Àwọn aṣòfin Nàíjíríà yarí mọ́ Obasanjo lọ́wọ́, wọ́n kéde owó àmúrelé wọn l‘óṣù

Oríṣun àwòrán, Nigerian Senate/ Facebook
Ile igbimọ aṣofin agba Naijiria ti sọ pe ko si otitọ kankan ninu wi pe awọn ni wọn n sọ iye owo oṣu to n bọ si apo wọn ati awọn ajẹmọnu loriṣiiriṣii.
Bakan naa ni wọn tun sọ pe awọn ko gba awọn ẹtọ kankan lati ileeṣẹ aarẹ.
Agbẹnusọ ile igbimọ aṣofin, Yemi Adaramodu to n ṣoju ẹkun Guusu Ekiti, wi pe erongba ẹsun ti wọn fi kan awọn ni “lati le jẹ ki gbogbo araalu korira wọn nipa iwa agabagebe oṣelu”.
Eyi lo waye lẹyin ti aarẹ tẹlẹri, Olusegun Obasanjo, sọrọ pe bi awọn aṣofin ko ṣe n sọ iye owo oṣu ati awọn ajẹmọnu ti wọn n gba ko ba ofin ati ilana mu.
Ọrọ naa lo si ti di awuyewuye to n mu oriṣiiriṣii ibeere jade lati ọdọ awọn ọmọ Naijiria, lati mọ daju nipa iye owo oṣu ati ajẹmọnu ti awọn aṣofin naa n gba.
Ipo keji ni ile igbimọ aṣofin wa, to si pin si meji ::– ile igbimọ aṣofin agba ti wọn n pe ni ‘Red Chamber’, awọn sẹnetọ mọkandinlaadọfa (109) ti wọn n ṣoju ẹkun mẹta-mẹta ni ipinlẹ kọọkan ati ile igbimọ aṣoju kekere ti wọn n pe ni ‘Green Chamber’, to kun fun awọn aṣoju-ṣofin 360.
Aṣoju-ṣofin kọọkan lo n ṣoju ẹkun kọọkan lorileede yii.
Ile igbimọ aṣofin agba naa ti wa sọ pe ẹnikẹni to ba ni ẹri to jinlẹ, wi pe awọn ni wọ n sọ iye owo oṣu wọn, ko mu u wa sita. Wọn wa ṣapejuwe gbogbo awọn to n gbe iroyin naa sita gẹgẹ bi irinṣẹ eṣu.
Kí ni àarẹ tẹ́lẹ rí, Olusegun Obasanjo sọ to tako awọn asofin?

Oríṣun àwòrán, Getty image
Gẹgẹ bi ọpọ awọn iroyin ṣe gbe e, aarẹ tẹlẹri Olusegun Obasanjo gba awọn aṣoju-ṣofin kan lalejo nile rẹ to wa niluu Abẹokuta, olu-ilu ipinlẹ Ogun, nibi ti wọn ti sọ oriṣiriṣi ọrọ to nii ṣe pẹlu orileede naa bii ọdun mẹfa fun saa kan ati bi ipo aarẹ yoo ṣe maa yi laarin Ariwa ati awọn ẹkun yooku.
Nibi ipade naa, o fi ẹsun kan awọn aṣofin pe awọn lo n pinnu iye owo oṣu ati ajẹmọnu wọn, to si ni ojuṣe ajọ Revenue Mobilisation Allocation and Fiscal Commission (RMFAC) ni lati ṣagbekalẹ iye owo oṣu wọn, kii ṣe ko jẹ pe awọ ni yoo pinnu.
“Ko yẹ ko jẹ pe ẹyin le ma maa pinnu owo oṣu ati ajẹmọnu yin, RMFAC lo yẹ ko ṣe e, ṣugbọn funra yin lẹ n sọ iye ti ẹ n fun ara yin – owo iwe iroyin, owo awọtẹlẹ - oriṣirṣi owo lẹ n fun ara yin. O yẹ ki ẹ mọ pe ko dara to.
“Ko dara to fun mi lati maa ṣagbekalẹ iye owo oṣu ti mo ma maa san fun ara mi. Ko ba iwa ọmọluabi mu, ẹ si n ṣe e.
“Awọn aṣofin agba n ṣe, awọn alakoso n fun un yin ni owo ti ko tọ sii yin. Gbogbo yin lẹ n gba igba miliọnu naira.” Obasanjo sọ fun wọn.
Kii ṣe igba akọkọ ree ti aarẹ tẹlẹri naa yoo maa sọ erongba rẹ, to si maa n jẹ ko di mimọ.
Lọdun 2023, nibi idanilẹkọọ ita gbangba to wa lara eto ayẹyẹ idasilẹ ọgọta ọdun ti wọn awọn agbẹjọro Afẹ Babalọla, Obasanjo sọ ọrọ yii.
Iroyin sọ nigba naa pe, pupọ awọn to yẹ ko gbe ogo iwe ofin Naijiria duo ni wọn n doju eto iṣejọba awarawa bolẹ julọ.
O ṣapejuwe abala iwe ofin ti awọn aṣofin fi n ṣagbekalẹ owo oṣu wọn, to si lo tako ojuṣe ileeṣẹ Revenue Mobilisation and Fiscal Commission.
Ninu ọrọ rẹ, Obasanjo sọ pe “Nipasẹ iwe ofin, ileeṣẹ Revenue Mobilisation and Fiscal Commission lo yẹ ko ṣagbakalẹ iye owo ti awọn aṣofin yoo maa gba, ṣugbọn awọn aṣofin gbe ofin pa ofin naa ti sẹgbẹ kan, wọn si n pinnu owo oṣu wọn.”
Kí ni ilé igbìmọ̀ aṣìfin sọ?

Oríṣun àwòrán, Nigerian Senate/Facebook
“Ileeṣẹ Revenue Mobilization Fiscal Allocation lo n san owo oṣu wa, to si lọ ni ibamu pẹlu iwe ofin.”
Bayii ni ile igbimọ aṣofin Naijiria ṣe fesi si ẹsun naa ti alẹnulọrọ fi kan wọn.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ile igbimọ aṣofin, Yemi Adaramodu gbe ade lọjọ Aiku, ọjọ kọkanla, oṣu kẹjọ loju opo ‘X’ rẹ, o sọ pe ẹsun ti Obasan jo fi kan awọn ni lati kan wọn mọ agbelebu.
Bakan naa lo tun sọ pe ko si aṣofin kankan to n gba owo ajẹmọnu lati ile iṣẹ aarẹ.
“Lati sọ oju abẹ nikoo, ile igbimọ aṣofin sọ pe owo ti ileeṣẹ Revenue Mobilization Fiscal Allocation Commission la kalẹ ni awọn n gba, ni ibamu pẹlu alakalẹ iwe ofin.”
Ṣugbọn ko mẹnuba iye owo ti ileeṣẹ RMFAC n san fun wọn gẹgẹ bi owo oṣu.
Adaramodu tun fi kun ọrọ rẹ pe “iṣẹ iwe ofin to lọ pẹlu ile igbimọ jẹ ohun to kere ninu eyi ti awọnsẹnetọ le ṣiṣẹ le lori, pẹlu oriṣiriṣi ohun to n ṣẹlẹ ninu eto iṣejọba kaakiri agbaye.”
Ile igbimọ aṣofin tun ṣalaye siwaju gẹgẹ bi ẹka ijọba to ṣe pataki, nipasẹ awọn ileeṣẹ wọn ni wọn fi n gbe iṣẹ akanṣe jade si awọn ẹkun ti wọn n ṣoju.
Bẹẹ ni wọ tun sọ pe iṣẹ ti wọn n ṣe si awọ agbegbe ti wọn n ṣoju ṣọtọọtọ, to si nii ṣe pẹlu bi awọn eeyan ṣe pọ to lawọn agbegbe wọn nipinlẹ kọọkan, ati pe gbogbo ẹkun kọọkan ni yoo jẹ anfaani awọn ohun amuṣọrọ ijọba apapọ.
Éèló gan-an lawọn aṣofin n gba?

Oríṣun àwòrán, Revenue Mobilization Allocation and Fiscal Commission website
Ọpọ ọrọ ijiroro lo ti n lọ kaakiri igboro nipa iye ti awọ aṣofin n gba.
Ko tii si ẹka ileeṣẹ ijọba tabi ileeṣẹ kankan to ṣi jade sita lati sọ pato iye owo ti wọn n gba.
Ju gbogbo rẹ lọ, awọn aṣofin kan lawọn igba ọtọọtọ ti sọ iye ti awọn to wa nipo oṣelu n gba, bo tilẹ jẹ pe wọn ko sọ iye to jẹ ni pato.
Lọdun 2018, Shehu Sani, aṣofin tẹlẹ to ṣoju aarin gbungbun Kasuna sọ pe oun ati awọn akẹgbẹ oun n gba miliọnu kan naira gẹgẹ bi owo awọn ohun ti wọn n ra, eyi to yatọ si owo oṣu.

Oríṣun àwòrán, Revenue Mobilization Allocation and Fiscal Commission website

Oríṣun àwòrán, Revenue Mobilization Allocation and Fiscal Commission website

Oríṣun àwòrán, Revenue Mobilization Allocation and Fiscal Commission website















