkẹ́ẹ̀tì ẹgbẹ́ sọ́wọ́ Biden lọ́dún 2020.

Àwọn àmúyẹ wo ni Donald Trump ní gẹ́gẹ́ bí olùkópa níbi ìjíròrò náà?

Donald Trump duro seyin Hillary Clinton

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kí kojú Donald Trump níbi ìjíròrò ni ìpèníjà ńlá tí Harris máa ní nínú ìrìnàjò rẹ̀ láti di Ààrẹ Amẹ́ríkà.

Trump tí kópa nínú ìjíròrò nígbà tó ń díje sípò Ààrẹ lọ́dún 2016 àti 2020, tó sì ti ṣàfihàn pé òun tó gbangba sùn lọ́yẹ́.

Níbi ìjíròrò ọdún 2016, níṣe ló ń lọ, tó ń bọ̀, tí kò sì dúró sí ojú kan. Ó dúró sẹ́yìn Hilary lásìkò tí Hilary ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, tó sì ní bó ṣe dúró sí òun lẹ́yìn náà kò tẹ́ òun lọ́rùn.

Níbi ìjíròrò àkọ́kọ́ tí òun àti Joe Biden kọ́kọ́ ṣe lọ́dún 2020, níṣe ló ń gba ọ̀rọ̀ mọ́ Biden lẹ́nu lásìkò tí Biden bá ń sọ̀rọ̀ títí tí Biden fi bínú to sì jágbe mọ Trump pé kó gbẹ́nu dákẹ́.

Gbogbo àwọn nǹkan yìí ni Trump máa ń ṣe láti fi darí àwọn ènìyàn sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.

Àmọ́, Trump máa ń yẹ̀bàá kúrò lórí ìbéèrè tí wọ́n bá bi í láti sọ àwọn nǹkan tí wọn kò bi í èyí tí ọ̀pọ̀ ti ṣàwárí pé irọ́ ló ń pa.

Ta ni ó ń lé iwájú nínú àwọn olùdíje?

Kó tó di wí pé Joe Biden juwọ́ sílẹ̀ láti má díje fún ipò Ààrẹ mọ́ nínú oṣù Keje, Joe Biden wà lẹ́yìn Donald Trump nínú àwọn ètò ìdìbò táwọn èèyàn ń ṣe lórí ayélujára.

RealClearPolitics, iléeṣẹ́ tó máa ń yànnàná ọ̀rọ̀ òṣèlú sọ pé àkójọpọ̀ tí àwọn ṣe ṣàfihàn pé Harris ti ń léwájú láti ìgbà tí wọ́n kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú Democrat. Wọ́n ní ó ń léwájú Trump pẹ̀lú pọ́ìntì 1.9 nígbà tó fi má di lọ́jọ́ Kẹta oṣù Kẹsàn-án.

Ẹ̀wẹ̀, Hilary Clinton fi pọ́ìntì márùn-ún léwájú Trump àmọ́ to pàdánù ètò ìdìbò gbogbogbo lọ́dún 2016.

Àwọn ètò ìdìbò ní àwọn ìpínlẹ̀ ni wọ́n rí gẹ́gẹ́ bí pàtàkì jù ti ìjọba àpapọ̀ lọ. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí àkójọpọ̀ àwọn ìbò yẹn ló máa sọ ẹni tí yóò di Ààrẹ.

Àwọn Ìpínlẹ̀ bíi Arizona, Georgia, Michigan, North Carolina àti Pennsylvania ṣe pàtàkì fún olùdíje láti borí ìbò.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù Kẹsàn-án RealClearPolitics sọ pé Harris gbìyànjú láti léwájú Trump ní Michigan àti Georgia àmọ́ tí Trump léwájú ní Arizona àti North Carolina.

Olùdíje nílò àkójọpọ̀ ìbò 270 láti di Ààrẹ Amẹ́ríkà. Àkójọpọ̀ ìbò tó wà ṣàfihàn pé Democrat ní àpapọ̀ 226 báyìí, Republicans sì ní 219 tí 93 tó kù sì le lọ sí ibikíbi nínú àwọn méjèèjì.