Awọn ọ̀dọ́ ìlú Ipokia fún iléèṣẹ́ aṣọ́bodè ní gbèdèke ọjọ́ mẹ́rìnlá lórí ọ̀rọ̀ ọ̀wọ́n epo

Awọn oṣiṣẹ aṣọbode

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ẹgbẹ kan, Ipokia Local Government Youth Forum (IPYF), ti fi ẹsun kan ileeṣẹ aṣọbode ilẹ Naijiria, Nigeria Customs Service (NSC), pe wọn n gbe epo to yẹ fun awọn eeyan Ipokia lọọ ta ni orilẹ-ede Benin.

Ẹgbẹ IPYF ṣọ pe eyi ko jẹ ki awọn eeyan ri epo ra ni awọn ile epo ni gbogbo ijọba ibilẹ Ipokia.

Wọn ni idaamu gidi ati owo gọbọi ni wọn fi n ra epo bẹntiroolu lọwọ awọn to n ta a lọja okunkun (Black market).

Koda, gbedeke ọsẹ meji pere ni ẹgbẹ naa sọ pe awọn fun ileeṣẹ aṣọbode Naijiria lati dẹkun bi wọn ṣe ni wọn n gbe epo to yẹ fun Ipokia lọọ ta ni ibomiran.

Wọn ni bi inira airi epo ra ti awọn n koju ba fi tẹsiwaju lẹyin ọsẹ meji, nitori bi awọn oṣiṣẹ aṣọbode ṣe n gbabọde, awọn yoo ti gbogbo ilu pa ni.

Ṣaaju ni ẹgbẹ yii ti kọkọ fi lẹta kan ṣọwọ si ọga agba ileeṣẹ aṣọbọde Naijiria, Bashir Adewale, eyi ti Alaga wọn, Imoleayo Mawutin Deji, buwọlu lorukọ ẹgbẹ.

Ninu lẹta naa ni wọn ti ṣalaye pe ọdun 2019 ni ijọba ti ṣofin awọn oniṣowo epo ko gbọdọ ta epo ni ijọba ibilẹ Ipokia.

Eyi mu ki awọn araalu o maa rin irin ogun kilomita si ilu naa, ki wọn to o ri epo ra.

Ija ti araalu ja lo mu ki ijọba pada fi aaye gba ileepo mẹrin lati maa ta epo fun wọn laarin ilu.

Ṣugbọn wọn ko ta a fun araalu, afi fun awọn ti wọn n ta a si Benin.

#1,500 sí 2,000 ni a n ra lita epo kan n’Ipokia

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ ni aarọ ọjọ Aje, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, 2024, Alaga IPYF, Imoleayo Mawutin Deji, ṣalaye pe,

O ni awọn aṣọbode ta a mọ si Custom, ẹka Ogun 1 pẹlu awọn alafọwọsowọpọ wọn to jẹ awọn eeyan ti wọn n ta epo bẹntiroolu, n fi iya jẹ awọn eeyan wa gan-an gidi.

"O dabii pe wọn fẹẹ maa da awọn diẹ kan si, ki owo maa kun apo wọn, wọn wa n fiya jẹ ọpọlọpọ eeyan.

‘’Gbedeke 20km ni wọn fun wa pe ki epo ma wọ agbegbe wa, nitori wọn n gbe epo to n wọ ọdọ wa lọ si ilẹ Olominira Benin, a si gba pe loootọ ni.

‘’Nitori ọpọlọpọ awọn eeyan wa ni wọn n ra epo ni Naijiria nibi, ti wọn n lọọ ta a si Benin, nigba ti wọn o tiẹ ti i yọ owo iranwọ ori epo (subsidy).

‘’Nisinyi, wọn ti yọ subsidy, epo ti wọn, sibẹ, wọn o yi ofin yẹn pada.

Ki wọn ma baa maa ta epo wa si Benin ni wọn ṣe fun wa ni gbedeke 20km, ṣugbọn ohun to n ṣẹlẹ naa niyẹn, awa ni iya ẹ n jẹ."

Ọgbẹni Deji sọ pe nnkan to wa le ju ni pe awọn ile epo diẹ ti wọn n ṣi, ti wọn ni ki wọn maa ta epo fawọn eeyan ki inira wọn ma baa pọju, awọn ọrẹ wọn ni wọn ta a fun, ti wọn n gbe e lọ si Benin Republic, loju awọn oṣiṣẹ aṣọbode.

‘’Igba ti wọn ṣe ipade akọkọ lati ṣi ile epo, ẹgbẹ ọdọ wa nibẹ. Ohun ti a fẹnuko le lori ni pe won a maa ta epo fun araalu, ṣugbọn wọn o ta a.

"1,500 si 2,000 ni lita epo kan ni ọja okunkun, awọn eeyan o ri epo ra nile epo."

‘’Awon to n ta a n sọ fun wa pe Owode lawon ti n lọọ ra epo wa, ijọba ibilẹ mi-in dẹ niyẹn.

A ti gbé ìgbésẹ̀ ṣíwájú gbèdéke ọ̀sẹ̀ méjì tí a fún àwọn Aṣọ́bọdè yìí

Ọga agba ajọ Aṣọbode ilẹ Naijiria, B.A Adeniyi

Oríṣun àwòrán, NCS

Mawutin ṣalaye pe oun ati awọn ọmọ ẹgbẹ IPYF ti gbe awọn igbesẹ kan ṣiwaju asiko yii, ko too di ti onigbedeke ọsẹ meji.

O ni oun ti mu ẹjọ awọn aṣọbode lọ si ileeṣẹ redio ri, to di wahala.

Alaga IPYF naa sọ pe awọn kan wa ti wọn jẹ oludena, ti wọn jẹ alagbara ninu ijọba ibilẹ Ipokia.

O ni awọn ni ki i jẹ kawọn ri ọrọ naa sọ.

''Bí wọn kò bá dá wa lóhùn láàárín ọ̀sẹ̀ méjì''

Gẹgẹ bi Alaga ẹgbẹ ọdọ ijọba ibilẹ Ipokia ṣe wi, o ni laarin ọsẹ meji yii, kawọn Aṣọbode ṣe atunyẹwo epo 20km ti wọn n ṣe fun Ipokia.

Ki wọn mojuto awọn ileepo, lati ri i pe wọn n ta a fawọn eeyan.

O ni bi wọn ko ba le ṣe eyi, ki wọn kuku ti gbogbo ile epo to wa nijọba ibilẹ Ipokia pa.

‘’Ooṣa bo o ba le gbe mi, ṣe mi bi o ṣe ba mi.

‘’Lẹyin ọsẹ meji ti a fun wọn yii, bi wọn ko ba ti da wa lohun, gbogbo ijọba ibilẹ Ipokia ati Ogun West ni awa ọdọ maa tipa.

‘’Ati oṣiṣẹ aṣọbode o, ati ọlọpaa o, a o ni i jẹ ki ohunkohun ṣiṣẹ, a maa ti i pa a ni, afi ti wọn ba da awọn eeyan wa lohun. Ao si ni i yi ipinnu wa yii pada o, iya yii ti pọju.’’

Igbiyanju wa lati ba ajọ Aṣọbode ilẹ wa sọrọ ko so eso rere.