Ìdí tí ara rẹ fi lè kọ kíndìnrín ti ẹlòmíràn bá fún ọ lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ

Aworan kindinrin

Oríṣun àwòrán, Getty images

Àkọlé àwòrán, Aworan kindinrin
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Ko si eyi to yẹ ko sẹ aisan ninu ẹya ara eeyan, nitori ọkọọkan wọn lo ni iṣẹ pataki ti wọn n ṣe.

Ọkan pataki ninu ẹya ara ẹda ni kindinrin jẹ, meji si ni ẹnikọọkan ni.

Iṣẹ kindinrin ni lati mu idọti kuro ninu ẹjẹ, ko si da ẹjẹ to mọ tonitoni pada sinu ara.

Iṣẹ rẹ tun ni lati ri si bi eeyan ṣe n tọ pẹlu.

Ida marun-un ẹjẹ ti ọkan n pin kaakiri ara lo n lọ sinu kindinrin, gẹgẹ bi iwadii awọn dokita ṣe fidi ẹ mulẹ.

Abawọn kan ko gbọdọ kan kindinrin, nitori yoo kan gbogbo ara bi wọn ṣe sọ.

Bi kindinrin ba daṣẹ silẹ fun awọn idi kan, awọn dokita ni ọna ti wọn maa n gba paarọ rẹ.

Ṣugbọn nigba mi-in, ara ẹni to nilo kindinrin yoo kọ eyi ti ẹlomiran fẹẹ fun un lati le wa laaye.

Àyọkà yii ṣalaye nipa bi wọn ṣe le paarọ kindinrin to bajẹ, ati ohun to le fa ki ara kọ eyi ti ẹnikan fi silẹ fun ẹni to ni aisan kindinrin.

Kí ni iṣẹ́-abẹ pípààrọ̀ kíndìnrín? (Kidney Transplant)

Aworan ọwọ ti wọn n fa ẹjẹ si lara

Oríṣun àwòrán, Getty image

Gẹgẹ bi ‘National Health Service’ (NHS), ajọ to n mojuto eto ilera ni United Kingdom ṣe ṣalaye, ọkan lara awọn iṣẹ-abẹ nla ni pipaarọ kindinrin, oun si ni ọna itọju fawọn eeyan ti wọn ti ni aisan kindinrin fun ọpọlọpọ ọdun.

Bi wọn ba n ṣe iṣẹ-abẹ pipaarọ kindinrin lọwọ, awọn dokita yoo yọ kindinrin ti wọn nilo lati ara ẹni to fẹẹ fi silẹ, wọn yoo fi si ara ẹni to nilo kindinrin naa lati maa lo o lọ.

Awọn eeyan to ṣi wa laaye le fi kindinrin wọn silẹ fun ẹni to nilo rẹ, wọn si tun maa n gba lati ara oku naa fun alaaye to nilo rẹ.

Bi wọn ba paarọ kindinrin ẹni ti tiẹ ti ni aisan, o ṣee ṣe kiru ẹni bẹẹ ṣi gbe ile aye fun igba pipẹ.

Ṣugbọn pipaarọ kindinrin le ma jẹ iwosan to pe, nitori bo ṣe wulo naa lo ṣe ni awọn ewu kan.

Ki wọn too ṣiṣẹ-abẹ kindinrin fun ẹni to nilo rẹ, awọn dokita yoo kọkọ ṣe ayẹwo boya ẹni to nilo kindinrin yii le ṣiṣẹ-abẹ ọhun rara, nitori ki i ṣe gbogbo eeyan ni iṣẹ-abẹ kindinrin wa fun.

Àwọn wo ni wọ́n lè pààrọ̀ kíndìnrín wọn?

*Ẹni to ti ni aisan kindinrin fun igba pipẹ.

*Ẹni ti ara rẹ le gbe iṣẹ abẹ nla bi eyi.

* Gbogbo òye gbọdọ foju han pe iṣẹ abẹ naa yoo yọri si rere ki wọn too ṣe e.

*Ẹni to fẹẹ ṣe iṣẹ-abẹ kindinrin gbọdọ le lo odiwọn awọn oogun to yẹ ko lo ti wọn ba paarọ kindinrin rẹ tan, titi kan oogun ti yoo maa gbogun ti awọn ohun ti ko ba fẹẹ ki ẹya ara tuntun naa ṣiṣẹ.

Kí ló ń fà á ti pípààrọ̀ kíndìnrìn fi lè má ṣiṣẹ́?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

National Kidney Foundation, ajọ kan to n ri si ilera kindinrin lorilẹede yii, ka awọn idi wọnyi gẹgẹ bii ohun to le fa a ti iṣẹ-abẹ kindinrin fi le ma ṣiṣẹ.

Kí ara kọ kíndìnrín tuntun náà:

Bi ara ẹni ti wọn paarọ kindinrin rẹ ba kọ eyi ti wọn ṣẹṣe fun un, o tumọ si pe awọn ṣọja ara alaisan naa ti bẹrẹ si i ba ẹya ara tuntun to wọle sibẹ ja niyẹn.

Eyi maa n ṣẹlẹ nigba ti ara alaisan naa ba ti mọ pe ajoji ni kindinrin to wọle yii, ti wọn si n ro o pe ko yẹ ko wa lara olootu awọn.

Ki ara kọ kindinrin tuntun tun le ṣẹlẹ, koda bi alaisan naa ba n lo awọn oogun rẹ bo ṣe tọ.

Bi alaisan kindinrin ba tun wa kọ, ti ko lo oogun rẹ bi dokita ṣe ni ko maa lo o, ewu to pọ lo n bẹ fun un nipa bi ara rẹ yoo ṣe maa ba ẹya ara ajeji to wọ ara rẹ ja.

O ṣe pataki fun alaisan kindinrin lati lo oogun rẹ gẹlẹ bi wọn ṣe kọ wọn fun un.

Ninu ọgọrun-un eeyan to ba ṣe iṣe-abẹ kindinrin, mẹwaa si mẹẹẹdogun ni ara wọn maa n kọ kindirin tuntun ti wọn ba gba.

Eyi si maa n waye laaarin ọdun kan ti wọn paarọ kindin atijọ si tuntun.

Bi ara ṣe n kọ kindinrin tun yatọ lati ara ẹnikan si ikeji, awọn kan wa ti ara wọn ko fẹ rara, nigba ti awọn mi-in ṣi maa n jagun ikọsilẹ kindinrin naa lọwọ ẹrọ.

2)Ẹjẹ̀ dídì:

Eyi maa n ṣẹlẹ nigba ti ẹjẹ to yẹ ko lọ si ara kindinrin tuntun naa ba dipọ, ti ko kọja sibi to yẹ. Eyi maa n sabaa ṣẹlẹ lẹyin iṣẹ-abẹ kindirin naa.

3)Kí omi dárogún sí àyíká ibi tí kíndìnrín wà:

Bi omi tabi ohunkohun ba darogun si ayika kindinrin, agbara omi naa le ba kindinrin jẹ bi wọn ko ba tọju rẹ.

4)Kòkòrò àìfojúrí (Infection):

Bi awọn kokoro aifojuri ba wa ninu kindinrin, o le fa iṣoro ti ko ni i kuro nibẹ mọ laye fun kindinrin.

Paapaa julọ bi wọn ko ba tete ri i ki wọn si tọju rẹ kia.

5)Àtubọtán àwọn òògùn tí ẹni tó ṣiṣẹ́-abẹ náà ń lò:

Awọn oogun kan ni atubọtan buruku lara, eyi ti oloyinbo n pe ni ‘side effects.’

Wọn yoo maa ṣakoba fun kindinrin tuntun. Bẹẹ ni awọn oogun kan wa ti wọn lewu fun kindinrin.

6) Ìṣòro láti ọ̀dọ̀ ẹni tó fi kíndìnrín sílẹ̀:

Gẹgẹ bo ṣe jẹ pe Oluwa nikan lo pe, awọn dokita to fẹẹ ṣiṣẹ-abẹ le gbagbọ pe kindinrin ẹnikan yoo ṣiṣẹ to peye, bi wọn ba lo o tan fun ẹni to nilo rẹ, o ṣee ṣe ko ma daa, ko si maa fa iṣoro fun ẹni to gba a.

Bi eyi ba ṣẹlẹ, o ṣee ṣe ki kindinrin naa ma ṣiṣe pẹ.

Kí ló ń fa àìsàn kíndìnrín?

1)Ẹjẹ riru

Imọ ijinlẹ fidi ẹ mulẹ, pe ẹjẹ riru jẹ ọna kan ti awọn eeyan maa n gba ni aisan kindinrin. Koda, koko kan gboogi ni wọn pe e pẹlu.

Till di oni yii, ko ti i si ẹnikan to le sọ koko ohun to n fa ẹjẹ riru funra rẹ.

Ṣugbọn awọn ohun ti wọn sọ pe o le fa a ni wahala aṣeju, ara asanju, jijẹ iyọ ju, amuju ọti ati siga mimu.

2)Aisan kindinrin ti wọn ko tọju

Bi awọn kokoro aifojuri ba wa ninu kindinrin eeyan, ti ẹni naa ko si tọju rẹ, wọn le pada di aisan kindinrin lọjọ iwaju.

Nigba mi-in, awọn kokoro aifojuri to ni i ṣe pẹlu bi a ṣe n tọ̀ maa n wa lara ohun ti yoo pada di aisan kindinrin.

Eyi wọpọ laaarin awọn obinrin.

3)Àlòjù òògùn

Apọju gbogbo nnkan ko daa.

Bi eeyan ba n lo oogun ju, paapaa oogun ara riro ati awọn oogun apakokoro ti a mọ si antibiotics, o le fa ki eeyan ni aisan kindinrin.

Bakan naa lo ri fun awọn egbogi oloro bii heroin ati cocaine, pẹlu awọn a-mu-ara-gba-yagiyagi, wọn maa n fa aisan kindinrin.

4) Ìtọ̀ Ṣuga

O ṣee ṣe ki awọn eeyan to ni aisan itọ ṣuga ni aisan kindinrin pẹlu.

Eyi ri bẹẹ nitori ara wọn ko le ṣe amojuto odiwọn ṣuga to yẹ ko wa ninu ẹjẹ mọ.

Eleyii le ba kindinrin jẹ, o le fa ki eeyan maa lo oogun ti yoo bori iṣoro naa ju, o si le pada di ohun ti eeyan yoo nilo kindinrin tuntun.

5) Ọti ati ẹlẹridodo mimu

Amuju ọti ko daa fun kindinrin rẹ, nitori yoo maa fun kindinrin ni iṣẹ to pọ ṣe.

Nigba mi-in paapaa, o le kan ẹdọ, ti yoo jẹ ki kindinrin maa ṣiṣẹ ẹdọ, ti yoo si maa gbe iṣẹ to le ju kindinrin lọ fun un lati ṣe.

Ni ti ẹlẹridodo, oun naa maa n ṣe akoba fun kindinrin, nitori eroja ‘phosphoric acid’ to wa ninu rẹ.

Awọn dokita ṣalaye pe ọti ẹlẹridodo naa ni ipa buruku to n ko lorii kindinrin eeyan.

Dokita Chuma Thomp, ṣalaye fun BBC pe omi lo daa keeyan maa mu lati din aisan kindinrin ku.

O ni omi lita mẹta lojumọ lo daa ki eeyan maa mu.

Dokita Chuma waa fi kun un ṣaa, pe ni ti Naijiria yii, oun gbagbọ pe omi lita mẹrin si marun-un lo yẹ ki eeyan maa mu lojumọ kan.

Ta a ni TG Omori, Ayàwòrán tí iṣẹ́-abẹ kíndìnrín kò ṣiṣẹ́ fún?

Aworan T.G Omori

Oríṣun àwòrán, T.G Omori/X

Àkọlé àwòrán, Aworan T.G Omori
T.G Omori nileewosan

Oríṣun àwòrán, T.G Omori/ X

Àkọlé àwòrán, T.G Omori nileewosan

Lati bii ọjọ meloo kan ni ọmọkunrin kan, TG Omori, to jẹ ayaworan, adari fidio ati orin ti gba ori ayelujara kan.

Ọmọkunrin naa lo gbe e si oju opo X rẹ pe lẹyin ọdun kan ti aburo oun yọnda kindinnrin foun lati maa lo, kindinrin naa ko ṣiṣẹ bo ṣe yẹ foun mọ.

TG Omori ti awọn eeyan tun mọ si Boy Director, ti ni aisan kindinrin tẹlẹ, o si ti ṣiṣẹ abẹ to yẹ, ṣugbọn kinni ọhun ko ṣiṣẹ.

Loju opo ayelujara rẹ to fi fọto ibi to ti n gba itọju si lo ti sọ pe oun o fẹẹ ku.

TG Omori rọ awọn eeyan lati ma ṣe gbagbe oun.

Diẹ ninu awọn gbajumọ olorin taka-sufee ti TG Omori ti ba dari orin ri ni: Olamide Badoo, Wizkid, Burna Boy, Tekno, Kiss Daniel, Fireboy DML, Falz, Timaya, Naira Marley ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ninu ọrọ kan to fi sita loju opo X rẹ ni 2022, TG Omori sọ pe oun ti gbe irinwo-le-marun-un (405) awo orin jade, iyẹn laarin ọdun 2018 si oṣu kẹfa ọdun 2022.

Ṣaa, ninu ọrọ rẹ lori ibusun ọsibitu to wa, TG Omori fi awọn ololufẹ rẹ lọkan balẹ, o ni, "Mo maa too dide pada, mo ṣeleri".