"Mò ń dojú kọ ohun tó burú jú tí abiyamọ le è rí, ọmọ mi méjì kúró ní Sudan tori ogun, gba àsálẹ̀ lọ Libya, n kò rí wọn mọ́, ogun sọ àlá wa di kòròfo"

Ahmed and Miriam

Oríṣun àwòrán, Michel Mvondo/BBC

    • Author, by Paul Njie & Michel Mvondo in Farchana
    • Role, BJ
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Mariam Hussein joko sori ẹni, o si n wo aworan akọbi ọmọ rẹ ọkunrin, Mohamed, ẹni ti ko tii gbọ nnkankan nipa rẹ lati ọdun meje sẹyin.

Pẹlu omije loju rẹ lo fi ṣalaye fun BBC pe, ọmọ oun naa tẹkọ leti lọ silẹ Europe lọna ati pa owo wale fun itọju oun ati mọlẹbi rẹ.

Ọdọkunrin naa kuro niluu Dafur, to jẹ olu ilu orilẹede Sudan, o si fi ẹsẹ rin gba aarin aṣalẹ Sahara.

Mariam sọ pe “nigba to de Libya, ẹẹmeji ọtọtọ ni wọn ji gbe.

“Nigba ti wọn kọkọ ji gbe, wọn beere owo itusilẹ, awa mọlẹbi atawọn ara adugbo lo da owo jọ lati gba itusilẹ rẹ.”

Igba to ba ọmọ rẹ naa sọrọ kẹyin ni ọdun 2017.

O ni “igba to gbiyanju lati kan si wa kẹyin, o ni ẹrọ ibanisọrọ ọrẹ oun kan loun n lo.”

Lẹyin ọpọlọpọ ọdun, Maria ko mọ boya ọmọ oun ti wọ ilẹ Europe, tabi o ti ku tabi o tilẹ ti sọnu.

Farchana Camp

Oríṣun àwòrán, Michel Mvondo/BBC

"Igbe aye inira tori Ogun Sudan lo mu ki Ahmed rin irufẹ irinajo ti ẹgbọn rẹ Mohamed rin, lati gba aṣalẹ kọja si Yuroopu"

Lọjọ kinni, oṣu Kẹrin, ọdun 2023, ogun bẹ silẹ laarin ẹgbẹ alatako ọmọ ogun Sudan, eyii to mu ki Mariam salọ si ila oorun orilẹede naa pẹlu ọmọ rẹ Ahmed.

Ni bayii, agọ Farchana ti awọn ogunlende n gbe ni wọn fi n ṣebugbe, nibi ti nnkan bii ẹgberun lọna mejilelogoji eeyan wa.

Bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan naa n ri ibi fi ori wọn pamọ si, igbe aye inira, bii airi ounjẹ jẹ, ni wọn n gbe nibẹ.

Igbe aye inira ọhun lo mu ki Ahmed pinnu lati rin irufẹ irinajo ti ẹgbọn rẹ Mohamed rin, lati gba aṣalẹ kọja.

O ti n mura lati fi Farchana silẹ, toun ti awọn ọrẹ rẹ kan lati fi ẹsẹ rin gba Libya ati Tunisia ki wọn le jade nilẹ Europe.

O ni “nigba ti a wa n ni Sudan, mo kawe ni fasiti nibi ti mo ti ni ala ọjọ iwaju rere fun ara mi, amọ nitori ogun to waye nibẹ, ala mi ti di korofo.”

Ohun to buru ju ti oju abiyamọ le ri nile aye ree

Ni bayii, Miriam ti n dojukọ ohun to buru ju ti oju abiyamọ le ri – pipadanu ọmọkunrin meji sinu aṣalẹ Sahara.

Iya naa ni “mo sọ fun ko ma lọ nitori ọmọ mi akọkọ ti sọnu loju ọna ọhun, nitori naa, ẹru n ba mi ki nnkan to ṣẹlẹ si ẹgbọn rẹ ma ṣẹlẹ si oun naa.

Ṣugbọn Ahmed ti kọti ikun si gbogbo ikilọ iya rẹ, gẹgẹ bo ṣe sọ, ko si ọjọ iwaju kankan fun oun ti oun ba duro si Chad.

O ni “ootọ ni mama mi ko gba ki n lọ, ṣugbọn mi o le duro si Chad, ko si eto ẹkọ tabi ohun idagbasoke kankan.

“Ogun naa ti ba gbogbo ala ọjọ ọla wa jẹ, gbogbo igba ti mo ba n ni itakurọsọ pẹlu awọn ọrẹ mi, a maa n dọwẹkẹ, amọ nigbakugba ti a ba wo ohun to jọ mọ eto ẹkọ lori Facebook inu wa maa n bajẹ.

“A maa n fi ara wa we awọn to lanfani si ẹkọ a si ri pe alafo to wa laarin wa ko kere… mi o le ma aba igbe aye mi lọ bayii.

Ahmed

Oríṣun àwòrán, Michel Mvondo/BBC

Igbiyanju to n ja kulẹ

Iṣoro ti Ahmed n doju kọ lọwọ yii farajọ ti Sidik, ti oun naa ti n gbe ni agọ awọn ogunlende Farchana fun ogun ọdun gbako.

Igba mẹta ọtọtọ lo ti gbiyanju lati rekọja silẹ Europe nipa gbigba oju ọna Libya ati Tunisia, amọ pabo ni gbogbo igbiyanju rẹ ja si.

Awọn onimọ sọ pe aṣalẹ Sahara ni oju ọna to buru julọ lagbaye ti awọn eeyan n gba rinrinajo.

Ajọ International Organisation for Migration (IOM) sọ pe eeyan 161 lo ku lasiko ti wọn n gba oju ̣ọna ọhun lọdun 2023 nikan ṣoṣo.

Laarin ọdun 2017 si 2019, ajọ IOM ti ko awọn aṣatipo lati Chad lọ si France fun igbe aye tuntun.

Bo tilẹ jẹ pe Ahmed atawọn ọrẹ rẹ n reti iranlọwọ awọn ajọ oloju aanu lati ko wọn kuro nibi ti wọn.

O ti sọ pe awọn ti ṣetan lati rinrinajo gba aṣalẹ Sahara kọja lai bikita nipa ewu to wa loju ọna ọhun.

O ni “ko si ohun ti yoo yẹ irinajo wa.”