'Ojú oníke ni mo fi ń ríran lẹ́yìn tí àwọn adigunjalè fọ́ mi lójú'

“Lẹyin ti mo ri pe mo ti padanu oju mi kan, o bẹrẹ si ni ma dun mi nitori nko ri bi ti tẹlẹ mọ.”
Eyi ni ọrọ Idris Badamasi nigba to sọ nipa bi o ṣe padanu oju rẹ, to si n lo oju onike.
Idris wọ iya ija pẹlu awọn adigunjale ni ọjọ kẹta, oṣu Kẹta, ọdun 2022.
O n gbinyanju lati daabo bo mọlẹbi rẹ lasiko ti iṣẹlẹ naa waye, to si padanu oju rẹ.
Bawo ni Idris se padanu oju rẹ?
“Mo n sun lọwọ ni mo gbọ ariwo, ẹ gba wa ni agbaala baba mi,”
Ni bi to ti n gbiyanju lati mọ nipa nnkan to n sẹlẹ ni o ṣalabapade awọn adigunjale.
“Bi mo se si ilẹkun, mo wa ri pe awọn adigunjale n gbiyanju lati fipa ba ọdọmọbinrin to n gbe pẹlu wa lasiko naa lopọ.”
O ni awọn adigunjale naa rapala wọ ile wọn, ti wọn si fi oju koju, to si bẹrẹ si ma fi ada lu.
“Mo pinnu lati ja pada nigba ti mo ti mọ pe mo setan lati ku ni alẹ ọjọ naa.
“Mo le wọn kuro ni inu ile sita, ibẹ ni mo ti ri pe awọn mii si wa ni ita .
“Bi wọn se bẹrẹ si ni ma lumi lati ori de ẹsẹ niyẹn.
"Ọkan lara wọn lo fi nnkan gba mi lpju, mo si ṣubu lulẹ. Ibẹ ni mo ti padanu oju mi."
Irinajo si lilo oju onike

Lọwọ yii, Idris n lo oju onike.
O ni oun ni ireti pe awọn dokita yoo wa atunṣe si oju oun sugbọn lẹyin to lọ si ile iwosan mẹfa niluu Abuja, wọn sọ fun pe oju naa ti lọ, ko si ma lo oju onike.
“Mo pade dokita naa, o sọ fun mi nipa oju prosthetic, pe ki wa nnkan lati ma lo.
“Oju naa ree lẹyin ti mo fọ tan, mo ma n lo jigi si to mo ba i wọ tan.
“Mo le wọ lọ si ibi kibi, mo n sun, koda mo n sun pẹlu rẹ. Mo le se ọpọ nnkan pẹlu rẹ.
Sugbọn Idris ni awọn ipenija kan wa pẹlu oju onike naa.
“Ti n ko ba fọ oju yii, yoo ma yun mi loju.”
Idris ni irinajo oun si tẹsiwaju nitori ara oun ko ti i ya tan.
“Irinajo si alaafia gun, to si le. Mo n tẹsiwaju."















