Buhari, Jonathan, Gowon, Abubakar péjú síbi ìpàdé ìgbìmọ̀ Májẹ̀óbàjẹ́, ṣe káre sí Tinubu pé kò gbà fáwọn olùwọ́de láti dojú ìjọba rẹ̀ bolẹ̀

Aworan aare Bola Tinubu ati Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, President Bola Ahmed Tinubu Media Centre/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn aarẹ ati olori orilẹede Naijiria tẹlẹ ri, aarẹ ile aṣofin agba l'Abuja, adari ile igbimọ aṣoju-ṣofin l"Abuja, adajọ agba ni Naijiria at'awọn gomina ṣe ipade pẹlu Aarẹ Bola Tinubu niluu Abuja lọjọ Iṣẹgun lori iwọde 'ebi n pa wa' to waye fún ọjọ mẹwaa kaakiri Naijiria.

Awọn to kopa ninu ipade ọhun si ṣe atilẹyin fun Tinubu gẹgẹ bi aarẹ Naijiria.

Igbimọ aarẹ ati olori orilẹede Naijiria tẹlẹ ri naa ṣe apejuwe ifẹhonuhan to waye gẹgẹ bi ọna lati doju ijọba Tinubu bolẹ.

Olusegun Obasanjo ati Ibrahim Babangida ko si nibi ipade naa, ko si ẹni to mọ idi ti wọn ko fi wa

Lara awọn olori orilẹede Naijiria tẹlẹ ri ti wọn ṣatilẹyin fun Aarẹ Tinubu nibi ipade ọhun ni Ajagun feyinti Yakubu Gowon, Aarẹ ana Muhammadu Buhari ati Ajagun feyinti Abdulsalami Abubakar to fi mọ Aarẹ tẹlẹ ri Goodluck Jonathan.

Buhari ati Jonathan lo wa nibi ipade ọhun l'Abuja nigba ti Gowon ati Abdulsalami darapọ mọ wọn lori ẹrọ kọmputa.

Amọ, Aarẹ ana Oloye Olusegun Obasanjo ati Olori orileede Naijiria tẹlẹ ri, Ibrahim Babangida ko si nibi ipade naa.

Bẹẹ ko si ẹni to mọ idi ti wọn ko fi darapọ mọ ipade ọhun.

Aworan aare Bola Tinubu atawon gomina

Oríṣun àwòrán, President Bola Ahmed Tinubu Media Centre/X

Minisita meje jabọ lori ibi ti nnkan de duro nipa ọrọ aje fun Igbimọ majẹobajẹ

Nigba to n b'awọn akọroyin sọrọ lẹyin ipade naa, gomina Abdulrahman Abdulrazaq ipinlẹ Kwara, to jẹ alaga awọn gomina ni Naijiria ṣalaye pe gbogbo awọn to wa nibi ipade naa lo ṣatilẹyin fun Aarẹ Tinubu lori bi o ṣe n tukọ orilẹede Naijiria.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O ni awọn olori ati aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹ ri to wa nibi ipade ọhun ni wọn dunnu si alaye awọn minisita lori ibi ti ọrọ aje Naijiria de duro.

Ninu ọrọ tiẹ, minisita fun nnkan alumọni inu ilẹ, Dele Alake sọ pe igbimọ awọn olori orilẹede ati aarẹ Naijiria tẹlẹ ri gboṣuba kare lai fun Tinubu lori bi ko ṣe gba fawọn to fẹ doju ijọba rẹ bolẹ lasiko ifẹhonuhan to waye.

Alake ni oludamọran aarẹ lori eto abo, Mallam Nuhu Ribadu naa jabọ lori bi eto Naijiria ṣe ri lasiko iwọde ati lẹyin iwọde to waye.

Minisita ohun alumoni inu ilẹ sọ pe igbimọ awọn olori ati aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹ ri gbagbọ pe rogbodiyan to ṣẹlẹ kii ṣe ifẹhonuhan lasan bi ko ṣe ọna da ijọba awaarawa to wa lode ru.

Alake ṣalaye pe minisita meje lo jabọ lori ibi ti nnkan de duro lori ọrọ aje Naijiria nibi ipade ọhun.

Minisita eto inawo, Wale Edun naa sọ pe oun lanfaani lati ṣalaye fún igbimọ aarẹ ati olori orilẹede Naijiria tẹlẹ ri lori awọn ilọsiwaju to ti ba ọrọ aje Naijiria.