Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Eyi ni akojọpọ awọn ohun to n ṣẹlẹ to tayọ kaakiri agbaye
Bi a ba n joyin, bi a ba n jadun, bi a ba n fi itan ewurẹ jẹka
Ka ma gbagbe pe atipo la jẹ laye
Gbajumọ akọrin ẹmi, Aduke Gold ti dagbere faye
Amọ ohun to sokunfa iku rẹ lo ma dẹru ba ni pupọ,
to si tun gba omije loju ẹni pẹlu.
Iru iku wo gan an lo pa Aduke Gold, igba wo si ni isinku rẹ?
Olori ẹbi ile Aduke ba BBC sọrọ
Kan si oju opo BBC.com/Yoruba lati mọ idi iku naa.
Njẹ o ti gbọ nipa Itankalẹ Aarun Monkey pox nilẹ Afrika?
Ewo tun niyẹn bayii?
Aarun kan to farapẹ igbona ni, to si ti n sọsẹ ni awọn ipa ibi kan.
Ọpọ ẹmi lo ti sofo, ti ọpọ eeyan si ti dero ile iwosan
Koda, ileeṣẹ to n sakoso Aarun ni ilẹ Afrika, CDC ti kede ilu o fararọ lori aarun naa
Bawo ni aarun naa se n tan kalẹ, bawo si ni a se le dena rẹ?
Kan si oju opo BBC.com/Yoruba.
