Àwọn onímọ̀ tọ̀ka àwọn ìpèníjà tó wà lọ́nà fún Kekere-Ekun, adájọ́ àgbà tuntun ní Naijiria

Kekere-Ekun

Oríṣun àwòrán, Supreme Court of Nigeria

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Aarẹ Bola Tinubu ti burawọle fun Kudirat Kekere-Ekun, gẹgẹ bii dele adajọ agba Naijiria.

Iburawọle yii lo n waye lẹyin ti ile igbimọ aṣofin agba Naijiria fontẹ lu iyansipo rẹ.

Kudirat Kekere-Ekun bọ sipo adajọ agba Naijiria lẹyin ti aṣaaju rẹ, Olukayode Ariwoola fẹyinti lẹnu iṣẹ.

Pẹlu iyansipo rẹ yii, Kekere-Ekun ni yoo jẹ obinrin keji ti yoo di ipo naa mu ninu itan Naijiria.

Wayi o, awọn onimọ nipa ofin ati eto idajọ ti sọrọ lori awọn ohun ti Kekere-Ekun gbọdọ gbajumọ lasiko rẹ gẹgẹ bii adele adajọ agba Naijiiria.

Awọn atunṣe ti Kudirat Kekere-Ekun gbọdọ gbajumọ ree

Eto idajọ to ya kankan

Ohun kan gboogi ti awọn araalu atawọn agbẹjọro n reti lati ọdọ adajọ agba yii ni eto idajọ to ya kankan.

Agbẹjọro kan, Kayode Oluwafemi sọ fun BBC pe Kekere-EKun gbọdọ ṣe awọn ohun ti yoo mu ki araalu ni igbagbọ ninu eto idajọ Naijiria.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Kayode sọ pe eto idajọ ti maa n pẹ ju ni Naijiria, awọn kan kii si n ri idajọ gba lasiko to yẹ, eyii to mu ki ọpọ araalu sọ ireti nu ninu ẹka eto idajọ Naijiria.

O ni o yẹ ki idajọ maa waye ni kankan ni Naijiria ki araalu le fi igbagbọ wọn sinu ile ẹjọ.

O pari ọrọ rẹ pe “a nilo ki idajọ maa waye ni kia kia, ki idajọ naa si waye lasiko to yẹ, eyii yoo mu ki araalu gbagbọ ninu ẹka eto idajọ.”

Owo oṣu to tọ fun awọn adajọ

Ojun miran to n kan awọn agbẹjọro lominu ni owo ti awọn adajọ n gba.

Wọn ni ti adajọ ba n gba owo oṣu to tọ, yoo ṣoro lati fun irufẹ adajọ bẹẹ lowo ẹyin lọna ati yi idajo po.

Kayode sọ pe ti adajọ agba tuntun ba n fẹ ki awọn eeyan ni ireti ninu ẹka eto idajọ, o ni lati ṣe afikun owo awọn adajọ ki wọn le kọ ẹyin si riba gbigba, eyii to lati lati yi idajọ po.

O ni “o ni lati mu awọn aba tuntun wa si ẹka eto idajọ ti yoo mu ki araalu ni igbagbọ ninu rẹ.

“Ti ẹ ba wo eto idibo to kọja yii, ẹ o ri pe ọpọ ni ko ni igbagbọ ninu ẹka eto idajọ mọ.”

Ààrẹ Tinubu búra fún Adájọ́ Kekere-Ekun gẹ́gẹ́ bí Adájọ́ àgbà ní Naijiria, àwọn ohun tó yẹ kí o mọ́ nípa rẹ̀ nìyí

Aworan Adajọ agba Kudirat Kekere-Ekun.

Oríṣun àwòrán, Supreme Court of Nigeria.

Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti bura fun Onidajọ Kudirat Kekere-Ẹkun gẹgẹ bii adajọ agba kẹtalelogun ti yoo jẹ lorilẹede Naijiria.

Onidajọ Kekere-Ẹkun yoo wa nipo, ṣaaju asiko ti awọn aṣofin agba Naijiria yoo fi fọwọ si iyansipo rẹ.

Kakere Ekun jẹjẹ ipo rẹ tuntun, o si buwọlu iwe iforukọsilẹ ẹjẹ ni nnkan bii agogo mejila ku ogun iṣẹju ni gbọngan ijoko ṣe’pade ni ile aarẹ nilu Abuja lọjọ Ẹti.

Onidajọ Kekere-Ẹkun ni yoo gba iṣẹ akoso ẹka iṣedajọ Naijiria lọwọ Ariwoọla to fi iṣẹ silẹ lọjọbọ, ọjọ kejilelogun osu kẹjọ lẹyin to pe aadọrin ọdun.

Kekere-Ẹkun lo n rọpo Onidajọ Ariwoọla gẹgẹbi adajọ agba tuntun Naijiria

Ajọ apapọ awọn adajọ ni Naijiria, National Judicial Council (NJC),ti fa Adajọ Kudirat Motonmori Kekere-Ekun,kalẹ fun Aarẹ Bọla Tinubu, lati yan an si ipo Adajọ agba orilẹede yii.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ NJC, Soji Oye, fi sita lo ti ṣalaye pe awọn fi ẹnu ko lati fa Adajọ Kekere-Ekun kalẹ nibi ipade awọn, eyi ti Adajọ agba, Olukayode Ariwoola dari.

Atẹjade naa ṣalaye pe Adajọ Ariwoola yoo kuro nipo naa ni ọjọ kejilelogun, oṣu kẹjọ 2024 yii, o si ṣe pataki lati gbe igbesẹ yiyan Adajọ agba tuntun.

Tẹ o ba gbagbe, Adajọ Olukayode Ariwoola lo ti wa ni ipo adajọ agba lorilẹede yii lati igba ti aarẹ ana, Muhammadu Buhari ti yan an lọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹsan-an ọdun 2022.

Gẹgẹ bi ofin, Adajọ Ariwoola yoo fi ipo naa silẹ lọjọ kejilelogun, oṣu kẹjọ ọdun 2024 yii, nigba ti baba naa yoo ti pe aadọrin ọdun (70).

Bakan naa, ofin ile ẹjọ to ga julọ ni pe adajọ to ba pawọle adajọ agb,lo ṣee ṣe ko bọ si ipo naa, lẹyin ti eyi to fipo silẹ ba pari saa rẹ.

Ni bayii, adajọ mọkanlelogun lo wa ni ileẹjọ to ga julọ.

Bi wọn ba yan Kekere-Ekun sipo naa, oun ni yoo jẹ adajọ obinrin keji to di ipo naa mu ni Naijiria.

Adajọbinrin Aloma Mukhtar ni obinrin akọkọ to di ipo yii mu, laarin oṣu kejila ọdun 2012 si oṣu kọkanla ọdun 2014.

Yatọ si ti Adajọ Kekere Ekun, ajọ awọn Adajọ tun fi orukọ adajọ mẹtadinlọgbọn mi-in ranṣẹ si awọn gomina ipinlẹ, ki wọn le bọ si ipo adajọ agba ni ipinlẹ wọn.

Bakan naa ni wọn fi orukọ ranṣẹ fun ipo Kadi, fun ile-ẹjọ Sharia to wa l’Abuja.

Ta a ni Adájọ̀ Kekere-Ekun?

Ọkan ninu awọn obinrin adajọ to wa nipo nla lorilẹede Naijiria ni Adajọ Kudirat Motonmori Olatokunbo Kekere-Ekun.

Ọjọ keje, oṣu karun-un, ọdun 1958 ni wọn bi i.

Ẹni ọdun mẹrindinlaadọrin (66) ni bayii.

Adajọ Kekere-Ekun kawe nipa imọ ofin ni Yunifasiti ipinlẹ Eko (UNILAG), o si di amofin ni 1981.

Fun abala ẹkọ ofin LL.M, ilu London ni Adajọ Kekere-Ekun ti gba a, ni ile-ekọ London School of Economic and Political Science, eyi si jẹ oṣu kọkanla ọdun 1983.

Adajọ Kekere-Ekun bẹrẹ iṣẹ amofin rẹ nipinlẹ Eko, lorilẹede Naijiria.

Ọdun 1989 lo gba iṣẹ gẹgẹ bii amofin onipele keji (Senior Magistrate Grade II) niluu Eko, loṣu kejila ọdun 1989.

Lẹyin eyi lo di Adajọ ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Eko, ninu oṣu keje ọdun 1996.

Adajọ Kudirat Kekere-Ekun ṣiṣẹ gẹgẹ bii Alaga igbimọ to n ri si idigunjale ati nnkan ija, iyẹn ni Zone 11, Ikẹja niluu Eko, laarin oṣu kọkanla ọdun 1996, si oṣu karun-un ọdun 1999.

Oṣu kẹsan-an ọdun 2004 ni Kekere-Ekun di adajọ ile-ẹjọ Ko-tẹ-mi-lọrun.

Lati ibẹ lo ti gba iyansipo lọ si ile-ẹjọ to ga julọ lọjọ kẹjọ, oṣu kẹfa ọdun 2013.

Yatọ si ọrọ ofin to jẹ Adajọ Kudirat logun, o fẹran ko maa kawe, ko maa kọrin.

Kekere-Ekun fẹran imọ ẹrọ igbalode ati igbani-nimọran.

Àwọn adájọ́ àgbà tó ti jẹ rí ní Naijiria

Adajọ Stafford Foster Sutton - 1955-1958

Adajọ Adetokunbo Ademola - 1958-1972

Adajọ Taslim Olawale Elias - 1972–1975

Adajọ Darnley Arthur Alexander- 1975–1979

Adajọ Atanda Fatai-Williams - 1979- 1983

Adajọ George Sodeinde Sowemimo - 1983–1985

Adajọ Ayo Gabriel lrikefe - 1985–1987

Adajọ Muhammed Bello - 1987–1995

Adajọ Muhammadu Lawal Uwais- 1995–2006

Adajọ Salisu Modibo Alfa Belgore - 2006–2007

Adajọ Idris Legbo Kutigi - 2007–2009

Adajọ Aloysius Iyorgyer Katsina-Alu - 2009–2011

Adajọ Dahiru Musdapher - 2011–2012

Adajọ Aloma Mariam Mukhtar - 2012–2014

Adajọ Mahmud Mohammed - 2014–2016

Adajọ W. S. Nkanu Onnoghen - 2016- 2019