‘’Ọjọ́ tí á bá fi àwọn ìbejì wa tọrọ báárà làwọn ọmọ náà yóò kú’’

Àkọlé fídíò,
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ni agboole Agbebejigoriẹṣin, eyi to wa ni ilu Abeokuta, ko si ẹnikan ninu ile naa ti ko bi ibeji, eyi to tumọ si pe ibeji ni wọn ṣaba n bi julọ.

Abẹwo BBC Yoruba si agboole ọhun fi han pe lati ori awọn baba ati iya nla wọn, ni ọrọ ti ri bẹẹ, debii pe ẹlomii bi ibeji ju igba kan ṣoṣo lọ.

Ẹnikan lara awọn to jẹ agbalagba ninu agboole naa, Arabinrin Bushirat Idowu, sọ pe itan ti awọn iya agba wọn sọ ni pe kii ṣe pe wọn ṣe nnkankan lati maa bi ibeji bẹẹ, 'o kan fun Ọlọrun ko maa fun wa ni."

Arabinrin Idowu ṣalaye pe ori ọmọ kẹrin ni oun paapaa bi ibeji, ati pe gbogbo ọmọ agboole Agbebejikoriẹṣin nile ati nilẹ okeere lo ma n bi wọn.

Awọn ibeji to n ṣere

Agba ile miran, Ọgbẹni Akeem Idowu, sọ pe igba meji ni oun bi ibeji - ọkunrin kan ati obinrin nigba akọkọ, to si tun bi ọkunrin meji lẹẹkan si.

Ọgbẹni Idowu sọ pe ni ilẹ isinku agboole naa, "ibeji lo pọ ju ninu awọn saare to wa nibẹ".

Ṣugbọn ṣa o, ara ọtọ ni awọn eniyan agboole Agbebejigoriẹṣin fi ma n ki awọn ibeji wọn kaabọ.

Arabinrin Idowu ṣalaye pe ti isọmọlorukọ ba ku ọla, ni wọn o ko oriṣiriṣi nnkan ti ẹnu n jẹ jọ, lati fi bọ awọn ibeji naa.

Arakunrin Idowu sọ pe dandan ni ṣiṣe saara ibeji naa.

"Nnkan ti awa ba ree, ti a si mu ni ọkunkundun pe, a gbọdọ maa ṣe e bi awọn baba nla wa ṣe n ṣe."

Eyi si lo ni o jẹ aṣiri bi wọn ṣe n bi awọn ọmọ naa titi di oni.

Bibi ibeji ninu ile naa ti pẹ ninu itan wọn debi i pe, wọn fi sọ orukọ agboole wọn.

Ki lo bi orukọ Agbebejigoriẹṣin?

Agboole Agbebejigoriẹṣin

Ni igba iwasẹ, awọn baba nla wọn n sin ọpọlọpọ ẹṣin, ti wọn ba si ti bi ibeji, ti awọn ibeji naa dagba, ori ẹṣin ni wọn ma n gbe wọn si lasiko ọdun ati saara ibeji wọn.

Eyi ni orukọ Agbebejigoriẹṣin fi lẹ mọ wọn lara titi di oni.

Eewọ wa fun agboole Agbebejigoriẹṣin

Arabinrin Bushirat Idowu sọ fun BBC pe eewọ ni fun ọmọ agboole naa lati jẹ ejo.

Bakan naa ni ẹni to ba ti bi ibeji ko gbọdọ jẹ fi ọbọ ṣere tabi fi awọn ibeji naa tọrọ bara gẹgẹ bi awọn kan ṣe ma n ṣe, gẹgẹ bi Ọgbẹni Akeem Idowu ṣe sọ.

"Ọjọ ti o ba gbe wọn lọ ọ tọrọ bara, ni ẹni naa yoo padanu awọn ibeji rẹ."

Ilu Igboora nipinlẹ Oyo lo tun gbajumọ fun ibeji bẹẹ.

Ni ilu naa, ko si idile ti ko ni o kere tan, ibeji kan.

Ọdọọdun si ni wọn ma n ṣe ajọdun fun gbogbo awọn ibeji ilu naa.

Koda, lati Naijiria ati oke okun ni awọn eniyan ti ma n wa woran awọn ibeji ni Igboora.

Ajọ UNESCO paapaa da ilu naa mọ gẹgẹ bi ibudo aṣa nnkan abalaye.