Èèyàn méjì ti lùgbàdì àrùn Mpox l'Osun, ìjọba ní kí aráàlú fọkàn balẹ̀

Aworan ẹni ti Mpox mu.

Oríṣun àwòrán, REUTERS

Àkọlé àwòrán, Aworan ẹni ti Mpox mu.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba ipinlẹ Osun ti fidi rẹ mulẹ pe arun Mpox to n ja kaakiri ilẹ Afirika ti wọ nipinlẹ naa, koda eeyan meji lo ti lugbadi rẹ.

Ọjọ Aje, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹjọ yii ni iroyin naa jade ninu atẹjade kan ti ọfiisi kọmiṣọna eto ilera ipinlẹ Osun, Jola Akintola, fi sita.

Ninu atẹjade naa ni ijọba ti ṣalaye pe ọkunrin ni awọn eeyan meji ti Mpox mu naa, ati pe ọmọ ọdun marun-un kan ati agbalagba ọkunrin ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, ni wọn.

Bakan naa, onimọ nipa awọ ara nipinlẹ Osun, Dokita Omolola Adeagbo, ṣalaye pe eeyan mẹtadinlaaadọta ni o ṣee ṣe ki Mpox ti mu, eyi ti ayẹwo si ti waye lori gbogbo wọn.

Dokita Adeagbo sọ pe abajade ayẹwo naa lo fidi rẹ mulẹ pe eeyan meji pere ni aisan naa ti fi ọwọ ba ninu wọn.

Gẹgẹ bi o ṣe ṣalaye, agbegbe Iwọ-Oorun ilu Ileṣa ni arun naa ti kọlu eeyan meji ọhun, wọn si ti bẹrẹ si ni gba itọju ni ile iwosan ijọba to wa nibẹ.

‘’Ẹ fi ọkàn balẹ̀, kò sí ìdí kan láti bẹ̀rù rárá’’

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹjọ ọdun 2024 yii, Kọmiṣọna eto Ilera ipinlẹ Osun, amofin Akintola, sọ pe ki awọn eeyan ipinlẹ naa fi ọkan balẹ.

O ni ko si idi kankan fun wọn lati bẹru rara.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

''Ootọ ni pe Mpox wa nipinlẹ Osun, ni ọsẹ mẹrinlelọgbọn ti a lo kọja, a ri eeyan meji ti arun Mpox mu nipinlẹ Osun.

A ri ẹyọ kan loṣu kẹta, ikeji si ṣẹṣẹ waye lọjọ Ẹti to kọja ni, awọn mejeeji waye nijọba ibilẹ kan naa, iyẹn Iwọ-Oorun Ilesa,'' Ọgbẹni Akintola ṣalaye.

Amọ, kọmiṣọna ni ko si idi kankan lati bẹru tori awọn mejeeji n ṣe daadaa nibi ti wọn wa.

Bakan naa ni Ọgbẹni Akintola sọ pe ijọba ti bẹrẹ si ni gbe gbogbo igbesẹ to yẹ lati dẹkun itankalẹ arun naa.

''A ti ba awọn araalu naa sọrọ pe ki wọn fi ọkan balẹ, ko si wahala.

Gbogbo igbesẹ to yẹ ki a gbe ni a ti gbe lati ri i pe arun naa ko tan kalẹ kọja awọn meji to ti mu yii lọ.''

‘’A ṣẹgun covid-19, a si dena itankalẹ Kọlẹra, a si tun ti bẹrẹ igbesẹ lori mpox to ti mu eeyan meji yii naa.

Gbogbo ọjọ Mọnde ni awọn alẹnulọrọ yoo maa jiroro lori ẹ lati mọ ọna ti ko fi ni i tan kalẹ.

Awọn oṣiṣẹ wa ti gbaradi, bi a ṣe dena Kọlẹra naa la maa dena itankalẹ mpox,'' Kọmiṣọna eto ilera ipinlẹ Osun lo sọ bẹẹ.

Ọna tí wọn yóò fi kápá Mpox l’Osun

Gẹgẹ bi atẹjade lati ọfiisi Kọmiṣọna eto Ilera ipinlẹ Osun ṣe sọ, awọn ọna wọnyi ni ijọba yoo fi kapa arun Mpox ko ma ba tan kalẹ:

*Riran awọn oṣiṣẹ eleto aabo pajawiri jade.

*Ilanilọye, ipolongo pẹlu itaniji fun awọn eeyan nipa arun naa, paapaa julọ lagbegbe Ogbon Alaafia, ati ibugbe ti arun naa ti ṣẹyọ.

*Ati nipa yiyẹ awọn agbegbe wo lati mọ bo ba ṣe n lọ si nibi kọọkan.